Sáàmù 86:1-17

  • Kò sí ọlọ́run tó dà bíi Jèhófà

    • Jèhófà ṣe tán láti dárí jini (5)

    • Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò jọ́sìn Jèhófà (9)

    • “Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ” (11)

    • “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀” (11)

Àdúrà Dáfídì. 86  Fetí sílẹ̀,* Jèhófà, kí o sì dá mi lóhùn,Nítorí pé ìyà ń jẹ mí, mo sì jẹ́ aláìní.+   Ṣọ́ ẹ̀mí* mi, torí pé adúróṣinṣin+ ni mí. Gba ìránṣẹ́ rẹ tó gbẹ́kẹ̀ lé ọ là,Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.+   Ṣojú rere sí mi, Jèhófà,+Nítorí ìwọ ni mò ń ké pè láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+   Mú kí ìránṣẹ́ rẹ* máa yọ̀,Nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo yíjú* sí, Jèhófà.   Nítorí pé ẹni rere ni ọ́,+ Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini;+Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.+   Jèhófà, gbọ́ àdúrà mi;Sì fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+   Mo ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi,+Torí mo mọ̀ pé wàá dá mi lóhùn.+   Jèhófà, kò sí èyí tó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run,+Kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.+   Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí o dáYóò wá forí balẹ̀ níwájú rẹ, Jèhófà,+Wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ.+ 10  Nítorí ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu;+Ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo.+ 11  Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ.+ Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.+ Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀* kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.+ 12  Mo fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi,+Màá sì máa yin orúkọ rẹ lógo títí láé, 13  Nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí mi pọ̀,O sì ti gba ẹ̀mí* mi lọ́wọ́ Isà Òkú.*+ 14  Ọlọ́run, àwọn agbéraga dìde sí mi;+Àwùjọ ìkà ẹ̀dá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* mi,Wọn ò sì kà ọ́ sí.*+ 15  Àmọ́ ní tìrẹ, Jèhófà, o jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò,*Tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òdodo* rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+ 16  Yíjú sí mi, kí o sì ṣojú rere sí mi.+ Fún ìránṣẹ́ rẹ ní agbára,+Kí o sì gba ọmọ ẹrúbìnrin rẹ là. 17  Fún mi ní àmì* oore rẹ,Kí àwọn tó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n. Nítorí ìwọ Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi àti olùtùnú mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn ìránṣẹ́ rẹ.”
Tàbí “gbé ọkàn mi.”
Tàbí “Mú ọkàn mi ṣọ̀kan.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Wọn ò fi tìrẹ pè.”
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Tàbí “òtítọ́.”
Tàbí “ẹ̀rí.”