Ìwé Kejì sí Tímótì 3:1-17

  • Nǹkan máa le gan-an ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn (1-7)

  • Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù pẹ́kípẹ́kí (8-13)

  • “Má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀” (14-17)

    • Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí (16)

3  Àmọ́ kí o mọ èyí pé, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn+ yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.  Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́,  ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà,* abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere,  ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run,  wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn;+ yẹra fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.  Lára wọn ni àwọn ọkùnrin kan ti jáde, tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn wọnú àwọn agbo ilé, tí wọ́n sì ń tan àwọn aláìlera obìnrin tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lọ́rùn, tí onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń darí,  gbogbo ìgbà ni wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ wọn ò ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ rárá.  Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà.  Síbẹ̀, wọn ò ní kọjá ibi tí wọ́n dé, torí ìwà òmùgọ̀* wọn máa hàn kedere sí gbogbo èèyàn, bíi tàwọn ọkùnrin méjì yẹn.+ 10  Àmọ́, o ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, bí mo ṣe ń ṣe nǹkan,+ ohun tí mo ní lọ́kàn, ìgbàgbọ́ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, 11  àwọn inúnibíni àti irú ìyà tó jẹ mí ní Áńtíókù,+ Íkóníónì+ àti Lísírà.+ Mo fara da àwọn inúnibíni yìí, Olúwa sì gbà mí nínú gbogbo wọn.+ 12  Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.+ 13  Àmọ́ àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i, wọ́n á máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n á sì máa ṣi àwọn náà lọ́nà.+ 14  Àmọ́ kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́,*+ o sì mọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn 15  àti pé láti kékeré jòjòló  + lo ti mọ ìwé mímọ́,+ èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 16  Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì wúlò fún kíkọ́ni,+ fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́,* fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo,+ 17  kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹni tí kì í fẹ́ ṣe àdéhùn.”
Tàbí “ìwà agọ̀.”
Ní Grk., “tí a sì ti yí ọ lérò pa dà láti gbà gbọ́.”
Tàbí “títún nǹkan ṣe.”