Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ṣíṣe ara lóge, síbẹ̀ kò sọ pé ó burú téèyàn bá ṣojú lóge, tó lo àtíkè tàbí tó tọ́tè, tó lo ohun ọ̀ṣọ́ tàbí àwọn nǹkan míì téèyàn fi ń ṣara lóge. Àmọ́, dípò tí Bíbélì á fi máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa ìrísí ara, ohun tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ jù ni “aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù.”​—1 Pétérù 3:3, 4.

Bíbélì kò sọ pé ó burú láti ṣara lóge

  •   Àwọn obìnrin olóòótọ́ nínú Bíbélì ṣe ara wọn lóge. Rèbékà tó fẹ́ Ísákì ọmọ Ábúráhámù wọ òrùka imú tó jẹ́ góòlù, ẹ̀gbà ọwọ́ tó jẹ́ góòlù àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ míì tó jẹ́ olówó ńlá, èyí tí Ábúráhámù tó pa dà di bàbá ọkọ rẹ̀ fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 24:22, 30, 53) Bákan náà, Ẹ́sítérì gbà kí wọ́n ṣe “ìwọ́ra obìnrin” fún òun, kí wọ́n lè múra rẹ̀ sílẹ̀ de ipò ayaba Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tó ń dúró dè é. (Ẹ́sítérì 2:7, 9, 12) Onírúurú ohun èlò ìṣaralóge ni wọ́n máa ń lò fún ìwọ́ra yìí.

  •   Bíbélì máa ń lo ọ̀ṣọ́ láti fi ṣàpèjúwe ohun tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi ẹni tó fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wé “yẹtí tí a fi wúrà ṣe, . . . ní etí tí ń gbọ́ràn.” (Òwe 25:12) Bákan náà, Ọlọ́run fi àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé bí ọkọ kan ṣe máa ń fi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ bíi ẹ̀gbà ọwọ́, ẹ̀gbà ọrùn àti yẹtí ṣe ìyàwó rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Ohun ọ̀ṣọ́ yìí mú kí orílẹ̀-èdè náà “lẹ́wà gidigidi.”​—Ìsíkíẹ́lì 16:11-​13.

Àṣìlóye nípa ṣíṣe ara lóge

 Àṣìlóye:1 Pétérù 3:3, Bíbélì dẹ́bi fún ‘irun dídì àti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára.’

 Òótọ́: Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé ẹsẹ yẹn jẹ́ ká rí i pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ ni pé ẹwà inú ló ṣe pàtàkì ju ìrísí tàbí ṣíṣe ara lóge lọ. (1 Pétérù 3:3-6) Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì náà wà tó ṣe irú àfiwé yìí.​—1 Sámúẹ́lì 16:7; Òwe 11:22; 31:30; 1 Tímótì 2:9, 10.

 Àṣìlóye: Bí Jésíbẹ́lì Ayaba búburú ṣe ṣojú lóge tàbí tó “lé tìróò sójú,” fi hàn pé ohun tí kò dáa ni láti máa ṣe ojú lóge.​—2 Àwọn Ọba 9:30

 Òótọ́: Ìwà burúkú ọwọ́ Jésíbẹ́lì, irú bíi iṣẹ́ àjẹ́ àti ìpànìyàn ni Ọlọ́run fi dá a lẹ́jọ́, kì í ṣe torí ìrísí rẹ̀.​—2 Àwọn Ọba 9:7, 22, 36, 37.