Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó O Máa Ń Jẹ́ Kí Ọlọ́run Bá Ẹ Sọ̀rọ̀ Lójoojúmọ́?

Ṣó O Máa Ń Jẹ́ Kí Ọlọ́run Bá Ẹ Sọ̀rọ̀ Lójoojúmọ́?

Ṣó O Máa Ń Jẹ́ Kí Ọlọ́run Bá Ẹ Sọ̀rọ̀ Lójoojúmọ́?

ÌGBÀ mélòó lo máa ń wo ara rẹ nínú dígí lóòjọ́? Ó ti mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lára láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, nígbà míì pàápàá ó ṣeé ṣe kó tó ìgbà bíi mélòó kan lóòjọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé a fọwọ́ pàtàkì mú ìrísí wa.

A lè fi Bíbélì kíkà wé wíwo dígí. (Jákọ́bù 1:23-25) Ìsọfúnni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Ó ń “gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà.” (Hébérù 4:12) Ìyẹn ni pé, ó ń jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín irú ẹni tá a rò pé a jẹ́ àti irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Bíi dígí, ó máa ń jẹ́ ká mọ ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe.

Yàtọ̀ sí pé Bíbélì máa ń jẹ́ ká mọ ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe, ó tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣàwọn àtúnṣe náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Kíyè sí pé mẹ́ta nínú àwọn nǹkan mẹ́rin tí ẹsẹ yìí sọ pé Bíbélì ṣàǹfààní fún ló kan àtúnṣe nínú ìwà àti ìṣe wa, ìyẹn kíkọ́ni, fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà àti mímú àwọn nǹkan tọ́. Tá a bá ní láti máa wo dígí lójoojúmọ́ ká bàa lè rí i pé ìrísí wa bójú mu, ẹ ò rí i pé ó túbọ̀ ṣe pàtàkì nígbà náà pé ká máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé!

Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run yan Jóṣúà láti jẹ́ aṣáájú fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” (Jóṣúà 1:8) Ó dájú pé kí Jóṣúà tó lè ṣàṣeyọrí, ó ní láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé “ní ọ̀sán àti ní òru.”

Bákan náà, Sáàmù kìíní jẹ́ ká mọ àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì déédéé nígbà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì. Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:1-3) Ó dájú pé a máa fẹ́ dà bí ọkùnrin yẹn.

Ó ti mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lára láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Nígbà tí wọ́n bi ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristẹni pé kí nìdí tó fi máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó ní: “Mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run lójoojúmọ́, mo sì máa ń retí pé kó dáhùn àdúrà mi, kí nìdí témi náà ò fi ní tẹ́tí sí i nípa kíka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́? Téèyàn bá fẹ́ kọ́rọ̀ òun àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ wọ̀, kò ní jẹ́ òun nìkan lá máa sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀.” Òdodo ọ̀rọ̀ ni ọkùnrin yẹn sọ. Ńṣe ni kíka Bíbélì dà bí ìgbà téèyàn ń fetí sí Ọlọ́run torí ìyẹn ló ń jẹ́ ká mọ èrò rẹ̀ lórí àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe.

Bó O Ṣe Lè Máa Ka Bíbélì Déédéé

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé. Ṣó o ti ka Bíbélì láti páálí dé páálí? Ohun tó dáa jù lọ nìyẹn tó o bá fẹ́ túbọ̀ mọ àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Àwọn kan ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti ka Bíbélì láti páálí dé páálí, àmọ́ ńṣe ni wọ́n máa ń dá a dúró tó bá yá. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Kí lo lè ṣe tí wàá fi lè ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin? O ò ṣe gbìyànjú àbá méjì tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Fi Bíbélì kíkà kún àwọn nǹkan tó ò ń ṣe lójoojúmọ́. Yan àkókò tó rọrùn fún ẹ lójoojúmọ́ tí wàá lè máa fi ka Bíbélì. Tún ṣètò àkókò míì tó o lè fi dípò. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé fún ìdí kan o ò lè ka Bíbélì lákòókò tó o ti ṣètò tẹ́lẹ̀, ṣètò àkókò míì tí wàá fi kà á, kí ọjọ́ kan má bàa lọ láìjẹ́ pé o ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wàá lè máa tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Bèróà ayé ọjọ́un. Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”−Ìṣe 17:11.

Ní àfojúsùn kan pàtó. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ka orí Bíbélì mẹ́ta sí márùn-ún lójoojúmọ́, o lè ka odindi Bíbélì tán láàárín ọdún kan. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tó wà láwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè ṣe é. O ò ṣe pinnu láti gbìyànjú ẹ̀ wò. Lábẹ́ àwọn ibi tá a kọ “Déètì,” sí, kọ déètì àwọn ọjọ́ tó o ṣètò láti fi ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orí Bíbélì tá a kọ pa pọ̀. Máa fàmì sí i tó o bá ti ń kà á tán. Èyí á jẹ́ kó o mọ ibi tó o dé.

Tó o bá sì ti ka odindi Bíbélì tán, ìyẹn ò ní kó o má kà á mọ́. O tún lè lo ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí láti máa fi ka Bíbélì láti páálí dé páálí lọ́dọọdún, bóyá kó o máa bẹ̀rẹ̀ láti ibi tó yàtọ̀ síra. Tó bá sì jẹ́ pé pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lo fẹ́ fi ka odindi Bíbélì tán, o lè fọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta ka àwọn orí Bíbélì tá a kọ pa pọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Gbogbo ìgbà tó o bá ń ka Bíbélì lo máa rí àwọn nǹkan tuntun tó kan ìgbésí ayé rẹ, ìyẹn àwọn nǹkan tó ò fún láfiyèsí tẹ́lẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà,” ìgbésí ayé wa àti ipò wa sì ń yí pa dà lójoojúmọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:31) Fi ṣe ìpinnu rẹ nígbà náà láti máa wonú dígí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì lójoojúmọ́. Ìyẹn á fi dá ẹ lójú pé ò ń jẹ́ kí Ọlọ́run máa bá ẹ sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́.—Sáàmù 16:8.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

1

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà

BÓ O ṢE MÁA ṢE É. Kọ déètì àwọn ọjọ́ tó o ṣètò láti fi ka àwọn orí Bíbélì tá a kọ pa pọ̀. Máa fàmì sí i bó o bá ti ń kà á tán. O lè ka àwọn ìwé Bíbélì náà bá a ṣe tò ó sínú àpótí yìí tàbí kó o yan àwọn àkòrí tó o bá fẹ́ kà nínú àwọn àkòrí tá a kọ sínú àpótí yìí. Tó o bá ń ka àwọn orí Bíbélì tó wà fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́, wàá ka odindi Bíbélì tán lọ́dún kan.

◆ Ka àwọn orí Bíbélì tó wà láwọn ibi tá a fi àmì PUPA sí láti mọ̀ nípa àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

● Ka àwọn orí Bíbélì tó wà láwọn ibi tá a fi àmì BÚLÚÙ sí láti fi mọ bí ìsìn Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀ lé.

2

ÀWỌN ÌWÉ TÍ MÓSÈ KỌ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ JẸ́NẸ́SÍSÌ 1-3

/ 4-7

/ 8-11

/ ◆ 12-15

/ ◆ 16-18

/ ◆ 19-22

/ ◆ 23-24

/ ◆ 25-27

/ ◆ 28-30

/ ◆ 31-32

/ ◆ 33-34

/ ◆ 35-37

/ ◆ 38-40

/ ◆ 41-42

/ ◆ 43-45

/ ◆ 46-48

/ ◆ 49-50

/ Ẹ́KÍSÓDÙ ◆ 1-4

/ ◆ 5-7

/ ◆ 8-10

/ ◆ 11-13

/ ◆ 14-15

/ ◆ 16-18

/ ◆ 19-21

/ 22-25

/ 26-28

/ 29-30

/ ◆ 31-33

/ ◆ 34-35

/ 36-38

/ 39-40

/ LÉFÍTÍKÙ 1-4

/ 5-7

/ 8-10

/ 11-13

/ 14-15

/ 16-18

/ 19-21

/ 22-23

/ 24-25

/ 26-27

/ NÚMÉRÌ 1-3

/ 4-6

/ 7-9

/ ◆ 10-12

/ ◆ 13-15

/ ◆ 16-18

/ ◆ 19-21

/ ◆ 22-24

/ ◆ 25-27

/ 28-30

/ ◆ 31-32

/ ◆ 33-36

/ DIUTARÓNÓMÌ 1-2

/ ◆ 3-4

/ 5-7

/ 8-10

/ 11-13

3

/ 14-16

/ ◆ 17-19

/ 20-22

/ 23-26

/ 27-28

/ ◆ 29-31

/ ◆ 32

/ ◆ 33-34

BÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ ṢE WỌ ILẸ̀ ÌLÉRÍ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ JÓṢÚÀ ◆ 1-4

/ ◆ 5-7

/ ◆ 8-9

/ ◆ 10-12

/ ◆ 13-15

/ ◆ 16-18

/ ◆ 19-21

/ ◆ 22-24

/ ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ ◆ 1-2

/ ◆ 3-5

/ ◆ 6-7

/ ◆ 8-9

/ ◆ 10-11

/ ◆ 12-13

/ ◆ 14-16

/ ◆ 17-19

/ ◆ 20-21

/ RÚÙTÙ ◆ 1-4

ÌGBÀ TÁWỌN ỌBA Ń ṢÀKÓSO NÍ ÍSÍRẸ́LÌ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ 1 SÁMÚẸ́LÌ ◆ 1-2

/ ◆ 3-6

/ ◆ 7-9

/ ◆ 10-12

/ ◆ 13-14

/ ◆ 15-16

/ ◆ 17-18

/ ◆ 19-21

/ ◆ 22-24

/ ◆ 25-27

/ ◆ 28-31

/ 2 SÁMÚẸ́LÌ ◆ 1-2

/ ◆ 3-5

/ ◆ 6-8

/ ◆ 9-12

/ ◆ 13-14

/ ◆ 15-16

/ ◆ 17-18

/ ◆ 19-20

/ ◆ 21-22

/ ◆ 23-24

/ 1 ÀWỌN ỌBA ◆ 1-2

/ ◆ 3-5

/ ◆ 6-7

/ ◆ 8

/ ◆ 9-10

/ ◆ 11-12

4

/ 1 ÀWỌN ỌBA (À ń bá a nìṣó) ◆ 13-14

/ ◆ 15-17

/ ◆ 18-19

/ ◆ 20-21

/ ◆ 22

/ 2 ÀWỌN ỌBA ◆ 1-3

/ ◆ 4-5

/ ◆ 6-8

/ ◆ 9-10

/ ◆ 11-13

/ ◆ 14-15

/ ◆ 16-17

/ ◆ 18-19

/ ◆ 20-22

/ ◆ 23-25

/ 1 KÍRÓNÍKÀ 1-2

/ 3-5

/ 6-7

/ 8-10

/ 11-12

/ 13-15

/ 16-17

/ 18-20

/ 21-23

/ 24-26

/ 27-29

/ 2 KÍRÓNÍKÀ 1-3

/ 4-6

/ 7-9

/ 10-14

/ 15-18

/ 19-22

/ 23-25

/ 26-28

/ 29-30

/ 31-33

/ 34-36

BÁWỌN JÚÙ ṢE PA DÀ DÉ LÁTI OKO ẸRÚ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ Ẹ́SÍRÀ ◆ 1-3

/ ◆ 4-7

/ ◆ 8-10

/ NEHEMÁYÀ ◆ 1-3

/ ◆ 4-6

/ ◆ 7-8

/ ◆ 9-10

/ ◆ 11-13

/ Ẹ́SÍTÉRÌ ◆ 1-4

/ ◆ 5-10

ÀWỌN ÌWÉ TÍ MÓSÈ KỌ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ JÓÒBÙ 1-5

/ 6-9

/ 10-14

/ 15-18

/ 19-20

5

/ 21-24

/ 25-29

/ 30-31

/ 32-34

/ 35-38

/ 39-42

ÀWỌN ÌWÉ ORIN ÀTÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ỌGBỌ́N

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ SÁÀMÙ 1-8

/ 9-16

/ 17-19

/ 20-25

/ 26-31

/ 32-35

/ 36-38

/ 39-42

/ 43-47

/ 48-52

/ 53-58

/ 59-64

/ 65-68

/ 69-72

/ 73-77

/ 78-79

/ 80-86

/ 87-90

/ 91-96

/ 97-103

/ 104-105

/ 106-108

/ 109-115

/ 116-119:63

/ 119:64-176

/ 120-129

/ 130-138

/ 139-144

/ 145-150

/ ÒWE 1-4

/ 5-8

/ 9-12

/ 13-16

/ 17-19

/ 20-22

/ 23-27

/ 28-31

/ ONÍWÀÁSÙ 1-4

/ 5-8

/ 9-12

/ ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 1-8

ÀWỌN WÒLÍÌ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ AÍSÁYÀ 1-4

/ 5-7

/ 8-10

6

/ AÍSÁYÀ (À ń bá a nìṣó) 11-14

/ 15-19

/ 20-24

/ 25-28

/ 29-31

/ 32-35

/ 36-37

/ 38-40

/ 41-43

/ 44-47

/ 48-50

/ 51-55

/ 56-58

/ 59-62

/ 63-66

/ JEREMÁYÀ 1-3

/ 4-5

/ 6-7

/ 8-10

/ 11-13

/ 14-16

/ 17-20

/ 21-23

/ 24-26

/ 27-29

/ 30-31

/ 32-33

/ 34-36

/ 37-39

/ 40-42

/ 43-44

/ 45-48

/ 49-50

/ 51-52

/ ÌDÁRÒ 1-2

/ 3-5

/ ÌSÍKÍẸ́LÌ 1-3

/ 4-6

/ 7-9

/ 10-12

/ 13-15

/ 16

/ 17-18

/ 19-21

/ 22-23

/ 24-26

/ 27-28

/ 29-31

/ 32-33

/ 34-36

/ 37-38

/ 39-40

/ 41-43

/ 44-45

/ 46-48

/ DÁNÍẸ́LÌ 1-2

/ 3-4

/ 5-7

/ 8-10

/ 11-12

7

/ HÓSÉÀ 1-7

/ 8-14

/ JÓẸ́LÌ 1-3

/ ÁMÓSÌ 1-5

/ 6-9

/ ỌBADÁYÀ ÀTI ​JÓNÀ

/ MÍKÀ 1-7

/ NÁHÚMÙ ÀTI ​HÁBÁKÚKÙ

/ SEFANÁYÀ ÀTI ​HÁGÁÌ

/ SEKARÁYÀ 1-7

/ 8-11

/ 12-14

/ MÁLÁKÌ 1-4

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ JÉSÙ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ RẸ̀

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ MÁTÍÙ 1-4

/ 5-7

/ 8-10

/ 11-13

/ 14-17

/ 18-20

/ 21-23

/ 24-25

/ 26

/ 27-28

/ MÁÀKÙ ● 1-3

/ ● 4-5

/ ● 6-8

/ ● 9-10

/ ● 11-13

/ ● 14-16

/ LÚÙKÙ 1-2

/ 3-5

/ 6-7

/ 8-9

/ 10-11

/ 12-13

/ 14-17

/ 18-19

/ 20-22

/ 23-24

/ JÒHÁNÙ 1-3

/ 4-5

/ 6-7

/ 8-9

/ 10-12

/ 13-15

/ 16-18

/ 19-21

BÍ ÌJỌ KRISTẸNI ṢE GBÈRÚ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ ÌṢE ● 1-3

/ ● 4-6

/ ● 7-8

/ ● 9-11

8

/ ÌṢE (À ń bá a nìṣó) ● 12-14

/ ● 15-16

/ ● 917-19

/ ● 20-21

/ ● 22-23

/ ● 24-26

/ ● 27-28

ÀWỌN LẸ́TÀ PỌ́Ọ̀LÙ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ RÓÒMÙ 1-3

/ 4-7

/ 8-11

/ 12-16

/ 1 KỌ́RÍŃTÌ 1-6

/ 7-10

/ 11-14

/ 15-16

/ 2 KỌ́RÍŃTÌ 1-6

/ 7-10

/ 11-13

/ GÁLÁTÍÀ 1-6

/ ÉFÉSÙ 1-6

/ FÍLÍPÌ 1-4

/ KÓLÓSÈ 1-4

/ 1 TẸSALÓNÍKÀ 1-5

/ 2 TẸSALÓNÍKÀ 1-3

/ 1 TÍMÓTÌ 1-6

/ 2 TÍMÓTÌ 1-4

/ TÍTÙ ÀTI ​FÍLÉMÓNÌ

/ HÉBÉRÙ 1-6

/ 7-10

/ 11-13

ÀWỌN ÌWÉ TÁWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ ÀTÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TÓ KÙ KỌ

DÉÈTÌ ORÍ □✔

/ JÁKỌ́BÙ 1-5

/ 1 PÉTÉRÙ 1-5

/ 2 PÉTÉRÙ 1-3

/ 1 JÒHÁNÙ 1-5

/ 2 JÒHÁNÙ/​3 JÒHÁNÙ ÀTI ​JÚÚDÀ

/ ÌṢÍPAYÁ 1-4

/ 5-9

/ 10-14

/ 15-18

/ 19-22

Kọ́kọ́ gé e lójú ìlà

Lẹ́yìn náà, kó o pa ojú ìwé méjèèjì pọ̀, kó o sì ká a

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ṣó o lè ya àkókò kan sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ tí wàá máa fi ka Bíbélì?