Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 12

Ìrètí Wo Ló Wà Fún Àwọn Tó Ti Kú?

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí èyí yà yín lẹ́nu, torí wákàtí náà ń bọ̀, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, tí wọ́n á sì jáde wá.”

Jòhánù 5:28, 29

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”

Ìṣe 24:15

“Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni. A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí. Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.”

Ìfihàn 20:12, 13