Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 19

Kí Ló Wà Nínú Oríṣiríṣi Ìwé Tó Para Pọ̀ Di Bíbélì?

ÌWÉ MÍMỌ́ LÉDÈ HÉBÉRÙ (“MÁJẸ̀MÚ LÁÉLÁÉ”)

ÌWÉ MÁRÙN-ÚN ÀKỌ́KỌ́:

Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Nọ́ńbà, Diutarónómì

Ìtàn látìgbà ìṣẹ̀dá títí tá a fi dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀

ÀWỌN ÌWÉ ÌTÀN (ÌWÉ MÉJÌLÁ):

Jóṣúà, Àwọn Onídàájọ́, Rúùtù

Ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà

1 Sámúẹ́lì àti 2 Sámúẹ́lì, 1 Àwọn Ọba àti 2 Àwọn Ọba, 1 Kíróníkà àti 2 Kíróníkà

Ìtàn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì títí dìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run

Ẹ́sírà, Nehemáyà, Ẹ́sítà

Ìtàn àwọn Júù lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì

ÀWỌN ÌWÉ EWÌ (ÌWÉ MÁRÙN-ÚN):

Jóòbù, Sáàmù, Òwe, Oníwàásù, Orin Sólómọ́nì

Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àtàwọn orin

ÀWỌN ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀ (ÌWÉ MẸ́TÀDÍNLÓGÚN):

Àìsáyà, Jeremáyà, Ìdárò, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì, Hósíà, Jóẹ́lì, Émọ́sì, Ọbadáyà, Jónà, Míkà, Náhúmù, Hábákúkù, Sefanáyà, Hágáì, Sekaráyà, Málákì

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó kan àwọn èèyàn Ọlọ́run

ÌWÉ MÍMỌ́ KRISTẸNI LÉDÈ GÍRÍÌKÌ (“MÁJẸ̀MÚ TUNTUN”)

ÀWỌN ÌWÉ ÌHÌN RERE (ÌWÉ MẸ́RIN):

Mátíù, Máàkù, Lúùkù, Jòhánù

Ìtàn ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù

ÌṢE ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ (ÌWÉ KAN):

Ìtàn bí ìjọ Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ àti iṣẹ́ àwọn míṣọ́nnárì

ÀWỌN LẸ́TÀ (ÌWÉ MỌ́KÀNLÉLÓGÚN):

Róòmù, 1 Kọ́ríńtì àti 2 Kọ́ríńtì, Gálátíà, Éfésù, Fílípì, Kólósè, 1 Tẹsalóníkà àti 2 Tẹsalóníkà

Lẹ́tà sáwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

1 Tímótì àti 2 Tímótì, Títù, Fílémónì

Lẹ́tà sáwọn Kristẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Hébérù, Jémíìsì, 1 Pétérù àti 2 Pétérù, 1 Jòhánù, 2 Jòhánù àti 3 Jòhánù, Júùdù

Lẹ́tà sí gbogbo Kristẹni

ÌFIHÀN (ÌWÉ KAN):

Oríṣiríṣi ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n fi han àpọ́sítélì Jòhánù