Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 14

Báwo Lo Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Ohun Ìní Rẹ?

“Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàájì yóò di aláìní; ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kò ní lówó lọ́wọ́.”

Òwe 21:17

“Ẹni tó yá nǹkan . . . ni ẹrú ẹni tó yá a ní nǹkan.”

Òwe 22:7

“Èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà? Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀, àmọ́ kó má lè parí rẹ̀, gbogbo àwọn tó ń wò ó sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n á ní: ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́lé àmọ́ kò lè parí rẹ̀.’”

Lúùkù 14:28-30

“Nígbà tí wọ́n yó, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ kó àwọn ohun tó ṣẹ́ kù jọ, kí ohunkóhun má bàa ṣòfò.’”

Jòhánù 6:12