Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A1

Ìlànà Tó Wà fún Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Bíbélì

Èdè Hébérù, Gíríìkì àti Árámáíkì àtijọ́ ni wọ́n fi kọ Bíbélì. Lóde òní, Bíbélì ti wà lódindi tàbí lápá kan ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èdè. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ń ka Bíbélì ni ò gbọ́ àwọn èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ níbẹ̀rẹ̀, torí náà wọ́n nílò Bíbélì tí a tú sí èdè wọn. Àwọn ìlànà wo ló yẹ kí àwọn tó bá fẹ́ túmọ̀ Bíbélì tẹ̀ lé, báwo làwọn tó túmọ̀ Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sì ṣe tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí?

Àwọn kan lè gbà pé Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, bó ṣe wà nínú èdè tí wọ́n ń tú gẹ́lẹ́ ló máa jẹ́ kí ẹni tó bá ń kà á lè mọ ohun tó wà nínú èdè tí wọ́n fi kọ ọ́ níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò fi gbogbo ìgbà rí bẹ́ẹ̀. Wo díẹ̀ lára ohun tó fà á:

  • Kò sí èdè méjì tí gírámà wọn, ọ̀rọ̀ wọn tàbí gbólóhùn wọn bára mu délẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú èdè Hébérù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ S. R. Driver sọ nínú ìwé rẹ̀ pé èdè “yàtọ̀ síra tó bá kan ti gírámà àti ibi tí ọ̀rọ̀ ti wá, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan . . . ó tún yàtọ̀ nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ ọ̀rọ̀ di gbólóhùn.” Bí wọ́n ṣe ń ronú ní èdè kan yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń ronú ní èdè míì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Driver ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ pé, “Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí gbólóhùn ṣe máa ń rí nínú èdè kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra.”

  • Kò sí èdè òde òní kankan tó jọra délẹ̀délẹ̀ pẹ̀lú èdè Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì nínú ọ̀rọ̀ àti gírámà, torí náà, Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan lè má ṣe kedere, ó tiẹ̀ tún lè gbé ìtúmọ̀ tí kò tọ̀nà síni lọ́kàn nígbà míì.

  • Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí gbólóhùn kan lè yí pa dà torí àwọn ọ̀rọ̀ tó yí i ká.

Atúmọ̀ èdè kan lè túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì láwọn apá ibì kan ní tààràtà, àmọ́ ó gba pé kéèyàn fara balẹ̀ ṣe é.

Àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé tó fi hàn pé èèyàn lè ṣi èdè tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan lóye:

  • Ìwé Mímọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “sùn” láti tọ́ka sí oorun lásán àti oorun ikú. (Mátíù 28:13; Ìṣe 7:60) Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá jẹyọ níbi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ikú, àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì lè lo ọ̀rọ̀ bíi “sùn nínú ikú,” èyí á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà ṣe kedere sí àwọn tó ń ka Bíbélì lóde òní.—1 Kọ́ríńtì 7:39; 1 Tẹsalóníkà 4:13; 2 Pétérù 3:4.

  • Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ kan tó wà ní Éfésù 4:14 tí a lè túmọ̀ ní tààràtà sí “nínú títa ayò àwọn èèyàn.” Àkànlò èdè àtijọ́ yìí jẹ mọ́ bí wọ́n ṣe máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ nídìí ayò. Lọ́pọ̀ èdè, ọ̀rọ̀ yìí kì í fi bẹ́ẹ̀ mọ́gbọ́n dání tí wọ́n bá túmọ̀ rẹ̀ ní tààràtà. Àmọ́ bí a ṣe tú ọ̀rọ̀ yìí sí “ẹ̀tàn àwọn èèyàn” mú kí ìtúmọ̀ rẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere.

  • Nínú Róòmù 12:11, wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó túmọ̀ ní tààràtà sí “sí ẹ̀mí tó ń hó.” Ọ̀rọ̀ yìí ò gbé ìtumọ̀ yẹn gangan yọ lédè Yorùbá, torí náà, nínú ìtumọ̀ Bíbélì yìí, a lo “kí iná ẹ̀mí máa jó.”

  • MÁTÍÙ 5:3

    Ìtumọ̀ tààrà: “òtòṣì ní ẹ̀mí”

    Èrò: “àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run”

    Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè, èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, Jésù lo ọ̀rọ̀ kan táwọn atúmọ̀ èdè sábà máa ń tú sí “Alábùkún-fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí.” (Mátíù 5:3, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́ lọ́pọ̀ èdè, kì í yéni dáadáa tí wọ́n bá túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ní tààràtà. Láwọn ìgbà míì, tí wọ́n bá túmọ̀ rẹ̀ ní tààràtà bó ṣe rí gan-an, ó lè túmọ̀ sí pé “òtòṣì ní ẹ̀mí” jẹ́ ẹni tó níṣòro ọpọlọ tàbí tí kò lókun inú, tí kò sì lè dá ìpinnu ṣe. Àmọ́, ohun tí Jésù ń fi ọ̀rọ̀ yìí kọ́ àwọn èèyàn ni pé, kì í ṣe ìgbà téèyàn bá rí àwọn nǹkan tara tó nílò ló máa tó lè láyọ̀, ìgbà tó bá rí ìdí tó fi yẹ kó máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ló máa tó láyọ̀. (Lúùkù 6:20) Torí náà, àwọn ọ̀rọ̀ bí “àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run” tàbí “àwọn tó mọ̀ pé àwọn nílò Ọlọ́run” túbọ̀ gbé ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn gangan yọ lọ́nà tó ṣe kedere.—Mátíù 5:3; The New Testament in Modern English.

  • Lọ́pọ̀ ibi tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “owú,” ó bá ìtumọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa lédè Yorùbá mu, ìyẹn ni pé kéèyàn bínú lórí ìwà àìṣòótọ́ tí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan hù tàbí kéèyàn máa jowú ẹnì kan torí ohun tó ní. (Òwe 6:34; Àìsáyà 11:13) Àmọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù yìí tún lè túmọ̀ sí ohun tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè lò ó fún “ìtara” tàbí ìfẹ́ láti dáàbò boni, irú èyí tí Jèhófà fi hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tàbí bó ṣe fẹ́ “kí a jọ́sìn òun nìkan.” (Ẹ́kísódù 34:14; 2 Àwọn Ọba 19:31; Ìsíkíẹ́lì 5:13; Sekaráyà 8:2) A tún lè lò ó fún “ìtara” tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní fún Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀ tàbí pé kéèyàn má ‘fàyè gba bíbá Ọlọ́run díje.’—Sáàmù 69:9; 119:139; Nọ́ńbà 25:11.

  • Wọ́n sábà máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà yadh sí “ọwọ́,” àmọ́ ibi tí wọ́n ti lò ó lè mú kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “àkóso,” kéèyàn ‘fúnni’ ní nǹkan, “agbára” tàbí àwọn ọ̀rọ̀ míì

    Ọ̀rọ̀ Hébérù tó sábà máa ń tọ́ka sí ọwọ́ èèyàn ní ìtumọ̀ tó pọ̀. Ibi tí wọ́n ti lò ó lè mú kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí “àkóso,” kéèyàn ‘fúnni’ ní nǹkan tàbí “agbára.” (2 Sámúẹ́lì 8:3; 1 Àwọn Ọba 10:13; Òwe 18:21) Kódà, ó lé ní ogójì (40) ọ̀nà tí a gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Nítorí àwọn ìdí yìí, iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì kọjá kéèyàn kàn máa lo ọ̀rọ̀ kan náà láti fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní gbogbo ibi tí ọ̀rọ̀ náà ti fara hàn. Atúmọ̀ èdè gbọ́dọ̀ fi làákàyè yan àwọn ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ tó sì ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì. Bákan náà, ó tún lè gba pé kó tún àwọn gbólóhùn tò lọ́nà tó bá ìlànà gírámà èdè tó ń túmọ̀ mu, èyí á sì mú kó rọrùn láti kà.

Lẹ́sẹ̀ kan náà, èèyàn gbọ́dọ̀ yẹra fún àṣejù tó bá dọ̀rọ̀ pé ká yí àwọn ọ̀rọ̀ pa dà. Atúmọ̀ èdè tó bá ń túmọ̀ Bíbélì lóréfèé nítorí ìwọ̀nba ohun tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan lè dojú ọ̀rọ̀ náà rú. Lọ́nà wo? Atúmọ̀ èdè náà lè ki èrò tara rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà bọnú ìtúmọ̀ tó ń ṣe tàbí kó fo àwọn ohun pàtàkì kan tó wà nínú èdè tó ń tú. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lóréfèé lè dùn ún kà, àwọn ọ̀rọ̀ inú wọn nígbà míì lè má jẹ́ kí ẹni tó bá ń kà wọ́n rí kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀.

Ohun tí atúmọ̀ èdè kan kọ́ nínú ẹ̀sìn rẹ̀ lè ní ipa lórí ìtúmọ̀ tó máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Mátíù 7:13 sọ pé: ‘Ọ̀nà tó lọ sí ìparun gbòòrò.’ Àwọn atúmọ̀ èdè kan lo “ọ̀run àpáàdì,” bóyá nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, dípò kí wọ́n lo “ìparun” tó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó wà níbẹ̀.

Ẹni tó bá ń túmọ̀ Bíbélì tún gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn bí àgbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn àti apẹja ni wọ́n fi kọ Bíbélì. (Nehemáyà 8:8, 12; Ìṣe 4:13) Torí náà, tí wọ́n bá túmọ̀ Bíbélì kan dáadáa, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ máa ṣe kedere sí àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́, láìka irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ sí. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere, tó wọ́pọ̀, tó sì rọrùn lóye dáa ju àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ lò.

Nínú àwọn Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ lóde òní, àwọn atúmọ̀ èdè kan ti dìídì yọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, kúrò láìnídìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé orúkọ náà wà nínú àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ àtijọ́. (Wo Àfikún A4.) Ọ̀pọ̀ atúmọ̀ èdè ló fi orúkọ oyè bí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀, kódà àwọn míì ò tiẹ̀ jẹ́ kó hàn pé Ọlọ́run ní orúkọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan, àdúrà Jésù tó wà ní Jòhánù 17:26 kà báyìí pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́.” Bákan náà, ní Jòhánù 17:6, ó kà pé: “Mo ti fi ọ́ han àwọn tí o fún mi.” Àmọ́, ìtúmọ̀ kan tó péye nípa àdúrà Jésù kà pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ” àti pé “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi.”

Bí a ṣe sọ nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú ẹ̀dà àkọ́kọ́ Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì pé: “A ò túmọ̀ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lóréfèé. A sapá gan-an láti rí i pé a túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ìyẹn láwọn ibi tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì òde òní bá ti gbà wá láyè àti láwọn ibi tí títúmọ̀ ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan kò bá ti ní jẹ́ kó ṣòro láti lóye gbólóhùn náà.” Torí náà, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun sapá gan-an láti má fì sápá kan nínú lílo àwọn ọ̀rọ̀ àti títò wọ́n bó ṣe wà nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n sapá láti yẹra fún lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí ò ní dùn-ún kà tàbí tí ò ní jẹ́ kí ìtumọ̀ ṣe kedere. Èyí ti mú kí Bíbélì náà rọrùn láti kà, kó sì dá ẹni tó bá ń kà á lójú pé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ló wà nínú rẹ̀.—1 Tẹsalóníkà 2:13.