Sáàmù 23:1-6
Orin Dáfídì.
23 Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.+
Èmi kì yóò ṣaláìní.+
2 Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní ibi ìjẹko tútù;Ó darí mi sí àwọn ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.*+
3 Ó tù mí* lára.+
Ó darí mi ní ipa ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀.+
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn nínú àfonífojì tó ṣókùnkùn biribiri,+Mi ò bẹ̀rù ewukéwu,+Nítorí o wà pẹ̀lú mi;+Ọ̀gọ* rẹ àti ọ̀pá rẹ ń fi mí lọ́kàn balẹ̀.*
5 O tẹ́ tábìlì fún mi níwájú àwọn ọ̀tá mi.+
O fi òróró pa orí mi;*+Ife mi kún dáadáa.+
6 Dájúdájú, ire àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,+Èmi yóò sì máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí kó jẹ́, “síbi omi tó pa rọ́rọ́.”
^ Tàbí “Ó tu ọkàn mi.”
^ Tàbí “ń tù mí nínú.”
^ Ìyẹn, ọ̀pá tí orí rẹ̀ rí rubutu.
^ Tàbí “tu orí mi lára.”