Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌBÉÈRÈ 10

Kí Ni Bíbélì Ṣèlérí Nípa Ọjọ́ Ọ̀la?

“Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”

Sáàmù 37:29

“Ayé wà títí láé.”

Oníwàásù 1:4

“Ó máa gbé ikú mì títí láé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.”

Àìsáyà 25:8

“Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú máa là, etí àwọn adití sì máa ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì máa kígbe ayọ̀. Torí omi máa tú jáde ní aginjù, odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.”

Àìsáyà 35:5, 6

“Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Ìfihàn 21:4

“Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn. Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé, wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ. Torí pé ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi, àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”

Àìsáyà 65:21, 22