Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 24:1-27

  • Wọ́n fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù (1-9)

  • Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú Fẹ́líìsì (10-21)

  • Wọ́n dá ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù dúró fún ọdún méjì (22-27)

24  Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà, Ananáyà,+ àlùfáà àgbà wá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà kan àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀* tó ń jẹ́ Tẹ́túlọ́sì, wọ́n sì gbé ẹjọ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù wá síwájú gómìnà.+  Nígbà tí wọ́n pè é, Tẹ́túlọ́sì bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ̀sùn kàn án, ó ní: “Bó ṣe jẹ́ pé à ń gbádùn àlàáfíà púpọ̀ nípasẹ̀ rẹ àti pé àròjinlẹ̀ rẹ ń mú kí àwọn àtúnṣe wáyé ní orílẹ̀-èdè yìí,  ìgbà gbogbo àti ibi gbogbo la ti ń rí èyí, Fẹ́líìsì Ọlọ́lá Jù Lọ, a dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá.  Àmọ́ kí n má bàa gbà ọ́ lákòókò jù, mo bẹ̀ ọ́ nítorí inúure rẹ pé kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní ṣókí.  A ti rí i pé alákòóbá* ni ọkùnrin yìí,+ ṣe ló ń dáná ọ̀tẹ̀+ sí ìjọba láàárín gbogbo àwọn Júù káàkiri ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, òun sì ni òléwájú nínú ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárẹ́tì.+  Ó tiẹ̀ tún fẹ́ sọ tẹ́ńpìlì di ẹlẹ́gbin, ìdí nìyẹn tí a fi mú un.+ 7 * ——  Nígbà tí ìwọ fúnra rẹ bá gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹ̀ wò, gbogbo ẹ̀sùn tí a fi ń kàn án yìí máa ṣe kedere sí ọ.”  Ni àwọn Júù náà bá gbè é lẹ́yìn láti ta kò ó, wọ́n ń tẹnu mọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. 10  Nígbà tí gómìnà mi orí sí Pọ́ọ̀lù pé kó sọ̀rọ̀, ó fèsì pé: “Bí mo ṣe mọ̀ dáadáa pé ọ̀pọ̀ ọdún lo ti ń ṣe onídàájọ́ orílẹ̀-èdè yìí, mo ṣe tán láti gbèjà ara mi.+ 11  Ìwọ fúnra rẹ lè wádìí, kò tíì ju ọjọ́ méjìlá (12) tí mo lọ jọ́sìn ní Jerúsálẹ́mù;+ 12  wọn ò sì rí mi pé mò ń bá èèyàn jiyàn nínú tẹ́ńpìlì, àbí pé mo dá àwùjọ onírúgúdù sílẹ̀, yálà nínú àwọn sínágọ́gù tàbí káàkiri ìlú náà. 13  Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè fún ọ ní ẹ̀rí àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí yìí. 14  Àmọ́ mo fẹ́ sọ fún ọ pé, ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ya ìsìn yìí ni mo gbà ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi,+ torí mo gba gbogbo ohun tó wà nínú Òfin gbọ́ àti ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé àwọn Wòlíì.+ 15  Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run, ìrètí tí àwọn ọkùnrin yìí náà ní, pé àjíǹde+ àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo+ yóò wà. 16  Nítorí èyí, ìgbà gbogbo ni mo máa ń fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn mi mọ́* níwájú Ọlọ́run àti èèyàn.+ 17  Tóò, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, mo dé láti mú ọrẹ àánú+ wá fún orílẹ̀-èdè mi, kí n sì mú àwọn ọrẹ wá pẹ̀lú. 18  Bí mo ṣe ń ṣe àwọn nǹkan yìí lọ́wọ́, wọ́n rí i pé mo wà ní mímọ́ lọ́nà Òfin nínú tẹ́ńpìlì,+ àmọ́ kì í ṣe pé mo kó èrò lẹ́yìn, àbí pé mò ń dá wàhálà sílẹ̀. Àwọn Júù kan láti ìpínlẹ̀ Éṣíà wà níbẹ̀, 19  tó yẹ kí wọ́n wà níwájú rẹ níbí, kí wọ́n wá fẹ̀sùn kàn mí tí wọ́n bá ní ohunkóhun lòdì sí mi.+ 20  Tàbí kẹ̀, kí àwọn ọkùnrin tó wà níbí yìí fúnra wọn sọ ohun àìtọ́ tí wọ́n rí nígbà tí mo dúró níwájú Sàhẹ́ndìrìn, 21  àyàfi ohun kan ṣoṣo yìí tí mo ké jáde nígbà tí mo dúró láàárín wọn, pé: ‘Torí àjíǹde àwọn òkú ni wọ́n ṣe ń dá mi lẹ́jọ́ lónìí níwájú yín!’”+ 22  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Fẹ́líìsì mọ̀ nípa Ọ̀nà + yìí dáadáa, ó sún ẹjọ́ àwọn ọkùnrin náà síwájú, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí Lísíà ọ̀gágun bá wá síbí, màá ṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn yín.” 23  Ó wá pàṣẹ fún ọ̀gá àwọn ọmọ ogun pé kí wọ́n fi ọkùnrin náà sí àhámọ́, àmọ́ kí wọ́n fún un ní òmìnira díẹ̀, kí wọ́n sì gba àwọn èèyàn rẹ̀ láyè láti máa bá a ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe. 24  Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, Fẹ́líìsì dé pẹ̀lú Dùrùsílà ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ Júù, ó ránṣẹ́ pe Pọ́ọ̀lù, ó sì ń fetí sí i bó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 25  Àmọ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ̀rọ̀ nípa òdodo àti ìkóra-ẹni-níjàánu pẹ̀lú ìdájọ́ tó ń bọ̀,+ ẹ̀rù ba Fẹ́líìsì, ó sì fèsì pé: “Ṣì máa lọ ná, màá ránṣẹ́ pè ẹ́ nígbà míì tí mo bá ráyè.” 26  Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ń retí pé Pọ́ọ̀lù máa fún òun lówó. Torí ìyẹn, lemọ́lemọ́ ló ń ránṣẹ́ pè é, tó sì ń bá a sọ̀rọ̀. 27  Lẹ́yìn ọdún méjì, Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì rọ́pò Fẹ́líìsì; àmọ́ torí pé Fẹ́líìsì ń wá ojú rere àwọn Júù,+ ó fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀ nínú àhámọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “agbẹjọ́rò kan.”
Tàbí “oníwàhálà.” Ní Grk., “àjàkálẹ̀ àrùn.”
Tàbí “wà láìlábààwọ́n.”