Òwe 16:1-33

  • Jèhófà ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn (2)

  • Fi gbogbo iṣẹ́ rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́ (3)

  • Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òṣùwọ̀n pípé ti wá (11)

  • Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun (18)

  • Ewú orí jẹ́ adé ẹwà (31)

16  Èèyàn lè gbèrò ohun kan lọ́kàn ara rẹ̀,*Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn rẹ̀* ti máa wá.+   Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́* lójú ara rẹ̀,+Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn.*+   Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́,*+Ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.   Jèhófà ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́,Kódà láti pa ẹni burúkú run ní ọjọ́ àjálù.+   Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.+ Ó dájú* pé wọn ò ní lọ láìjìyà.   Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+Ìbẹ̀rù Jèhófà sì máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.+   Tí inú Jèhófà bá dùn sí ọ̀nà èèyàn,Ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.+   Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀ àmọ́ kó jẹ́ olóòótọ́+Ju kéèyàn fi èrú kó èrè púpọ̀ jọ.+   Èèyàn lè ro bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa rí lọ́kàn rẹ̀,Àmọ́ Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ rẹ̀.+ 10  Ìpinnu tó ní ìmísí* ló yẹ kó máa wà lẹ́nu ọba;+Kò gbọ́dọ̀ dá ẹjọ́ lọ́nà tí kò tọ́.+ 11  Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé ti wá;Gbogbo òkúta ìwọ̀n tó wà nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+ 12  Àwọn ọba kórìíra ìwà burúkú,+Nítorí òdodo ló ń fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ gbọn-in.+ 13  Ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́ ìdùnnú àwọn ọba. Wọ́n fẹ́ràn ẹni tó bá ń sọ òótọ́.+ 14  Ìbínú ọba dà bí òjíṣẹ́ ikú,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n ló ń tù ú lójú.*+ 15  Ẹni tó bá rí ojú rere ọba, ayé onítọ̀hún á ládùn;Ojú rere rẹ̀ dà bíi ṣíṣú òjò ìgbà ìrúwé.+ 16  Ó mà sàn kéèyàn ní ọgbọ́n ju kó ní wúrà o!+ Ó sì dára kéèyàn ní òye ju kó ní fàdákà.+ 17  Láti yẹra fún ohun búburú ni ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin. Ẹni tó bá ń ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀.+ 18  Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun,Ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.+ 19  Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀* láàárín àwọn oníwà pẹ̀lẹ́+Ju kéèyàn pín nínú ẹrù tí àwọn agbéraga kó. 20  Ẹni tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀ràn yóò ṣàṣeyọrí,*Aláyọ̀ sì ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. 21  Ẹni tó ní ọkàn ọgbọ́n ni a ó pè ní olóye,+Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ rere* ń yíni lérò pa dà.+ 22  Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tó ni ín,Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń bá wọn wí. 23  Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye+Ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀. 24  Ọ̀rọ̀ dídùn jẹ́ afárá oyin,Ó dùn mọ́ ọkàn,* ó sì ń wo egungun sàn.+ 25  Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+ 26  Ikùn* lébìrà ló ń mú kó ṣiṣẹ́ kára,Ebi tó ń pa á* sì ń mú kó tẹpá mọ́ṣẹ́.+ 27  Èèyàn tí kò ní láárí máa ń hú ohun tí kò dáa jáde;+Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí iná tó ń jóni.+ 28  Oníwàhálà* máa ń dá ìyapa sílẹ̀,+Abanijẹ́ sì máa ń tú àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+ 29  Oníwà ipá máa ń tan ọmọnìkejì rẹ̀Á sì kó o ṣìnà. 30  Bó ṣe ń ṣẹ́jú ló ń gbèrò ibi. Ó fún ètè rẹ̀ pọ̀ bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ibi. 31  Ewú orí jẹ́ adé ẹwà*+Nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.+ 32  Ẹni tí kì í tètè bínú+ sàn ju akíkanjú ọkùnrin,Ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀* sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.+ 33  Orí itan ni à ń ṣẹ́ kèké lé,+Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìpinnu tí ó bá ṣe ti wá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìdáhùn tí ó tọ́.” Ní Héb., “ìdáhùn ahọ́n.”
Ní Héb., “Èèyàn ló máa ń ṣètò ọkàn.”
Ní Héb., “mọ́.”
Ní Héb., “ẹ̀mí.”
Ní Héb., “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”
Ní Héb., “Ọwọ́ sí ọwọ́.”
Tàbí “Ìpinnu àtọ̀runwá.”
Tàbí “ń yẹra fún un.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ẹni tó rẹlẹ̀ ní ẹ̀mí.”
Ní Héb., “rí ire.”
Tàbí “tó ń tuni lára.” Ní Héb., “tó sì ní ètè dídùn.”
Tàbí “Ó dùn lẹ́nu.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn.”
Ní Héb., “Ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “Elétekéte.”
Tàbí “ògo.”
Ní Héb., “ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀.”