Oníwàásù 7:1-29

  • Orúkọ rere àti ọjọ́ ikú (1-4)

  • Ìbáwí tí ọlọ́gbọ́n fúnni (5-7)

  • Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ (8-10)

  • Àǹfààní ọgbọ́n (11, 12)

  • Ọjọ́ rere àti ọjọ́ burúkú (13-15)

  • Yẹra fún àṣejù (16-22)

  • Àwọn ohun tí akónijọ kíyè sí (23-29)

7  Orúkọ rere* sàn ju òróró dáradára,+ ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.  Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àsè,+ torí pé ìyẹn ni òpin gbogbo èèyàn, ó sì yẹ kí àwọn alààyè fi sọ́kàn.  Ìbànújẹ́ sàn ju ẹ̀rín lọ,+ torí ojú tó fà ro ń mú kí ọkàn túbọ̀ ṣiṣẹ́ dáadáa.+  Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, àmọ́ ilé ìdùnnú* ni ọkàn òmùgọ̀ wà.+  Ó sàn kéèyàn fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n+ ju kéèyàn máa gbọ́ orin àwọn òmùgọ̀.  Torí pé bí ẹ̀gún tó ń jó lábẹ́ ìkòkò ṣe máa ń ta pàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí;+ asán sì ni èyí pẹ̀lú.  Ìnilára lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bíi wèrè, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì ń sọ ọkàn dìdàkudà.+  Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ. Ó sàn kéèyàn ní sùúrù ju pé kéèyàn ní ẹ̀mí ìgbéraga.+  Má ṣe máa yára* bínú,+ torí pé àyà àwọn òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.*+ 10  Má sọ pé, “Kí nìdí tí àwọn ọjọ́ àtijọ́ fi sàn ju ti ìgbà yìí lọ?” torí pé kì í ṣe ọgbọ́n ló mú kí o béèrè bẹ́ẹ̀.+ 11  Ọgbọ́n pẹ̀lú ogún jẹ́ ohun tó dáa, ó sì jẹ́ àǹfààní fún àwọn tó ń rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.* 12  Nítorí ọgbọ́n jẹ́ ààbò+ bí owó ṣe jẹ́ ààbò,+ àmọ́ àǹfààní ìmọ̀ ni pé: Ọgbọ́n máa ń dá ẹ̀mí àwọn tó ní in sí.+ 13  Kíyè sí iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ta ló lè mú kí ohun tó ṣe ní wíwọ́ tọ́?+ 14  Ní ọjọ́ tí nǹkan bá dáa, jẹ́ kó hàn lójú rẹ,+ àmọ́ ní ọjọ́ àjálù, fiyè sí i pé Ọlọ́run ti ṣe àkọ́kọ́ àti èkejì,+ kí aráyé má bàa lè sọ ní pàtó* ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ iwájú.+ 15  Ohun gbogbo ni mo ti rí ní gbogbo ìgbé ayé asán mi,+ látorí olódodo tó ṣègbé nínú òdodo rẹ̀,+ dórí ẹni burúkú tó pẹ́ láyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà burúkú ló ń hù.+ 16  Má ṣe òdodo àṣelékè,+ bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe gbọ́n ní àgbọ́njù.+ Àbí o fẹ́ pa ara rẹ ni?+ 17  Má sọ ìwà burúkú dàṣà, má sì ya òmùgọ̀.+ Ṣé ó yẹ kí o kú láìtọ́jọ́ ni?+ 18  Ó sàn kéèyàn gba ìkìlọ̀ àkọ́kọ́, kó má sì jẹ́ kí èkejì bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́;+ nítorí ẹni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run yóò pa méjèèjì mọ́. 19  Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n lágbára ju akíkanjú ọkùnrin mẹ́wàá tó ń ṣọ́ ìlú.+ 20  Nítorí kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.+ 21  Bákan náà, má ṣe máa fọkàn sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn èèyàn bá sọ;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń bú* ọ; 22  torí o mọ̀ lọ́kàn rẹ dáadáa pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti bú àwọn míì.+ 23  Gbogbo èyí ni mo ti fi ọgbọ́n dán wò, mo sì sọ pé: “Màá di ọlọ́gbọ́n.” Àmọ́, ó kọjá agbára mi. 24  Ohun tó ti wà, ọwọ́ ò lè tó o, ó sì jinlẹ̀ gidigidi. Ta ló lè lóye rẹ̀?+ 25  Mo darí ọkàn mi kí n lè mọ̀, kí n lè wádìí, kí n sì lè wá ọgbọ́n àti ohun tó ń fa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀, mo sì darí rẹ̀ kí n lè lóye aburú tó wà nínú ìwà ẹ̀gọ̀ àti àìlọ́gbọ́n tó wà nínú ìwà wèrè.+ 26  Mo wá rí i pé: Ohun tó korò ju ikú lọ ni obìnrin tó dà bí àwọ̀n ọlọ́dẹ, tí ọkàn rẹ̀ dà bí àwọ̀n ńlá, tí ọwọ́ rẹ̀ sì dà bíi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ á bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀,+ àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ á kó sọ́wọ́ rẹ̀.+ 27  Akónijọ+ sọ pé, “Wò ó! èyí ni mo ti rí. Mo gbé àwọn nǹkan yẹ̀ wò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan kí n lè mọ ibi tí màá parí èrò sí, 28  àmọ́ mi* ò tíì rí ohun tí mò ń fi ìgbà gbogbo wá. Mo rí ọkùnrin kan* nínú ẹgbẹ̀rún, àmọ́ mi ò tíì rí obìnrin kan nínú wọn. 29  Èyí nìkan ṣoṣo ni mo ti rí pé: Ọlọ́run tòótọ́ dá aráyé ní adúróṣinṣin,+ àmọ́ wọ́n ti wá ọ̀pọ̀ ètekéte.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Orúkọ.”
Tàbí “ìgbádùn.”
Tàbí kó jẹ́, “ìbínú ni àmì àwọn òmùgọ̀.”
Ní Héb., “kánjú ní ẹ̀mí láti.”
Ìyẹn, àwọn tó wà láàyè.
Tàbí “ṣàwárí.”
Ní Héb., “ṣépè fún.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkùnrin kan tó jẹ́ adúróṣinṣin.”