Òwe 8:1-36

  • Ọgbọ́n sọ̀rọ̀ bí èèyàn (1-36)

    • ‘Èmi ni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run’ (22)

    • ‘Gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run’ (30)

    • ‘Mo fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn’ (31)

8  Ǹjẹ́ ọgbọ́n ò máa ké jáde? Ṣé òye ò máa gbé ohùn rẹ̀ sókè?+   Ní orí àwọn ibi gíga+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà,Ó dúró ní àwọn oríta.   Lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè tó wọnú ìlú,Ní àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà,Ó ń ké tantan pé:+   “Ẹ̀yin ni mò ń pè, ẹ̀yin èèyàn;Gbogbo yín* ni mò ń ké sí.   Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́ àròjinlẹ̀;+Ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ wá ọkàn òye.*   Ẹ fetí sílẹ̀, torí ohun tí mò ń sọ ṣe pàtàkì,Ètè mi ń sọ ohun tí ó tọ́;   Nítorí ẹnu mi ń sọ òtítọ́ ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,Ètè mi sì kórìíra ohun tó burú.   Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Kò sí ẹ̀tàn kankan tàbí màgòmágó nínú wọn.   Gbogbo wọn tọ̀nà lójú ẹni tó lóyeWọ́n sì tọ́ lójú àwọn tó ti wá ìmọ̀ rí. 10  Ẹ gba ìbáwí mi dípò fàdákà,Àti ìmọ̀ dípò wúrà tó dára jù lọ,+ 11  Nítorí ọgbọ́n sàn ju iyùn* lọ;Kò sí ohun ṣíṣeyebíye míì tí a lè fi wé e. 12  Èmi ọgbọ́n, mò ń bá àròjinlẹ̀ gbé;Mo ti wá ìmọ̀ àti làákàyè rí.+ 13  Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìkórìíra ohun búburú.+ Mo kórìíra ìṣefọ́nńté àti ìgbéraga+ àti ọ̀nà ibi àti ọ̀rọ̀ àyídáyidà.+ 14  Mo ní ìmọ̀ràn rere àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́;+Òye+ àti agbára+ jẹ́ tèmi. 15  Ipasẹ̀ mi ni àwọn ọba ń ṣàkóso,Tí àwọn aláṣẹ sì ń pàṣẹ òdodo.+ 16  Ipasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣàkóso,Tí àwọn èèyàn pàtàkì sì ń fi òdodo ṣèdájọ́. 17  Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi,Àwọn tó sì ń wá mi yóò rí mi.+ 18  Ọrọ̀ àti ògo wà lọ́dọ̀ mi,Ọlá tó wà pẹ́ títí* àti òdodo. 19  Èso mi sàn ju wúrà lọ, àní wúrà tí a yọ́ mọ́,Ohun tí mo sì ń mú jáde sàn ju fàdákà tó dára jù lọ.+ 20  Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,Ní àárín àwọn ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo; 21  Mo fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ mi ní ogún tó ṣeyebíye,Mo sì mú kí ilé ìkẹ́rùsí wọn kún. 22  Jèhófà ṣẹ̀dá mi gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀nà rẹ̀,+Àkọ́bẹ̀rẹ̀ àwọn àṣeyọrí rẹ̀ ti ìgbà láéláé.+ 23  Láti ayébáyé* ni a ti gbé mi kalẹ̀,+Láti ìbẹ̀rẹ̀, ṣáájú kí ayé tó wà.+ 24  Nígbà tí kò sí àwọn ibú omi,+ a mú mi jáde,*Nígbà tí kò sí àwọn ìsun omi tó kún dẹ́múdẹ́mú. 25  Kí a tó fìdí àwọn òkè ńlá kalẹ̀,Ṣáájú àwọn òkè kéékèèké, a ti mú mi jáde, 26  Nígbà tí kò tíì dá ayé àti àwọn pápá rẹ̀Tàbí erùpẹ̀ ilẹ̀ tó kọ́kọ́ wà. 27  Nígbà tó dá ọ̀run,+ mo wà níbẹ̀;Nígbà tó fi ààlà* sí orí omi,+ 28  Nígbà tó ṣe àwọsánmà sókè,*Nígbà tó dá àwọn ìsun ibú omi, 29  Nígbà tó pàṣẹ fún òkunPé kí omi rẹ̀ má kọjá àṣẹ tó pa fún un,+Nígbà tó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,* 30  Nígbà náà, mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.+ Èmi ni àrídunnú rẹ̀+ lójoojúmọ́;Inú mi sì ń dùn níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà;+ 31  Inú mi ń dùn nítorí ayé tí ó dá fún èèyàn láti máa gbé,Mo sì fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn* lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. 32  Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;Bẹ́ẹ̀ ni, aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa àwọn ọ̀nà mi mọ́. 33  Ẹ fetí sí ìbáwí+ kí ẹ sì gbọ́n,Ẹ má ṣe pa á tì láé. 34  Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fetí sí miTó ń jí wá sẹ́nu* ọ̀nà mi lójoojúmọ́,Tó ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn mi; 35  Nítorí ẹni tó bá rí mi yóò rí ìyè,+Yóò sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. 36  Àmọ́ ẹni tó bá pa mí tì, ara* rẹ̀ ló ń ṣe,Àwọn tó sì kórìíra mi fẹ́ràn ikú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ẹ̀yin ọmọ èèyàn.”
Ní Héb., “lóye ọkàn.”
Tàbí “Ohun àjogúnbá tó ṣeyebíye.”
Tàbí “Láti ayérayé.”
Tàbí “a bí mi nínú ìrora ìbímọ.”
Ní Héb., “àmì òbìrìkìtì.”
Ní Héb., “tó mú kí àwọsánmà lágbára lókè.”
Tàbí “tó fi àṣẹ gbé àwọn ìpìlẹ̀ ayé kalẹ̀.”
Tàbí “aráyé.”
Tàbí “Tó ń wà lójúfò lẹ́nu.”
Tàbí “ọkàn.”