Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 6

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, . . . inú rẹ ni ẹni tí mo fẹ́ kó ṣàkóso Ísírẹ́lì ti máa jáde wá.”

Míkà 5:2

ÌMÚṢẸ

“Lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Ọba Hẹ́rọ́dù, wò ó! àwọn awòràwọ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù láti Ìlà Oòrùn.”

Mátíù 2:1

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”

Sáàmù 22:18

ÌMÚṢẸ

“Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n pín in sí mẹ́rin . . . Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà ò ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.’”

Jòhánù 19:23, 24

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀; kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.”

Sáàmù 34:20

ÌMÚṢẸ

“Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n rí i pé ó ti kú, torí náà, wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Jòhánù 19:33

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Wọ́n gún un torí àṣìṣe wa.”

Àìsáyà 53:5

ÌMÚṢẸ

“Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Jòhánù 19:34

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Wọ́n . . . san owó iṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.”

Sekaráyà 11:12, 13

ÌMÚṢẸ

“Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Méjìlá náà, tí wọ́n ń pè ní Júdásì Ìsìkáríọ́tù, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, ó sì sọ pé: ‘Kí lẹ máa fún mi, kí n lè fà á lé yín lọ́wọ́?’ Wọ́n bá a ṣe àdéhùn ọgbọ̀n (30) ẹyọ fàdákà.”

Mátíù 26:14, 15; 27:5