Sáàmù 36:1-12

  • Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣeyebíye

    • Ẹni burúkú kì í bẹ̀rù Ọlọ́run (1)

    • Ọlọ́run ni orísun ìyè (9)

    • “Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀” (9)

Sí olùdarí. Ti Dáfídì, ìránṣẹ́ Jèhófà. 36  Ẹ̀ṣẹ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn ẹni burúkú;Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lójú rẹ̀.+   Ó ń pọ́n ara rẹ̀ lé ju bó ṣe yẹ lọDébi pé kò rí àṣìṣe ara rẹ̀, kí ó sì kórìíra rẹ̀.+   Ọ̀rọ̀ ìkà àti ẹ̀tàn ló wà lẹ́nu rẹ̀;Kì í ronú bó ṣe máa ṣe rere.   Ó máa ń gbèrò ibi, kódà lórí ibùsùn rẹ̀. Ọ̀nà tí kò dáa ló forí lé;Kì í kọ ohun búburú sílẹ̀.   Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run,+Òtítọ́ rẹ ga títí dé àwọsánmà.   Òdodo rẹ dà bí àwọn òkè ńlá;*+Àwọn ìdájọ́ rẹ dà bí alagbalúgbú ibú omi.+ Àti èèyàn àti ẹranko ni ò ń dá sí,* Jèhófà.+   Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run!+ Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹNi àwọn ọmọ èèyàn fi ṣe ibi ààbò.+   Wọ́n ń mu àwọn ohun tó dára jù lọ ní* ilé rẹ ní àmutẹ́rùn,+O sì mú kí wọ́n máa mu nínú adùn rẹ tó ń ṣàn bí odò.+   Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;+Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀.+ 10  Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́,+Àti òdodo rẹ sí àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+ 11  Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn agbéraga tẹ̀ mí mọ́lẹ̀Tàbí kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú lé mi dà nù. 12  Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;A ti là wọ́n mọ́lẹ̀, wọn kò sì lè dìde.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “dà bí àwọn òkè Ọlọ́run.”
Tàbí “gbà là.”
Ní Héb., “mu ọ̀rá.”