Sáàmù 37:1-40

  • Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò láásìkí

    • Má ṣe banú jẹ́ nítorí ẹni ibi (1)

    • “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ nínú Jèhófà” (4)

    • “Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́” (5)

    • “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé” (11)

    • Àwọn olódodo kò ní ṣaláìní oúnjẹ (25)

    • Àwọn olódodo yóò gbé láyé títí láé (29)

Ti Dáfídì. א [Áléfì] 37  Má banú jẹ́* nítorí àwọn ẹni burúkúTàbí kí o jowú àwọn aṣebi.+   Kíákíá ni wọ́n á gbẹ dà nù bíi koríko+Wọ́n á sì rọ bíi koríko tútù. ב [Bétì]   Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere;+Máa gbé ayé,* kí o sì máa hùwà òtítọ́.+   Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ* nínú Jèhófà,Yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́. ג [Gímélì]   Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́;*+Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.+   Yóò mú kí òdodo rẹ yọ bí ọjọ́,Àti ìwà títọ́ rẹ bí oòrùn ọ̀sán gangan. ד [Dálétì]   Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà+Kí o sì dúró* dè é. Má banú jẹ́ nítorí ẹniTó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.+ ה [Híì]   Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì;+Má ṣe bínú kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ibi.*   Nítorí a ó mú àwọn ẹni ibi kúrò,+Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni yóò jogún ayé.+ ו [Wọ́ọ̀] 10  Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́;+ Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,Wọn ò ní sí níbẹ̀.+ 11  Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé,+Inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.+ ז [Sáyìn] 12  Ẹni burúkú ń dìtẹ̀ olódodo;+Ó ń wa eyín pọ̀ sí i. 13  Àmọ́ Jèhófà yóò fi í rẹ́rìn-ín,Nítorí Ó mọ̀ pé ọjọ́ rẹ̀ máa dé.+ ח [Hétì] 14  Àwọn ẹni burúkú fa idà wọn yọ, wọ́n sì tẹ* ọrun wọnLáti mú àwọn tí à ń ni lára àti àwọn aláìní balẹ̀,Láti pa àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́. 15  Àmọ́ idà àwọn fúnra wọn yóò gún ọkàn wọn;+A ó sì ṣẹ́ ọrun wọn. ט [Tétì] 16  Ohun díẹ̀ tí olódodo níSàn ju ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ẹni burúkú ní.+ 17  A ó ṣẹ́ apá àwọn ẹni burúkú,Àmọ́ Jèhófà yóò ti àwọn olódodo lẹ́yìn. י [Yódì] 18  Jèhófà mọ ohun tí àwọn aláìlẹ́bi ń bá yí,*Ogún wọn yóò sì wà títí láé.+ 19  Ní àkókò àjálù, ojú kò ní tì wọ́n;Ní àkókò ìyàn, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. כ [Káfì] 20  Àmọ́ àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé;+Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò pòórá bí ibi ìjẹko tó léwé dáadáa;Wọ́n á pòórá bí èéfín. ל [Lámédì] 21  Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án pa dà,Àmọ́ olódodo lawọ́,* ó sì ń fúnni ní nǹkan.+ 22  Àwọn tí Ọlọ́run bù kún yóò jogún ayé,Àmọ́ àwọn tí Ọlọ́run gégùn-ún fún yóò pa rẹ́.+ מ [Mémì]  23  Jèhófà máa ń darí ẹsẹ̀ ẹni*+Nígbà tí inú Rẹ̀ bá dùn sí ọ̀nà ẹni náà.+  24  Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ṣubú, kò ní balẹ̀ pátápátá,+Nítorí pé Jèhófà dì í lọ́wọ́ mú.*+ נ [Núnì] 25  Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó,Síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì,+Tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ* kiri.+ 26  Ó máa ń yáni ní nǹkan látọkàn wá,+Ìbùkún sì ń dúró de àwọn ọmọ rẹ̀. ס [Sámékì] 27  Yẹra fún ohun búburú, máa ṣe rere,+Wàá sì máa gbé ayé títí láé. 28  Nítorí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo,Kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.+ ע [Áyìn] Ìgbà gbogbo ni yóò máa ṣọ́ wọn;+Àmọ́ a ó pa àtọmọdọ́mọ àwọn ẹni burúkú rẹ́.+  29  Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé,+Wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.+ פ [Péè] 30  Ẹnu olódodo ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,*Ahọ́n rẹ̀ sì ń sọ nípa ìdájọ́ òdodo.+ 31  Òfin Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;+Ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní tàsé.+ צ [Sádì] 32  Ẹni burúkú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. 33  Àmọ́ Jèhófà kò ní jẹ́ kí ọwọ́ ẹni yẹn tẹ̀ ẹ́,+Kò sì ní dá a lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ṣèdájọ́ rẹ̀.+ ק [Kófì] 34  Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀,Yóò gbé ọ ga láti jogún ayé. Nígbà tí a bá pa àwọn ẹni burúkú rẹ́,+ wàá rí i.+ ר [Réṣì] 35  Mo ti rí ìkà ẹ̀dá tó jẹ́ olubiTó ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ tó dàgbà sí.+ 36  Àmọ́, ó kọjá lọ lójijì, kò sì sí mọ́;+Mo wá a kiri, mi ò sì rí i.+ ש [Ṣínì] 37  Máa fiyè sí aláìlẹ́bi,*Kí o sì máa wo adúróṣinṣin,+Nítorí àlàáfíà ń dúró de ẹni yẹn ní ọjọ́ ọ̀la.+ 38  Àmọ́ a ó pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́,Ìparun ló sì ń dúró de àwọn ẹni burúkú ní ọjọ́ ọ̀la.+ ת [Tọ́ọ̀] 39  Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá;+Òun ni odi ààbò wọn ní àkókò wàhálà.+ 40  Jèhófà á ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì gbà wọ́n sílẹ̀.+ Á gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, á sì gbà wọ́n là,Nítorí òun ni wọ́n fi ṣe ibi ààbò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “gbaná jẹ.”
Tàbí “ilẹ̀ náà.”
Tàbí “Ní ayọ̀ tó kọyọyọ.”
Ní Héb., “Yí ọ̀nà rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”
Tàbí “fi sùúrù dúró.”
Tàbí kó jẹ́, “Má ṣe bínú, torí á mú kí o ṣe ibi.”
Tàbí “fi okùn sí.”
Ní Héb., “àwọn ọjọ́ àwọn aláìlẹ́bi.”
Tàbí “ń ṣàánú.”
Tàbí “mú kí ẹsẹ̀ ẹni múlẹ̀.”
Tàbí “fi ọwọ́ Rẹ̀ dì í mú.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n.”
Tàbí “ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”