Sí Àwọn Ará Gálátíà 6:1-18
6 Ẹ̀yin ará, tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀, kí ẹ̀yin tí ẹ kúnjú ìwọ̀n nípa tẹ̀mí sapá láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́* tọ́ ẹni náà sọ́nà.+ Àmọ́ kí ẹ máa kíyè sí ara yín lójú méjèèjì,+ kí a má bàa dẹ ẹ̀yin náà wò.+
2 Ẹ máa bá ara yín gbé ẹrù tó wúwo,+ nípa bẹ́ẹ̀, ẹ ó mú òfin Kristi ṣẹ.+
3 Tí ẹnì kan bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan,+ ó ń tan ara rẹ̀ jẹ ni.
4 Àmọ́ kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò,+ nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.+
5 Torí kálukú ló máa ru ẹrù ara rẹ̀.*+
6 Yàtọ̀ síyẹn, kí ẹni tí à ń kọ́* ní ọ̀rọ̀ náà máa ṣàjọpín ohun rere gbogbo pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ni* ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.+
7 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ: Ọlọ́run kò ṣeé tàn.* Nítorí ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká;+
8 torí pé ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ara rẹ̀ máa ká ìdíbàjẹ́ látinú ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń fúnrúgbìn nítorí ẹ̀mí máa ká ìyè àìnípẹ̀kun látinú ẹ̀mí.+
9 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere, torí tí àkókò bá tó, a máa kórè rẹ̀ tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá.*+
10 Tóò, nígbà tí a bá ti láǹfààní rẹ̀,* ẹ jẹ́ ká máa ṣe rere fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ní pàtàkì fún àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.
11 Ẹ wo àwọn lẹ́tà gàdàgbà tí mo fi kọ̀wé sí yín ní ọwọ́ ara mi.
12 Gbogbo àwọn tí ó fẹ́ kí àwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa wọn nínú ara,* ni àwọn tó fẹ́ sọ ọ́ di dandan fún yín pé kí ẹ dádọ̀dọ́,* wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ kí a má bàa ṣe inúnibíni sí wọn nítorí òpó igi oró* Kristi.
13 Nítorí àwọn tó ń dádọ̀dọ́* pàápàá kì í pa Òfin mọ́,+ àmọ́ wọ́n fẹ́ kí ẹ dádọ̀dọ́ kí wọ́n lè máa ti ara yín yangàn.
14 Ní tèmi, mi ò ní yangàn láé, àfi nípa òpó igi oró* Olúwa wa Jésù Kristi,+ ẹni tí a tipasẹ̀ rẹ̀ sọ ayé di òkú* lójú tèmi àti èmi lójú ti ayé.
15 Nítorí ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kọ́ ló ṣe pàtàkì,+ ẹ̀dá tuntun ló ṣe pàtàkì.+
16 Ní ti gbogbo àwọn tó ń rìn létòlétò nínú ìlànà ìwà rere yìí, kí àlàáfíà àti àánú wà lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni, lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.+
17 Láti ìsinsìnyí lọ, kí ẹnikẹ́ni má dà mí láàmú mọ́, nítorí àpá ẹrú Jésù wà ní ara mi.+
18 Ẹ̀yin ará, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ̀mí tí ẹ̀ ń fi hàn. Àmín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “ẹ̀mí ìwà tútù.”
^ Tàbí “ṣe ojúṣe tirẹ̀.”
^ Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́.”
^ Tàbí “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ni.”
^ Ní Grk., “fi ṣe ẹlẹ́yà.”
^ Tàbí “juwọ́ sílẹ̀.”
^ Ní Grk., “ní àkókò tí a yàn kalẹ̀.”
^ Tàbí “tí wọ́n fẹ́ lẹ́wà lóde ara.”
^ Tàbí “kọlà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “kọlà.”
^ Tàbí “kan ayé mọ́gi.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ìkọlà.”
^ Tàbí “àìkọlà.”