Jẹ́nẹ́sísì 1:1-31

  • Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé (1, 2)

  • Àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ní ọjọ́ kìíní sí ìkẹfà (3-31)

    • Ọjọ́ 1: ìmọ́lẹ̀; ọ̀sán àti òru (3-5)

    • Ọjọ́ 2: òfúrufú (6-8)

    • Ọjọ́ 3: ilẹ̀ àti ewéko (9-13)

    • Ọjọ́ 4: àwọn orísun ìmọ́lẹ̀ tó wà lọ́run (14-19)

    • Ọjọ́ 5: àwọn ẹja àtàwọn ẹyẹ (20-23)

    • Ọjọ́ 6: àwọn ẹran orí ilẹ̀ àti èèyàn (24-31)

1  Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.+  Nígbà yẹn, ayé wà ní bọrọgidi, ó sì ṣófo. Òkùnkùn bo ibú omi,*+ ẹ̀mí Ọlọ́run*+ sì ń lọ káàkiri lójú omi.+  Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ wà.” Ìmọ́lẹ̀ sì wà.+  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí í pààlà sáàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.  Ọlọ́run pe ìmọ́lẹ̀ ní Ọ̀sán, ó sì pe òkùnkùn ní Òru.+ Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kìíní.  Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí òfúrufú+ wà láàárín omi, kí omi sì pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀.”+  Ọlọ́run wá ṣe òfúrufú, ó pààlà sáàárín omi tó wà lókè òfúrufú náà àti omi tó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀.  Ọlọ́run pe òfúrufú ní Ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kejì.  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Kí àwọn omi tó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́ jọ síbì kan, kí ilẹ̀ sì fara hàn.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10  Ọlọ́run pe ilẹ̀ náà ní Ayé,+ àmọ́ ó pe omi tó wọ́ jọ ní Òkun.+ Ọlọ́run sì rí i pé ó dára.+ 11  Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí koríko hù ní ayé, pẹ̀lú àwọn ewéko tó ń so èso àti àwọn igi eléso tó ní irúgbìn ní irú tiwọn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12  Koríko bẹ̀rẹ̀ sí í hù ní ayé pẹ̀lú àwọn ewéko tó ń so èso+ àti àwọn igi eléso tó ní irúgbìn ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 13  Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹta. 14  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Kí orísun ìmọ́lẹ̀*+ wà ní ojú ọ̀run, kí ìyàtọ̀ lè wà láàárín ọ̀sán àti òru,+ wọ́n á sì jẹ́ àmì láti fi mọ àwọn àsìkò, ọjọ́ àti ọdún.+ 15  Wọ́n á jẹ́ orísun ìmọ́lẹ̀ tí á máa tàn sórí ayé láti ojú ọ̀run.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16  Ọlọ́run dá orísun ìmọ́lẹ̀ ńlá méjì, èyí tó tóbi á máa yọ ní ọ̀sán,+ èyí tó kéré á sì máa yọ ní òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀.+ 17  Ọlọ́run wá fi wọ́n sí ojú ọ̀run kí wọ́n lè máa tàn sórí ayé, 18  kí wọ́n lè máa yọ ní ọ̀sán àti ní òru, kí wọ́n sì mú kí ìyàtọ̀ wà láàárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.+ Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19  Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹrin. 20  Ọlọ́run sì sọ pé: “Kí àwọn ohun alààyè* máa gbá yìn-ìn nínú omi, kí àwọn ẹ̀dá tó ń fò sì máa fò lójú ọ̀run.”*+ 21  Ọlọ́run sì dá àwọn ẹran ńlá inú òkun àti gbogbo ohun alààyè* tó ń gbá yìn-ìn nínú omi ní irú tiwọn àti àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 22  Torí náà, Ọlọ́run súre fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún inú omi òkun,+ kí àwọn ẹ̀dá tó ń fò sì pọ̀ ní ayé.” 23  Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ karùn-ún. 24  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí ilẹ̀ mú àwọn ohun alààyè* jáde ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran tó ń rákò* àti àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25  Ọlọ́run dá àwọn ẹran inú igbó ní irú tiwọn àti àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti àwọn ẹran tó ń rákò ní irú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 26  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Jẹ́ ká+ dá èèyàn ní àwòrán wa,+ kí wọ́n jọ wá,+ kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, àwọn ẹran ọ̀sìn, lórí gbogbo ayé àti lórí gbogbo ẹran tó ń rákò tó sì ń rìn lórí ilẹ̀.”+ 27  Ọlọ́run sì dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run; akọ àti abo ló dá wọn.+ 28  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé,+ kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀,+ kí ẹ máa jọba lórí+ àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti lórí gbogbo ohun alààyè tó ń rìn lórí ilẹ̀.” 29  Ọlọ́run sì sọ pé: “Mo fún yín ní gbogbo ewéko ní gbogbo ayé, àwọn tó ń so èso àti gbogbo igi eléso tó ní irúgbìn. Kí wọ́n jẹ́ oúnjẹ fún yín.+ 30  Mo sì fi gbogbo ewéko tútù ṣe oúnjẹ fún gbogbo ẹran inú igbó àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run àti gbogbo ohun abẹ̀mí* tó ń rìn lórí ilẹ̀.”+ Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 31  Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run rí gbogbo ohun tó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an.+ Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì mọ́, èyí ni ọjọ́ kẹfà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “omi tó ń ru gùdù.”
Tàbí “agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run.”
Tàbí “àwọn ìmọ́lẹ̀.”
Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”
Tàbí “òfúrufú.”
Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”
Tàbí “àwọn alààyè ọkàn.”
Tàbí “àwọn ẹran tó ń rìn káàkiri,” ó jọ pé àwọn ẹran afàyàfà àti oríṣiríṣi ẹran míì wà lára wọn.
Tàbí “ohun tó ní ẹ̀mí; ohun tó jẹ́ alààyè ọkàn.”