Sáàmù 31:1-24
Sí olùdarí. Orin Dáfídì.
31 Jèhófà, ìwọ ni mo fi ṣe ibi ààbò mi.+
Kí ojú má tì mí láé.+
Gbà mí sílẹ̀ nítorí òdodo rẹ.+
2 Tẹ́tí sí mi.*
Tètè wá gbà mí sílẹ̀.+
Di àpáta ààbò fún mi,Ibi olódi láti gbà mí sílẹ̀.+
3 Ìwọ ni àpáta mi àti ibi ààbò mi;+Wàá darí mi,+ wàá sì ṣamọ̀nà mi, nítorí orúkọ rẹ.+
4 Wàá yọ mí kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pa mọ́ dè mí,+Nítorí pé ìwọ ni odi ààbò mi.+
5 Ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.+
O ti rà mí pa dà, Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́.*+
6 Mo kórìíra àwọn tó ń bọ òrìṣà asán, tí kò ní láárí,Àmọ́ ní tèmi, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.
7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ yóò máa mú inú mi dùn gidigidi,Nítorí o ti rí ìpọ́njú mi;+O mọ ìdààmú ńlá tó bá mi.*
8 O kò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,Àmọ́ o mú kí n dúró ní ibi ààbò.*
9 Ṣojú rere sí mi, Jèhófà, torí mo wà nínú ìdààmú.
Ìrora ti sọ ojú mi di bàìbàì,+ àárẹ̀ sì ti bá gbogbo ara mi.*+
10 Ẹ̀dùn ọkàn+ ti gba ayé mi kan,Ìrora ni mo sì fi ń lo ọdún ayé mi.+
Agbára mi ń tán lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi;Àárẹ̀ ti mú egungun mi.+
11 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ń fi mí ṣẹ̀sín,+Pàápàá àwọn aládùúgbò mi.
Mo ti di ẹni àríbẹ̀rù lójú àwọn ojúlùmọ̀ mi;Tí wọ́n bá rí mi lóde, ṣe ni wọ́n ń sá fún mi.+
12 Mi ò sí lọ́kàn wọn mọ́,* wọ́n sì ti gbàgbé mi, àfi bíi pé mo ti kú;Mo dà bí ìkòkò tó fọ́.
13 Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àhesọ burúkú;Àwọn ohun ẹ̀rù yí mi ká.+
Nígbà tí wọ́n kóra jọ lé mi lórí,Wọ́n gbèrò láti gba ẹ̀mí* mi.+
14 Àmọ́ Jèhófà, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé.+
Mo sọ pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.”+
15 Ọwọ́ rẹ ni ọjọ́ ayé* mi wà.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi àti lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí mi.+
16 Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ.+
Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ gbà mí sílẹ̀.
17 Jèhófà, kí ojú má tì mí nígbà tí mo bá ké pè ọ́.+
Kí ojú ti àwọn ẹni burúkú;+Kí wọ́n dákẹ́ sínú Isà Òkú.*+
18 Kí kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn òpùrọ́ lẹ́nu,+Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga àti ẹ̀gàn sí àwọn olódodo.
19 Oore rẹ mà pọ̀ o!+
O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ,+O sì ti fi wọ́n hàn lójú gbogbo èèyàn, nítorí àwọn tó fi ọ́ ṣe ibi ààbò.+
20 Wàá fi wọ́n pa mọ́ sí ibi ìkọ̀kọ̀ tó wà níwájú rẹ+Kúrò nínú rìkíṣí àwọn èèyàn;Wàá fi wọ́n pa mọ́ sínú àgọ́ rẹKúrò lọ́wọ́ àwọn abanijẹ́.*+
21 Ìyìn ni fún Jèhófà,Nítorí ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi lọ́nà àgbàyanu+ ní ìlú tí ọ̀tá dó tì.+
22 Ní tèmi, jìnnìjìnnì bò mí, mo sì sọ pé:
“Màá ṣègbé níwájú rẹ.”+
Àmọ́ nígbà tí mo ké pè ọ́, o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.+
23 Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ adúróṣinṣin sí i!+
Jèhófà ń dáàbò bo àwọn olóòótọ́,+Àmọ́ ó máa ń san èrè tó kún rẹ́rẹ́ fún àwọn tó bá ń gbéra ga.+
24 Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì mọ́kàn le,+Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dúró de Jèhófà.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Bẹ̀rẹ̀ kí o sì fetí sí mi.”
^ Tàbí “Ọlọ́run olóòótọ́.”
^ Tàbí “ìdààmú ọkàn mi.”
^ Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
^ Tàbí “ọkàn mi àti ikùn mi.”
^ Tàbí “Wọn ò fiyè sí mi mọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “àwọn àkókò.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “lọ́wọ́ ìjà ahọ́n.”