Sáàmù 94:1-23

  • Àdúrà pé kí Ọlọ́run gbẹ̀san

    • ‘Ìgbà wo ni àwọn ẹni burúkú máa wà dà?’ (3)

    • Ìtọ́sọ́nà Jáà ń fúnni láyọ̀ (12)

    • Ọlọ́run ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì (14)

    • ‘Fífi òfin bojú láti dáná ìjàngbọ̀n’ (20)

94  Jèhófà, Ọlọ́run ẹ̀san,+Ìwọ Ọlọ́run ẹ̀san, máa tàn yanran!   Dìde, ìwọ Onídàájọ́ ayé.+ San àwọn agbéraga ní ẹ̀san tó yẹ wọ́n.+   Ìgbà wo, Jèhófà,Ìgbà wo ni àwọn ẹni burúkú ò ní yọ̀ mọ́?+   Wọ́n ń sọ̀rọ̀ yàùyàù, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga;Gbogbo àwọn aṣebi ń fọ́nnu nípa ara wọn.   Jèhófà, wọ́n tẹ àwọn èèyàn rẹ mọ́lẹ̀,+Wọ́n sì ń fìyà jẹ ogún rẹ.   Wọ́n pa opó àti àjèjì,Wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìníbaba.   Wọ́n ń sọ pé: “Jáà kò rí i;+Ọlọ́run Jékọ́bù kò kíyè sí i.”+   Ẹ jẹ́ kó yé yín, ẹ̀yin aláìnírònú;Ẹ̀yin òmùgọ̀, ìgbà wo lẹ máa ní ìjìnlẹ̀ òye?+   Ẹni tó dá* etí, ṣé kò lè gbọ́ràn ni? Ẹni tó dá ojú, ṣé kò lè ríran ni?+ 10  Ẹni tó ń tọ́ àwọn orílẹ̀-èdè sọ́nà, ṣé kò lè báni wí ni?+ Òun ló ń fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀!+ 11  Jèhófà mọ èrò àwọn èèyàn,Ó mọ̀ pé èémí lásán ni wọ́n.+ 12  Aláyọ̀ ni ẹni tí o tọ́ sọ́nà, Jáà,+Ẹni tí o kọ́ ní òfin rẹ,+ 13  Kí o lè fún un ní ìsinmi ní ọjọ́ àjálù,Títí a ó fi gbẹ́ kòtò fún ẹni burúkú.+ 14  Nítorí Jèhófà ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì,+Kò sì ní fi ogún rẹ̀ sílẹ̀.+ 15  A ó tún pa dà máa ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo,Gbogbo àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin yóò sì máa tẹ̀ lé e. 16  Ta ló máa bá mi dìde sí ẹni burúkú? Ta ló máa gbèjà mi níwájú àwọn aṣebi? 17  Tí kì í bá ṣe ti Jèhófà tó ràn mí lọ́wọ́,Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ ni ǹ bá* ti ṣègbé.*+ 18  Nígbà tí mo sọ pé: “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀,”Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ló ń gbé mi ró.+ 19  Nígbà tí àníyàn* bò mí mọ́lẹ̀,*O tù mí nínú, o sì tù mí lára.*+ 20  Ṣé ìtẹ́* ìwà ìbàjẹ́ lè ní nǹkan ṣe pẹ̀lú rẹNígbà tó ń fi òfin bojú láti* dáná ìjàngbọ̀n?+ 21  Wọ́n ń ṣe àtakò tó lágbára sí olódodo,*+Wọ́n sì ń dájọ́ ikú fún aláìṣẹ̀.*+ 22  Àmọ́ Jèhófà máa di ibi ààbò* fún mi,Ọlọ́run mi ni àpáta ààbò mi.+ 23  Yóò mú kí iṣẹ́ ibi wọn dà lé wọn lórí.+ Yóò fi iṣẹ́ ibi wọn pa wọ́n run.* Jèhófà Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “gbin.”
Ní Héb., “ti máa gbé inú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”
Tàbí “ọkàn mi ì bá.”
Tàbí “ìrònú tó ń gbéni lọ́kàn sókè.”
Tàbí “pọ̀ nínú mi.”
Tàbí “Ìtùnú rẹ tu ọkàn mi lára.”
Tàbí “àwọn alákòóso tó ní; àwọn onídàájọ́ tó ní.”
Tàbí “fi àṣẹ.”
Ní Héb., “Wọ́n dá ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ lẹ́bi (pe ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní burúkú).”
Tàbí “sí ọkàn olódodo.”
Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”
Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”
Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”