Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwé Sáàmù

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ọ̀nà méjì tó yàtọ̀ síra

      • Kíka òfin Ọlọ́run ń fúnni láyọ̀ (2)

      • Àwọn olódodo dà bí igi eléso (3)

      • Àwọn èèyàn burúkú dà bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ (4)

  • 2

    • Jèhófà àti ẹni àmì òróró rẹ̀

      • Jèhófà ń fi àwọn orílẹ̀-èdè rẹ́rìn-ín (4)

      • Jèhófà fi ọba rẹ̀ jẹ (6)

      • Bọlá fún ọmọ náà (12)

  • 3

    • Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kódà nínú ewu

      • ‘Kí nìdí tí àwọn ọ̀tá fi pọ̀ tó báyìí?’ (1)

      • “Ti Jèhófà ni ìgbàlà” (8)

  • 4

    • Àdúrà ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run

      • “Tí inú bá bí yín, ẹ má ṣẹ̀” (4)

      • ‘Màá sùn ní àlàáfíà’ (8)

  • 5

    • Jèhófà ni ibi ààbò àwọn olódodo

      • Ọlọ́run kórìíra ìwà burúkú (4, 5)

      • “Ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ” (8)

  • 6

    • Ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere

      • Òkú kì í yin Ọlọ́run (5)

      • Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere (9)

  • 7

    • Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà

      • “Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà” (8)

  • 8

    • Ògo Ọlọ́run àti iyì ọmọ èèyàn

      • ‘Orúkọ rẹ mà níyì o!’ (1, 9)

      • ‘Kí ni ẹni kíkú jẹ́?’ (4)

      • A fi ọlá ńlá dé èèyàn ládé (5)

  • 9

    • Ìkéde àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run

      • Jèhófà jẹ́ ibi ààbò tó dájú (9)

      • Mímọ orúkọ Ọlọ́run ń mú ká gbẹ́kẹ̀ lé e (10)

  • 10

    • Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́

      • Ẹni burúkú ń fọ́nnu pé: “Kò sí Ọlọ́run” (4)

      • Àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ ń yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà (14)

      • “Jèhófà ni Ọba títí láé” (16)

  • 11

    • Fífi Jèhófà ṣe ibi ààbò

      • “Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀” (4)

      • Ọlọ́run kórìíra ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá (5)

  • 12

    • Jèhófà dìde láti gbé ìgbésẹ̀

      • Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ (6)

  • 13

    • Dúró de ìgbàlà Jèhófà

      • ‘Títí dìgbà wo, Jèhófà?’ (1, 2)

      • Jèhófà ń san èrè fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀ (6)

  • 14

    • Irú ẹni tí òmùgọ̀ jẹ́

      • “Kò sí Jèhófà” (1)

      • “Kò sí ẹni tó ń ṣe rere” (3)

  • 15

    • Ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà?

      • Ó ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀ (2)

      • Kì í bani jẹ́ (3)

      • Kì í yẹ àdéhùn, kódà tó bá máa pa á lára (4)

  • 16

    • Jèhófà ni Orísun oore

      • “Jèhófà ni ìpín mi” (5)

      • ‘Èrò inú mi ń tọ́ mi sọ́nà láàárín òru’ (7)

      • ‘Jèhófà wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi’ (8)

      • “O ò ní fi mí sílẹ̀ nínú Isà Òkú” (10)

  • 17

    • Àdúrà ààbò

      • “O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn mi” (3)

      • “Òjìji ìyẹ́ apá rẹ” (8)

  • 18

    • Yin Ọlọ́run nítorí ìgbàlà

      • “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi” (2)

      • Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin (25)

      • Pípé ni ọ̀nà Ọlọ́run (30)

      • ‘Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sọ mí di ẹni ńlá’ (35)

  • 19

    • Òfin Ọlọ́run àti àwọn ohun tó dá ń jẹ́rìí

      • “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run” (1)

      • Òfin pípé Ọlọ́run ń sọ agbára dọ̀tun (7

      • “Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mi ò mọ̀ nípa rẹ̀” (12)

  • 20

    • Ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn rí ìgbàlà

      • Àwọn kan gbẹ́kẹ̀ lé kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin, “àmọ́ àwa ń ké pe orúkọ Jèhófà” (7))

  • 21

    • Ìbùkún wà lórí ọba tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

      • Ó fún ọba ní ẹ̀mí gígùn (4)

      • Ọlọ́run á ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ (8-12)

  • 22

    • Ẹni tí kò nírètí wá dẹni tó ń ṣọpẹ́

      • “Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” (1)

      • ‘Wọ́n ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi’ (18)

      • Yin Ọlọ́run láàárín ìjọ (22, 25)

      • Gbogbo ayé yóò máa jọ́sìn Ọlọ́run (27)

  • 23

    • “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi”

      • “Èmi kì yóò ṣaláìní” (1)

      • “Ó tù mí lára” (3)

      • “Ife mi kún dáadáa” (5)

  • 24

    • Ọba ológo wọ ẹnubodè

      • “Jèhófà ló ni ayé” (1)

  • 25

    • Àdúrà ìtọ́sọ́nà àti ìdáríjì

      • “Kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ” (4)

      • ‘Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà tímọ́tímọ́’ (14)

      • “Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí” (18)

  • 26

    • Rírìn nínú ìwà títọ́

      • “Yẹ̀ mí wò, Jèhófà” (2)

      • Yẹra fún ẹgbẹ́ búburú (4, 5)

      • ‘Màá rìn yí ká pẹpẹ Ọlọ́run’ (6)

  • 27

    • Jèhófà ni odi ààbò ayé mi

      • Mọyì tẹ́ńpìlì Ọlọ́run (4)

      • Jèhófà ń tọ́jú ẹni kódà tí àwọn òbí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀ (10)

      • “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà” (14)

  • 28

    • Ọlọ́run gbọ́ àdúrà onísáàmù

      • “Jèhófà ni agbára mi àti apata mi” (7)

  • 29

    • Ohùn Jèhófà lágbára

      • Jọ́sìn nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́ (2)

      • “Ọlọ́run ológo sán ààrá” (3)

      • Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára (11)

  • 30

    • Ọ̀fọ̀ yí pa dà di ìdùnnú

      • Ojú rere Ọlọ́run wà títí ọjọ́ ayé (5)

  • 31

    • Fi Jèhófà ṣe ibi ààbò

      • “Ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé” (5)

      • “Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́” (5)

      • Oore Ọlọ́run mà pọ̀ o (19)

  • 32

    • Aláyọ̀ ni àwọn tó rí ìdáríjì

      • “Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ” (5)

      • Ọlọ́run ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye (8)

  • 33

    • Ìyìn ni fún Ẹlẹ́dàá

      • “Ẹ kọ orin tuntun sí i” (3)

      • Jèhófà fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ dá àwọn nǹkan (6)

      • Orílẹ̀-èdè Jèhófà ń láyọ̀ (12)

      • Ojú Jèhófà tó ń ṣọ́ni (18)

  • 34

    • Jèhófà ń gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀

      • “Ẹ jẹ́ ká jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga” (3)

      • Áńgẹ́lì Jèhófà ń dáàbò boni (7)

      • “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà” (8)

      • ‘Kò sí ìkankan nínú egungun rẹ̀ tí ó ṣẹ́’ (20)

  • 35

    • Àdúrà ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá

      • Kí a lé àwọn ọ̀tá dà nù (5)

      • Máa yin Ọlọ́run láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn (18)

      • Wọ́n kórìíra mi láìnídìí (19)

  • 36

    • Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣeyebíye

      • Ẹni burúkú kì í bẹ̀rù Ọlọ́run (1)

      • Ọlọ́run ni orísun ìyè (9)

      • “Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀” (9)

  • 37

    • Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò láásìkí

      • Má ṣe banú jẹ́ nítorí ẹni ibi (1)

      • “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ nínú Jèhófà” (4)

      • “Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́” (5)

      • “Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé” (11)

      • Àwọn olódodo kò ní ṣaláìní oúnjẹ (25)

      • Àwọn olódodo yóò gbé láyé títí láé (29)

  • 38

    • Àdúrà ẹni tí ìyà ń jẹ tó ronú pìwà dà

      • “Ìdààmú àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó lé kenkà” (6)

      • Jèhófà ń dá àwọn tó ń dúró dè é lóhùn (15)

      • “Ẹ̀ṣẹ̀ mi dààmú mi” (18)

  • 39

    • Ẹ̀mí èèyàn kúrú

      • Èémí lásán ni èèyàn (5, 11)

      • “Má ṣe gbójú fo omijé mi” (12)

  • 40

    • Dídúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí kò láfiwé

      • Iṣẹ́ Ọlọ́run pọ̀ kọjá ohun tó ṣeé ròyìn (5)

      • Àwọn ẹbọ kọ́ ni ohun tí Ọlọ́run dìídì ń fẹ́ (6)

      • ‘Láti ṣe ìfẹ́ rẹ ni inú mi dùn sí’ (8)

  • 41

    • Àdúrà lórí ibùsùn àìsàn

      • Ọlọ́run ń fún aláìsàn lókun (3)

      • Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ dalẹ̀ mi (9)

  • 42

    • Yíyin Ọlọ́run tó jẹ́ Olùgbàlà Atóbilọ́lá

      • Mò ń wá Ọlọ́run bí àgbọ̀nrín ṣe ń wá omi (1, 2)

      • “Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí mi?” (5, 11)

      • “Dúró de Ọlọ́run” (5, 11)

  • 43

    • Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ tó ń gbani là

      • ‘Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ jáde’ (3)

      • “Kí nìdí tí ìrẹ̀wẹ̀sì fi bá ẹ̀mí mi?” (5)

      • “Dúró de Ọlọ́run” (5)

  • 44

    • Àdúrà ìrànlọ́wọ́

      • “Ìwọ lo gbà wá” (7)

      • Bí “àgùntàn tó wà fún pípa” (22)

      • “Dìde nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ wa!” (26)

  • 45

    • Ìgbéyàwó ọba tí Ọlọ́run fòróró yàn

      • Ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu (2)

      • “Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ títí láé” (6)

      • Ọkàn ọba ń fà sí ẹwà ìyàwó rẹ̀ (11)

      • Àwọn ọmọkùnrin yóò jẹ́ olórí ní gbogbo ayé (16)

  • 46

    • “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa”

      • Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run (8)

      • Ọlọ́run fòpin sí ogun ní gbogbo ayé (9)

  • 47

    • Ọlọ́run ni Ọba lórí gbogbo ayé

      • ‘Jèhófà yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù’ (2)

      • Ẹ kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run (6, 7)

  • 48

    • Síónì, ìlú Ọba Títóbi Lọ́lá

      • Ayọ̀ gbogbo ayé (2)

      • Ẹ ṣàyẹ̀wò ìlú náà àti àwọn ilé gogoro rẹ̀ (11-13)

  • 49

    • Gbígbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ jẹ́ ìwà òmùgọ̀

      • Kò sí èèyàn tó lè ra ọmọnìkejì rẹ̀ pa dà (7, 8)

      • Ọlọ́run ń rani pa dà lọ́wọ́ Isà Òkú (15)

      • Ọrọ̀ kò lè gbani lọ́wọ́ ikú (16, 17)

  • 50

    • Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ láàárín olóòótọ́ àti ẹni burúkú

      • Májẹ̀mú Ọlọ́run lórí ẹbọ (5)

      • “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ Onídàájọ́” (6)

      • Gbogbo ẹranko jẹ́ ti Ọlọ́run (10, 11)

      • Ọlọ́run tú àwọn ẹni burúkú fó (16-21)

  • 51

    • Àdúrà ẹni tó ronú pìwà dà

      • Ẹlẹ́ṣẹ̀ látinú oyún wá (5)

      • “Wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi” (7)

      • “Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi” (10)

      • Ọkàn tó gbọgbẹ́ wu Ọlọ́run (17)

  • 52

    • Gbẹ́kẹ̀ lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀

      • Ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń fi ìwà burúkú ṣògo (1-5)

      • Àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ (7)

  • 53

    • Irú ẹni tí òmùgọ̀ jẹ́

      • “Kò sí Jèhófà” (1)

      • “Kò sí ẹni tó ń ṣe rere” (3)

  • 54

    • Àdúrà ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ọ̀tá yí mi ká

      • “Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi” (4)

  • 55

    • Àdúrà ẹni tí ọ̀rẹ́ dà

      • Ẹni tí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀gàn (12-14)

      • “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà” (22)

  • 56

    • Àdúrà ẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí

      • ‘Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé’ (4)

      • ‘Omijé mi nínú ìgò awọ rẹ’ (8)

      • “Kí ni èèyàn lásánlàsàn lè fi mí ṣe?” (4, 11)

  • 57

    • Ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere

      • Ààbò lábẹ́ ìyẹ́ apá Ọlọ́run (1)

      • Àwọn ọ̀tá kó sínú pańpẹ́ tí àwọn fúnra wọn dẹ (6)

  • 58

    • Ọlọ́run kan wà tó ń ṣèdájọ́ ayé

      • Àdúrà pé kí ìyà jẹ àwọn ẹni burúkú (6-8)

  • 59

    • Ọlọ́run jẹ́ apata àti ibi ààbò

      • ‘Má ṣe ṣàánú àwọn ọ̀dàlẹ̀’ (5)

      • “Màá kọrin nípa okun rẹ” (16)

  • 60

    • Ọlọ́run ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá

      • Asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn (11)

      • “Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára” (12)

  • 61

    • Ọlọ́run jẹ́ ilé gogoro alágbára sí àwọn ọ̀tá

      • “Màá wà nínú àgọ́ rẹ” (4)

  • 62

    • Ìgbàlà tòótọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

      • “Mo dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run” (1, 5)

      • ‘Ẹ tú ọkàn yín jáde níwájú Ọlọ́run’ (8)

      • Àwọn èèyàn jẹ́ èémí lásán (9)

      • Má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ (10)

  • 63

    • Ó ń wù mí láti rí Ọlọ́run

      • “Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sàn ju ìyè” (3)

      • ‘Ìpín tó dára jù lọ la fi tẹ́ mi lọ́rùn’ (5)

      • Mò ń ṣe àṣàrò nípa Ọlọ́run ní òru (6)

      • ‘Mo rọ̀ mọ́ Ọlọ́run’ (8)

  • 64

    • Ààbò lọ́wọ́ àtakò tó fara sin

      • “Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà” (7)

  • 65

    • Ọlọ́run ń bójú tó ayé

      • “Olùgbọ́ àdúrà” (2)

      • “Aláyọ̀ ni ẹni tí o yàn” (4)

      • Oore Ọlọ́run pọ̀ rẹpẹtẹ (11)

  • 66

    • Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run

      • “Ẹ wá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run” (5)

      • “Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún ọ” (13)

      • Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà (18-20)

  • 67

    • Gbogbo ayé yóò bẹ̀rù Ọlọ́run

      • Àwọn èèyàn yóò mọ ọ̀nà Ọlọ́run (2)

      • ‘Kí gbogbo èèyàn máa yin Ọlọ́run’ (3, 5)

      • “Ọlọ́run yóò bù kún wa” (6, 7)

  • 68

    • ‘Kí Ọlọ́run tú àwọn ọ̀tá rẹ̀ ká’

      • “Bàbá àwọn ọmọ aláìníbaba” (5)

      • Ọlọ́run ń fi ilé fún àwọn tó dá wà (6)

      • Àwọn obìnrin tó ń kéde ìhìn rere (11)

      • Àwọn ẹ̀bùn tó jẹ́ èèyàn (18)

      • ‘Jèhófà ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́’ (19)

  • 69

    • Àdúrà ìgbàlà

      • “Ìtara ilé rẹ ti gbà mí lọ́kàn” (9)

      • “Tètè dá mi lóhùn” (17)

      • ‘Ọtí kíkan ni wọ́n fún mi mu’ (21)

  • 70

    • Ó bẹ Ọlọ́run pé kó tètè wá ran òun lọ́wọ́

      • “Tètè wá ràn mí lọ́wọ́” (5)

  • 71

    • Ìgbọ́kànlé àwọn arúgbó

      • Ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run láti ìgbà èwe wá (5)

      • “Nígbà tí mi ò bá lágbára mọ́” (9)

      • ‘Ọlọ́run ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá’ (17)

  • 72

    • Àkóso Ọba tí Ọlọ́run yàn máa mú àlááfíà wá

      • “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀” (7)

      • Àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun (8)

      • Yóò gbani lọ́wọ́ ìwà ipá (14)

      • Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ lórí ilẹ̀ (16)

      • A ó máa yin orúkọ Ọlọ́run títí láé (19)

  • 73

    • Ọkùnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run pa dà ní èrò tó bá ti Ọlọ́run mu

      • “Ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lójú ọ̀nà” (2)

      • “Ìdààmú bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀” (14)

      • ‘Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run’ (17)

      • Orí ilẹ̀ tọ́ ń yọ̀ ni àwọn ẹni ibi wà (18)

      • Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára (28)

  • 74

    • Àdúrà pé kí Ọlọ́run rántí àwọn èèyàn rẹ̀

      • Onísáàmù sọ àwọn iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run (12-17)

      • “Rántí bí ọ̀tá ṣe pẹ̀gàn rẹ” (18)

  • 75

    • Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ bó ṣe tọ́

      • Àwọn ẹni burúkú yóò mu ohun tó wà nínú ife Jèhófà (8)

  • 76

    • Ọlọ́run ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Síónì

      • Ọlọ́run ń gba àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ là (9)

      • Ọlọ́run máa rẹ àwọn agbéraga ọ̀tá wálẹ̀ (12)

  • 77

    • Àdúrà lásìkò wàhálà

      • Ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run (11, 12)

      • ‘Ìwọ Ọlọ́run, ta ló tóbi bí rẹ?’ (13)

  • 78

    • Àbójútó Ọlọ́run àti àìnígbàgbọ́ Ísírẹ́lì

      • Ẹ sọ fún ìran tó ń bọ̀ (2-8)

      • “Wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run” (22)

      • “Ọkà ọ̀run” (24)

      • ‘Wọ́n kó ẹ̀dùn ọkàn bá Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì’ (41)

      • Láti Íjíbítì títí dé Ilẹ̀ Ìlérí (43-55)

      • ‘Wọn ò yéé pe Ọlọ́run níjà’ (56)

  • 79

    • Àdúrà ìgbà tí àwọn orílẹ̀-èdè ya bo àwọn èèyàn Ọlọ́run

      • “A ti di ẹni ẹ̀gàn” (4)

      • ‘Ràn wá lọ́wọ́ nítorí orúkọ rẹ’ (9)

      • “San án pa dà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìlọ́po méje” (12)

  • 80

    • Wọ́n wá Olùṣọ́ Àgùntàn Ísírẹ́lì kó lè mú wọn bọ̀ sípò

      • “Ọlọ́run, mú wa bọ̀ sípò” (3)

      • Ísírẹ́lì, àjàrà Ọlọ́run (8-15)

  • 81

    • Ọlọ́run rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣègbọràn

      • Ẹ má ṣe sin àwọn ọlọ́run àjèjì (9)

      • ‘Ká ní ẹ lè fetí sí mi’ (13)

  • 82

    • Ọlọ́run ní kí àwọn èèyàn máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́

      • Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ ní àárín “àwọn ọlọ́run” (1)

      • “Ẹ gbèjà aláìní” (3)

      • “Ọlọ́run ni yín” (6)

  • 83

    • Àdúrà ìgbà tí èèyàn bá ń kojú ọ̀tá

      • “Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́” (1)

      • Àwọn ọ̀tá dà bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo (13)

      • Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run (18)

  • 84

    • Àárò àgọ́ ìjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run ń sọ mí

      • Ó ń wu ọmọ Léfì kan pé kó dà bí ẹyẹ (3)

      • “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ” (10)

      • “Ọlọ́run jẹ́ oòrùn àti apata” (11)

  • 85

    • Àdúrà ìmúbọ̀sípò

      • Ọlọ́run máa sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ (8)

      • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ pàdé (10)

  • 86

    • Kò sí ọlọ́run tó dà bíi Jèhófà

      • Jèhófà ṣe tán láti dárí jini (5)

      • Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò jọ́sìn Jèhófà (9)

      • “Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ” (11)

      • “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀” (11)

  • 87

    • Síónì, ìlú Ọlọ́run tòótọ́

      • Àwọn tí a bí ní Síónì (4-6)

  • 88

    • Àdúrà pé kí Ọlọ́run gbani lọ́wọ́ ikú

      • ‘Ẹ̀mí mi ti dé ẹnu Isà Òkú’ (3)

      • ‘Àràárọ̀ ni mò ń gbàdúrà sí ọ’ (13)

  • 89

    • Onísáàmù kọ orin nípa ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀

      • Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú (3)

      • Àwọn ọmọ Dáfídì máa wà títí láé (4)

      • Ẹni àmì òróró Ọlọ́run pè É ní “Bàbá” (26)

      • Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá dájú (34-37)

      • Èèyàn ò lè bọ́ lọ́wọ́ Isà Òkú (48)

  • 90

    • Ọlọ́run ayérayé àti èèyàn ẹlẹ́mìí kúkúrú

      • Ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí àná (4)

      • Ọjọ́ ayé èèyàn jẹ́ 70 sí 80 ọdún (10)

      • “Kọ́ wa bí a ó ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa” (12)

  • 91

    • Ààbò ní ibi ìkọ̀kọ̀ Ọlọ́run

      • Ó gbà á lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ (3)

      • Ààbò lábẹ́ ìyẹ́ apá Ọlọ́run (4)

      • Bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún tilẹ̀ ṣubú, nǹkan kan ò ní ṣe ọ́ (7)

      • Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì láti máa ṣọ́ ọ (11)

  • 92

    • Jèhófà, ẹni gíga ni ọ́ títí láé

      • Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tóbi, èrò rẹ̀ sì jinlẹ̀ (5)

      • “Olódodo máa gbilẹ̀ bí igi” (12)

      • Àwọn arúgbó á máa lókun (14)

  • 93

    • Ìṣàkóso Jèhófà tóbi

      • “Jèhófà ti di Ọba!” (1)

      • “Àwọn ìránnilétí rẹ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” (5)

  • 94

    • Àdúrà pé kí Ọlọ́run gbẹ̀san

      • ‘Ìgbà wo ni àwọn ẹni burúkú máa wà dà?’ (3)

      • Ìtọ́sọ́nà Jáà ń fúnni láyọ̀ (12)

      • Ọlọ́run ò ní pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì (14)

      • ‘Fífi òfin bojú láti dáná ìjàngbọ̀n’ (20)

  • 95

    • Ìjọsìn tòótọ́ pẹ̀lú ìgbọràn

      • “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀” (7)

      • “Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le” (8)

      • “Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi” (11)

  • 96

    • “Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà”

      • Jèhófà ni ìyìn yẹ jù lọ (4)

      • Ọlọ́run àwọn èèyàn jẹ́ ọlọ́run asán (5)

      • Jọ́sìn Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́ (9)

  • 97

    • Jèhófà ga fíìfíì ju gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù

      • “Jèhófà ti di Ọba!” (1)

      • Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí o sì kórìíra ohun búburú (10)

      • Ìmọ́lẹ̀ tàn fún olódodo (11)

  • 98

    • Jèhófà jẹ́ Olùgbàlà àti Onídàájọ́ òdodo

      • Jèhófà jẹ́ kí a mọ ìgbàlà rẹ̀ (2, 3)

  • 99

    • Jèhófà, Ọba mímọ́

      • Ó gúnwà lórí àwọn kérúbù (1)

      • Ọlọ́run tó ń dárí jini tó sì ń fìyà jẹni (8)

  • 100

    • Ẹ fi ọpẹ́ fún Ẹlẹ́dàá

      • “Ẹ fi ayọ̀ sin Jèhófà” (2)

      • ‘Ọlọ́run ló dá wa’ (3)

  • 101

    • Alákòóso tó ń hu ìwà títọ́

      • ‘Mi ò ní gba ìgbéraga láyè’ (5)

      • “Màá bojú wo àwọn olóòótọ́” (6)

  • 102

    • Àdúrà ẹni tí a ni lára nígbà tí nǹkan tojú sú u

      • “Mo dà bí ẹyẹ tó dá wà lórí òrùlé” (7)

      • ‘Àwọn ọjọ́ mi jẹ́ òjìji tó ń pa rẹ́ lọ’ (11)

      • “Jèhófà máa tún Síónì kọ́” (16)

      • Jèhófà wà títí láé (26, 27)

  • 103

    • “Jẹ́ kí n yin Jèhófà”

      • Ọlọ́run ń mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa (12)

      • Àánú Ọlọ́run dà bíi ti bàbá sí ọmọ (13)

      • Ọlọ́run máa ń rántí pé erùpẹ̀ ni wá (14)

      • Ìtẹ́ Jèhófà àti ìjọba rẹ̀ (19)

      • Àwọn áńgẹ́lì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ (20)

  • 104

    • Yin Ọlọ́run torí àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú ìṣẹ̀dá

      • Ayé máa wà títí láé (5)

      • Oúnjẹ àti wáìnì wà fún ẹni kíkú (15)

      • “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o!” (24)

      • ‘Tí a bá mú ẹ̀mí kúrò, wọ́n á kú’ (29)

  • 105

    • Àwọn iṣẹ́ òdodo Jèhófà lórí àwọn èèyàn rẹ̀

      • Ọlọ́run rántí májẹ̀mú rẹ̀ (8-10)

      • “Ẹ má fọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi” (15)

      • Ọlọ́run lo Jósẹ́fù tí wọ́n mú lẹ́rú (17-22)

      • Àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run ní Íjíbítì (23-36)

      • Bí Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì (37-39)

      • Ọlọ́run rántí ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù (42)

  • 106

    • Ísírẹ́lì kò moore

      • Kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run (13)

      • Wọ́n gbé ògo tó yẹ Ọlọ́run fún ère akọ màlúù (19, 20)

      • Wọn ò nígbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run (24)

      • Wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń sin Báálì (28)

      • Wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù (37)

  • 107

    • Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀

      • Ó darí wọn gba ọ̀nà tí ó tọ́ (7)

      • Ó tẹ́ ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ àti ẹni tí ebi ń pa lọ́rùn (9)

      • Ó mú wọn jáde látinú òkùnkùn (14)

      • Ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ láti mú wọn lára dá (20)

      • Ó ń dáàbò bo aláìní lọ́wọ́ ìnilára (41)

  • 108

    • Àdúrà ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá

      • Asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn (12)

      • “Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára” (13)

  • 109

    • Àdúrà ẹni tí ìdààmú bá

      • ‘Kí ẹlòmíì gba ipò rẹ̀’ (8)

      • Ọlọ́run dúró ti aláìní (31)

  • 110

    • Ọba àti àlùfáà bíi ti Melikisédékì

      • ‘Máa jọba láàárín àwọn ọ̀tá rẹ’ (2)

      • Àwọn ọ̀dọ́ tó yọ̀ǹda ara wọn dà bí ìrì tó ń sẹ̀ (3)

  • 111

    • Ẹ yin Jèhófà nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tóbi

      • Orúkọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ó sì yẹ fún ọ̀wọ̀ (9)

      • Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n (10)

  • 112

    • Olódodo máa ń bẹ̀rù Jèhófà

      • Ẹni tó bá ń yáni ní nǹkan tọkàntọkàn yóò láásìkí (5)

      • “A ó máa rántí àwọn olódodo títí láé” (6)

      • Ọ̀làwọ́ máa ń fún àwọn aláìní (9)

  • 113

    • Ọlọ́run lókè máa ń gbé aláìní dìde

      • Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí láé (2)

      • Ọlọ́run máa ń tẹ̀ ba (6)

  • 114

    • Ísírẹ́lì bọ́ lọ́wọ́ Íjíbítì

      • Òkun sá lọ (5)

      • Àwọn òkè ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún bí àgbò (6)

      • Akọ àpáta di ìsun omi (8)

  • 115

    • Ọlọ́run nìkan ni ògo yẹ

      • Àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí (4-8)

      • Ọlọ́run fi ayé fún àwọn èèyàn (16)

      • “Àwọn òkú kì í yin Jáà” (17)

  • 116

    • Orin ọpẹ́

      • “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà?” (12)

      • “Màá gbé ife ìgbàlà” (13)

      • “Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà” (14, 18)

      • Àdánù ńlá ni ikú àwọn adúróṣinṣin (15)

  • 117

    • Kí gbogbo orílẹ̀-èdè yin Jèhófà

      • Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ọlọ́run ní pọ̀ gan-an (2)

  • 118

    • Ó dúpẹ́ nítorí ìṣẹ́gun Jèhófà

      • ‘Mo ké pe Jáà, ó sì dá mi lóhùn’ (5)

      • “Jèhófà wà lẹ́yìn mi” (6, 7)

      • Òkúta tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ yóò di olórí òkúta igun ilé (22)

      • “Ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà” (26)

  • 119

    • Mọrírì ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye

      • ‘Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú ipa ọ̀nà wọn mọ́?’ (9)

      • “Mo fẹ́ràn àwọn ìránnilétí rẹ” (24)

      • “Ọ̀rọ̀ rẹ ni ìrètí mi” (74, 81, 114)

      • “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (97)

      • “Òye tó jinlẹ̀ ju ti gbogbo àwọn olùkọ́ mi” (99)

      • “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi” (105)

      • “Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ” (160)

      • Àlàáfíà jẹ́ ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run (165)

  • 120

    • Àjèjì tó ń fẹ́ àlàáfíà

      • ‘Gbà mí lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn’ (2)

      • “Àlàáfíà ni èmi ń fẹ́” (7)

  • 121

    • Jèhófà ń ṣọ́ àwọn èèyàn rẹ̀

      • “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá” (2)

      • Jèhófà kì í sùn (3, 4)

  • 122

    • Àdúrà fún àlàáfíà Jerúsálẹ́mù

      • Ayọ̀ tó wà nínú lílọ sí ilé Jèhófà (1)

      • Ìlú tó so pọ̀ mọ́ra (3)

  • 123

    • À ń wo Jèhófà pé kó ṣojú rere sí wa

      • ‘Bíi ti àwọn ìránṣẹ́, à ń wojú Jèhófà’ (2)

      • “Wọ́n ti kàn wá lábùkù dé góńgó” (3)

  • 124

    • “Ká ní Jèhófà ò wà pẹ̀lú wa ni”

      • Bọ́ nínú pańpẹ́ tó ṣẹ́ (7)

      • ‘Orúkọ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ wa’ (8)

  • 125

    • Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀

      • “Bí àwọn òkè ṣe yí Jerúsálẹ́mù ká” (2)

      • “Kí àlàáfíà wà ní Ísírẹ́lì” (5)

  • 126

    • Ayọ̀ sọ nígbà tí Ọlọ́run kó àwọn èèyàn Síónì pa dà

      • “Jèhófà ti ṣe àwọn ohun ńlá” (3)

      • Ẹkún di ayọ̀ (5, 6)

  • 127

    • Láìsí Ọlọ́run, asán ni gbogbo nǹkan

      • “Bí Jèhófà ò bá kọ́ ilé” (1)

      • Àwọn ọmọ jẹ́ èrè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (3)

  • 128

    • Ayọ̀ tó wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà

      • Ìyàwó tó dà bí igi àjàrà tó ń so (3)

      • “Kí aásìkí Jerúsálẹ́mù ṣojú rẹ” (5)

  • 129

    • Wọ́n gbógun tì í, àmọ́ wọn ò ṣẹ́gun

      • Ojú ti àwọn tó kórìíra Síónì (5)

  • 130

    • “Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́”

      • ‘Tó bá jẹ́ àṣìṣe lo fẹ́ máa wò’ (3)

      • Ìdáríjì tòótọ́ wà lọ́dọ̀ Jèhófà (4)

      • “Mò ń retí Jèhófà” (6)

  • 131

    • Mo ní ìtẹ́lọ́rùn bí ọmọ tí a gba ọmú lẹ́nu rẹ̀

      • Mi ò lé nǹkan ńláńlá (1)

  • 132

    • Ó yan Dáfídì àti Síónì

      • “Má ṣe kọ ẹni àmì òróró rẹ sílẹ̀” (10)

      • Ó gbé ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà Síónì (16)

  • 133

    • Wọ́n ń gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan

      • Bí òróró lórí Áárónì (2)

      • Bí ìrì Hámónì (3)

  • 134

    • Wọ́n ń yin Ọlọ́run ní òròòru

      • “Ẹ gbé ọwọ́ yín sókè nínú ìjẹ́mímọ́” (2)

  • 135

    • Ẹ yin Jáà nítorí ó tóbi

      • Iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu lórí Íjíbítì (8, 9)

      • “Orúkọ rẹ wà títí láé” (13)

      • Òrìṣà aláìlẹ́mìí (15-18)

  • 136

    • Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé

      • Ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run àti ayé (5, 6)

      • Fáráò kú sínú Òkun Pupa (15)

      • Ọlọ́run ń rántí àwọn tí ìdààmú bá (23)

      • Ó ń fún gbogbo ohun alààyè ní oúnjẹ (25)

  • 137

    • Létí àwọn odò Bábílónì

      • Wọn ò kọ orin Síónì (3, 4)

      • Bábílónì máa di ahoro (8)

  • 138

    • Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ga, ó ń ṣìkẹ́ èèyàn

      • ‘O dáhùn àdúrà mi’ (3)

      • ‘Bí mo tiẹ̀ wà nínú ewu, o gbà mí sílẹ̀’ (7)

  • 139

    • Ọlọ́run mọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ dáadáa

      • Kò sẹ́ni tó lè sá mọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run lọ́wọ́ (7)

      • “O ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu” (14)

      • ‘O rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn’ (16)

      • “Darí mi sí ọ̀nà ayérayé” (24)

  • 140

    • Jèhófà, Olùgbàlà tó lágbára

      • Àwọn aṣebi dà bí ejò (3)

      • Àwọn oníwà ipá yóò ṣubú (11)

  • 141

    • Àdúrà ààbò

      • “Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí” (2)

      • Ìbáwí olódodo dà bí òróró (5)

      • Àwọn ẹni burúkú já sí àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ (10)

  • 142

    • Àdúrà ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni

      • “Kò síbi tí mo lè sá lọ” (4)

      • ‘Ìwọ ni gbogbo ohun tí mo ní’ (5)

  • 143

    • Mò ń wá Ọlọ́run bí ilẹ̀ gbígbẹ ṣe ń wá òjò

      • ‘Mò ń ronú lórí àwọn iṣẹ́ rẹ’ (5)

      • “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ” (10)

      • ‘Kí ẹ̀mí dáradára rẹ máa darí mi’ (10)

  • 144

    • Àdúrà ìṣẹ́gun

      • ‘Kí ni ẹni kíkú jẹ́?’ (3)

      • ‘Kí a tú àwọn ọ̀tá ká’ (6)

      • Aláyọ̀ ni àwọn èèyàn Jèhófà (15)

  • 145

    • Ẹ yin Ọlọ́run, Ọba ńlá

      • ‘Màá kéde títóbi Ọlọ́run’ (6)

      • “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá” (9)

      • ‘Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò máa yìn ọ́’ (10)

      • Ìjọba Ọlọ́run tó máa wà títí láé (13)

      • Ọwọ́ Ọlọ́run ń tẹ́ gbogbo ẹ̀dá lọ́rùn (16)

  • 146

    • Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn

      • Nígbà tí èèyàn bá kú, èrò inú rẹ̀ á ṣègbé (4)

      • Ọlọ́run ń gbé àwọn tó sorí kodò dìde (8)

  • 147

    • Ẹ máa yin àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run tó fi ìfẹ́ àti agbára rẹ̀ hàn

      • Ó ń wo àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn sàn (3)

      • Ó ń fi orúkọ pe gbogbo àwọn ìràwọ̀ (4)

      • Ó ń fi yìnyín ránṣẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú (16)

  • 148

    • Kí gbogbo ẹ̀dá máa yin Jèhófà

      • “Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀” (2)

      • ‘Ẹ yìn ín, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀’ (3)

      • Kí àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn arúgbó máa yin Ọlọ́run (12, 13)

  • 149

    • Orin ìyìn tó dá lórí ìṣẹ́gun Ọlọ́run

      • Inú Ọlọ́run ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀ (4)

      • Ọlá jẹ́ ti àwọn ẹni ìdúróṣinṣin Ọlọ́run (9)

  • 150

    • Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà

      • Halelúyà! (1, 6)