Sáàmù 72:1-20

  • Àkóso Ọba tí Ọlọ́run yàn máa mú àlááfíà wá

    • “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀” (7)

    • Àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun (8)

    • Yóò gbani lọ́wọ́ ìwà ipá (14)

    • Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ lórí ilẹ̀ (16)

    • A ó máa yin orúkọ Ọlọ́run títí láé (19)

Nípa Sólómọ́nì. 72  Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+   Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ rò,Kí ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní.+   Kí àwọn òkè ńlá fún àwọn èèyàn ní àlàáfíà,Kí àwọn òkè kéékèèké sì mú òdodo wá.   Kí ó gbèjà* àwọn tó jẹ́ aláìní,Kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là,Kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.+   Láti ìran dé ìran,Wọ́n á máa bẹ̀rù rẹ níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà,Tí òṣùpá sì ń yọ.+   Yóò dà bí òjò tó ń rọ̀ sórí koríko tí a gé,Bí ọ̀wààrà òjò tó ń mú kí ilẹ̀ rin.+   Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀,*+Àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀+ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.   Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́* láti òkun dé òkunÀti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+   Àwọn tó ń gbé ní aṣálẹ̀ yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò sì lá erùpẹ̀.+ 10  Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù yóò máa san ìṣákọ́lẹ̀.*+ Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà yóò mú ẹ̀bùn wá.+ 11  Gbogbo àwọn ọba yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa sìn ín. 12  Nítorí yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,Yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. 13  Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà,Yóò sì gba ẹ̀mí* àwọn tálákà là. 14  Yóò gbà wọ́n* lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá,Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye lójú rẹ̀. 15  Kí ó máa wà láàyè, kí a sì fún un ní wúrà Ṣébà.+ Kí a máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo,Kí a sì máa bù kún un láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. 16  Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ* máa wà lórí ilẹ̀;+Ó máa kún àkúnwọ́sílẹ̀ lórí àwọn òkè. Èso rẹ̀ máa dára bíi ti Lẹ́bánónì,+Nínú àwọn ìlú, àwọn èèyàn máa pọ̀ bí ewéko ilẹ̀.+ 17  Kí orúkọ rẹ̀ wà títí láé,+Kí ó sì máa lókìkí níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ṣì wà. Kí àwọn èèyàn gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀;+Kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀. 18  Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+Òun nìkan ló ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu.+ 19  Kí á yin orúkọ rẹ̀ ológo títí láé,+Kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ayé.+ Àmín àti Àmín. 20  Ibí ni àdúrà Dáfídì, ọmọ Jésè+ parí sí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “dá ẹjọ́.”
Ní Héb., “rú jáde.”
Tàbí “ṣàkóso.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Tàbí “owó òde.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ra ọkàn wọn pa dà.”
Tàbí “ọkà.”