Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 16

Kí Lo Lè Ṣe Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmú?

“Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú láé.”

Sáàmù 55:22

“Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere, àmọ́ ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.”

Òwe 21:5

“Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́, ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.”

Àìsáyà 41:10

“Èwo nínú yín ló lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwàláàyè rẹ̀, tó bá ń ṣàníyàn?”

Mátíù 6:27

“Torí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”

Mátíù 6:34

“Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”

Fílípì 1:10

“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”

Fílípì 4:6, 7