Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn

 Bó o ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe ìgbéyàwó rẹ láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún un. Kí ló ń ṣe fún ìgbéyàwó rẹ?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe àwọn tọkọtaya láǹfààní tí wọ́n bá fọgbọ́n lò ó. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan máa ń lò ó láti bára wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí wọn ò bá sí pa pọ̀.

     “Tó o bá tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ pé ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ’ tàbí ‘Ọkàn mi fà sí ẹ’ lè mú kí àárín yín gún régé.”​—Jonathan.

  •   Tèèyàn ò bá fọgbọ́n lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, ó lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo ìgbà làwọn kan máa ń lo fóònù tàbí tábúlẹ́ẹ̀tì wọn, ó sì máa ń gba gbogbo àkókò tó yẹ kí wọ́n lò pẹ̀lú ọkọ tàbí ìyàwó wọn wọn.

     “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo mọ̀ pé ó máa ń wu ọkọ mi láti bá mi sọ̀rọ̀, àmọ́ fóònù tí mò ń tẹ̀ kò jẹ́ ká fẹ́ sọ̀rọ̀.”​—Julissa.

  •   Àwọn kan sọ pé àwọn lè máa bá ọkọ tàbí aya àwọn sọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì káwọn sì máa lo fóònù wọn lásìkò kan náà. Sherry Turkle tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé “àlá tí kò lè ṣẹ ni tẹ́nì kan bá rò pé òun lè ṣe nǹkan méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà.” Kódà, ó ní kì í ṣe ìwà ọmọlúwàbí. Ó tún sọ pé, “òótọ́ kan ni pé kò sí bá a ṣe lè gbìyànjú láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ́ẹ̀kan náà tí àwọn nǹkan ọ̀hún sì máa dáa.” a

     “Mo máa ń gbádùn àkókò témi àtọkọ mi fi máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, àmọ́ kì í ṣègbà tó bá ń ṣe nǹkan méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan náà. Tó bá ti ń ṣe nǹkan méjì tàbí mẹ́tà lẹ́ẹ̀kan náà, ó máa ń ṣe mí bíi pé ohun tó ń ṣe yẹn ló jẹ ẹ́ lógún jù, kò sì fẹ́ mọ̀ bóyá mo wà pẹ̀lú òun tàbí mi ò sí.”​—Sarah.

 Kókó ibẹ̀: Bó o ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe ìgbéyàwó rẹ láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún un.

 Ohun tó o lè ṣe

 Mọ ohun tó yẹ kó o fi sípò àkọ́kọ́. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.’ (Fílípì 1:10) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé àkókò tó yẹ kí èmi àtọkọ mi tàbí aya mi fi wà pa pọ là ń lò nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé?’

 “Kì í ṣe ohun tó bójú mu kí ọkùnrin àtobìnrin kan máa lo fóònù wọn níbí tí wọ́n ti ń jẹun nílé oúnjẹ, káwọn méjèèjì máa tẹ fóònù kí wọ́n má sì bára wọn sọ̀rọ̀. Kó yẹ ká jẹ́ kí ẹ̀rọ ìgbàlódé gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa pa àjọṣe àwa méjèèjì tì, àjọṣe wa lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.”​—⁠Matthew.

 Fi ààlà sí i. Bíbélì sọ pé: “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.” (Éfésù 5:​15, 16) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Ṣé mo lè ya àkókò kan pàtó sọ́tọ̀ tí màá fi ka àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tí kì í ṣe pàjáwìrì, tí máa sì fèsì wọn dípò kí n kàn máa fèsì gbogbo àtẹ̀jíṣẹ́ lójú ẹsẹ̀ bó ṣe ń wọlé?’

 “Ọgbọ́n tí mo sábà máa ń dá ni pé mo máa ń yí fóònù mi wálẹ̀ lọ́nà tí kò fi ní dún, màá sì fèsì àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tó bá wọlé nígbà tó bá rọ̀ mí lọ́rùn. Ó ṣọ̀wọ́n kí ìpè tó ń wọlé, ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ lórí fóònù tàbí lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ̀tì jẹ́ nǹkan pàjáwìrì tó gba pé kéèyàn fèsì lójú ẹsẹ̀.”​—Jonathan.

 Tó bá ṣeé ṣe, máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ níbi iṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.” (Oníwàásù 3:⁠1) Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé mo ti ń jẹ́ kí iṣẹ́ mi kó bá ìdílé mi torí bí mo ṣe ń fi fóònù ṣe àwọn iṣẹ́ tó yẹ kí n ṣe níbi iṣẹ́ nígbà tí mo bá wà nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àkóbá wo nìyẹn ń ṣe fún ìgbéyàwó mi? Báwo ni ọkọ tàbí aya mi ṣe máa dáhùn ìbéèrè yìí?’

 “Ẹ̀rọ ìgbàlódé ti mú kó rọrùn láti ṣiṣẹ́ níbikíbi àti nígbàkigbà. Témi àti ìyàwó mi bá ti wà pa pọ̀, mo máa ń sapá gan-an kí n má máa wo fóònù mi látìgbàdégbà kí n má sì máa ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́.”​—Matthew.

 Bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ẹ ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé. Bíbélì sọ pé: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ẹni kọ̀ọ̀kan yín ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, tó bá sì níbi tó ti yẹ kẹ́ ẹ̀ ṣàtúnṣe, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tó yẹ kẹ́ ẹ jọ jíròrò tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

 “Èmi àti ọkọ mi fọkàn tán ara wa gan-an, a sì máa ń sọ fúnra wa tá a bá ti rí i pé ẹni kan ti ń lo àkókò jù nídìí fóònù tàbí tábúlẹ́ẹ̀tì rẹ̀. Àwa méjèèjì rí i pé ó lè dá ìṣòro sílẹ̀, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń fara balẹ̀ ká lè lóye ara wa.”​—⁠Danielle.

 Kókó ibẹ̀: Rí i dájú pé o lo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti mú kí nǹkan rọrùn fún ẹ, má sì jẹ́ kó darí ẹ.

a Látinú ìwé Reclaiming Conversation—The Power of Talk in a Digital Age.