Sáàmù 83:1-18

  • Àdúrà ìgbà tí èèyàn bá ń kojú ọ̀tá

    • “Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́” (1)

    • Àwọn ọ̀tá dà bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo (13)

    • Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run (18)

Orin. Orin Ásáfù.+ 83  Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;+Má ṣàìsọ̀rọ̀,* má sì dúró jẹ́ẹ́, ìwọ Olú Ọ̀run.   Wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú rúkèrúdò;+Àwọn tó kórìíra rẹ ń hùwà ìgbéraga.*   Wọ́n fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n gbìmọ̀ pọ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ;Wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ nítorí àwọn àyànfẹ́ rẹ.*   Wọ́n sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọ́n run kí wọ́n má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+Kí a má sì rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”   Wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe;*Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀* láti bá ọ jà,+   Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti àwọn ọmọ Hágárì,+   Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì,Filísíà+ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ní Tírè.+   Ásíríà+ pẹ̀lú ti dara pọ̀ mọ́ wọn;Wọ́n ran àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì+ lọ́wọ́.* (Sélà)   Kí o ṣe wọ́n bí o ti ṣe Mídíánì,+Bí o ti ṣe Sísérà àti Jábínì ní odò* Kíṣónì.+ 10  Wọ́n pa run ní Ẹ́ń-dórì;+Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀. 11  Ṣe àwọn èèyàn pàtàkì wọn bí Órébù àti Séébù,+Kí o sì ṣe àwọn olórí* wọn bíi Séébà àti Sálímúnà,+ 12  Nítorí wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ilẹ̀ tí Ọlọ́run ń gbé.” 13  Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo,*+Bí àgékù pòròpórò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. 14  Bí iná tó ń jó igbóÀti bí ọwọ́ iná tó ń jó àwọn òkè,+ 15  Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ kó jìnnìjìnnì bá wọn.+ 16  Fi àbùkù bò wọ́n lójú,*Kí wọ́n lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà. 17  Kí ojú tì wọ́n, kí jìnnìjìnnì sì bá wọn títí láé;Kí wọ́n tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé; 18  Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Má pa ẹnu mọ́.”
Tàbí “ń gbé orí wọn sókè.”
Ní Héb., “àwọn tí o fi pa mọ́.”
Tàbí “dá májẹ̀mú.”
Ní Héb., “Wọ́n jọ gbàmọ̀ràn pẹ̀lú ọkàn kan.”
Ní Héb., “Wọ́n ti di apá fún àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì.”
Tàbí “àfonífojì.”
Tàbí “àwọn aṣáájú.”
Tàbí “ewéko gbígbẹ tí atẹ́gùn ń gbé kiri.”
Ní Héb., “kún ojú wọn.”