Sí Àwọn Ará Éfésù 1:1-23

  • Ìkíni (1, 2)

  • Àwọn ìbùkún tẹ̀mí (3-7)

  • À ń kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi (8-14)

    • “Iṣẹ́ àbójútó kan” ní àwọn àkókò tí a ti yàn (10)

    • A fi ẹ̀mí gbé èdìdì lé wọn gẹ́gẹ́ bí “àmì ìdánilójú” (13, 14)

  • Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ìgbàgbọ́ àwọn ará Éfésù, ó sì gbàdúrà fún wọn (15-23)

1  Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, sí àwọn ẹni mímọ́ tó wà ní Éfésù,+ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú Kristi Jésù:  Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa.  Ìyìn ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, torí ó ti fi gbogbo ìbùkún tẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run jíǹkí wa nínú Kristi,+  bí ó ṣe yàn wá láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀* ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé, kí a lè jẹ́ mímọ́, kí a sì wà láìní àbààwọ́n+ níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́.  Nítorí ó ti yàn wá ṣáájú+ kí ó lè sọ wá dọmọ+ nípasẹ̀ Jésù Kristi, torí ohun tí ó wù ú tí ó sì fẹ́ nìyẹn,+  kí a lè yìn ín nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ológo+ tó fi jíǹkí wa nípasẹ̀ àyànfẹ́ rẹ̀.+  Ipasẹ̀ ìràpadà tó fi ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ san ni a fi rí ìtúsílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa,+ nítorí ọlá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.  Ó mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí pọ̀ gidigidi fún wa nínú gbogbo ọgbọ́n àti òye*  bó ṣe jẹ́ ká mọ àṣírí mímọ́+ nípa ìfẹ́ rẹ̀. Èyí bá ohun tó ń wù ú mu, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò 10  iṣẹ́ àbójútó kan* láti kó ohun gbogbo jọ nínú Kristi nígbà tí àwọn àkókò tí a yàn bá tó, àwọn ohun tó wà ní ọ̀run àti àwọn ohun tó wà ní ayé.+ Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ẹni 11  tí a wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí a sì yàn wá láti jẹ́ ajogún pẹ̀lú rẹ̀,+ ní ti pé a ti yàn wá ṣáájú nítorí ohun tí ẹni tó ń ṣe ohun gbogbo fẹ́, bí ó ṣe ń pinnu ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, 12  kí iṣẹ́ ìsìn àwa tí a kọ́kọ́ nírètí nínú Kristi lè yìn ín lógo. 13  Àmọ́ ẹ̀yin náà nírètí nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìyẹn ìhìn rere nípa ìgbàlà yín. Lẹ́yìn tí ẹ gbà á gbọ́, a fi ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí gbé èdìdì lé yín+ nípasẹ̀ rẹ̀, 14  ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ àmì ìdánilójú* ogún tí à ń retí,+ kí àwọn èèyàn* Ọlọ́run lè rí ìtúsílẹ̀+ nípasẹ̀ ìràpadà,+ sí ìyìn àti ògo rẹ̀. 15  Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé látìgbà tí èmi náà ti gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú Jésù Olúwa àti nípa ìfẹ́ tí ẹ fi hàn sí gbogbo àwọn ẹni mímọ́, 16  mi ò yéé dúpẹ́ nítorí yín. Mo sì ń dárúkọ yín nínú àdúrà mi, 17  pé kí Ọlọ́run Olúwa wa Jésù Kristi, Baba ògo, fún yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti ìfihàn nínú ìmọ̀ tó péye nípa rẹ̀.+ 18  Ó ti la ojú inú* yín, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó pè yín láti ní, kí ẹ lè mọ ọrọ̀ ológo tó fẹ́ fi ṣe ogún fún àwọn ẹni mímọ́+ 19  àti bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ lórí àwa onígbàgbọ́ lọ́nà tó ta yọ.+ Èyí hàn nínú bí agbára ńlá rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́, 20  nígbà tó lò ó láti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú, tó sì mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀+ ní àwọn ibi ọ̀run, 21  tí ó ga ju gbogbo ìjọba àti àṣẹ àti agbára àti ipò olúwa àti gbogbo orúkọ tí à ń pè,+ kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí* nìkan, àmọ́ nínú èyí tó ń bọ̀ pẹ̀lú. 22  Ó tún fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,+ ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo nínú ìjọ,+ 23  èyí tó jẹ́ ara rẹ̀,+ tó sì jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tó ń fi ohun gbogbo kún inú ohun gbogbo.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, Kristi.
Tàbí “làákàyè.”
Tàbí “láti máa bójú tó àwọn nǹkan.”
Tàbí “àsansílẹ̀; ìdánilójú (ẹ̀jẹ́) ohun tó ń bọ̀.”
Ní Grk., “ohun ìní.”
Ní Grk., “ojú ọkàn.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.