Ìwé Kejì Pétérù 1:1-21

  • Ìkíni (1)

  • Ẹ jẹ́ kí pípè yín dá yín lójú (2-15)

    • Àwọn ànímọ́ tí a fi kún ìgbàgbọ́ (5-9)

  • Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú (16-21)

1  Símónì Pétérù, ẹrú àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, sí ẹ̀yin tí ẹ ti ní irú ìgbàgbọ́ tó ṣeyebíye tí àwa náà ní,* nípasẹ̀ òdodo Ọlọ́run wa àti Jésù Kristi Olùgbàlà:  Kí ìmọ̀ tó péye + nípa Ọlọ́run àti Jésù Olúwa wa mú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà pọ̀ sí i fún yín,  torí agbára rẹ̀ tó wá láti ọ̀run ti jẹ́ ká ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run* látinú ìmọ̀ tó péye nípa Ẹni tó fi ògo àti ìwà mímọ́ rẹ̀ pè wá.+  Àwọn nǹkan yìí ló fi jẹ́ ká ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu gan-an,*+ kí ẹ lè tipasẹ̀ wọn nípìn-ín nínú àwọn ohun ti ọ̀run,+ nígbà tí ẹ ti bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ ayé tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́* máa ń fà.  Nítorí èyí, ẹ sa gbogbo ipá yín+ láti fi ìwà mímọ́ kún ìgbàgbọ́ yín,+ ìmọ̀ kún ìwà mímọ́ yín,+  ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín,+ ìfọkànsin Ọlọ́run+ kún ìfaradà yín,  ìfẹ́ ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ ará yín.+  Torí bí àwọn nǹkan yìí bá wà nínú yín, tí ẹ sì ní wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, wọn ò ní jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso+ ní ti ìmọ̀ tó péye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.  Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní àwọn nǹkan yìí jẹ́ afọ́jú, ó ti di ojú rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀,*+ ó sì ti gbàgbé pé a wẹ òun mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀+ tó ti dá tipẹ́tipẹ́. 10  Torí náà, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe, kí pípè+ àti yíyàn yín lè dá yín lójú, torí tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ ò ní kùnà láé.+ 11  Ní tòótọ́, èyí á mú kí ẹ wọlé fàlàlà* sínú Ìjọba ayérayé+ ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.+ 12  Ìdí nìyí tó fi wù mí kí n máa rán yín létí àwọn nǹkan yìí nígbà gbogbo, bí ẹ tiẹ̀ mọ̀ wọ́n, tí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́ tó wà nínú yín. 13  Àmọ́ mo rí i pé ó dáa, tí mo bá ṣì wà nínú àgọ́* yìí,+ láti máa rán yín létí kí n lè ta yín jí,+ 14  bí mo ṣe mọ̀ pé màá tó bọ́ àgọ́ mi kúrò, bí Olúwa wa Jésù Kristi ṣe jẹ́ kí n mọ̀ kedere.+ 15  Màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nígbà gbogbo, kó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, ẹ̀yin fúnra yín á lè rántí* àwọn nǹkan yìí. 16  Ó dájú pé kì í ṣe àwọn ìtàn èké tí a dọ́gbọ́n hùmọ̀ la tẹ̀ lé nígbà tí a jẹ́ kí ẹ mọ agbára Olúwa wa Jésù Kristi àti ìgbà tó máa wà níhìn-ín, àmọ́ a fi ojú ara wa rí ọlá ńlá rẹ̀.+ 17  Torí ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, nígbà tí ògo ọlá ńlá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún un* pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́ mi, ẹni tí èmi fúnra mi tẹ́wọ́ gbà.”+ 18  Àní, ọ̀rọ̀ yìí la gbọ́ láti ọ̀run nígbà tí a wà pẹ̀lú rẹ̀ ní òkè mímọ́. 19  Torí náà, a ní ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú kó túbọ̀ dá wa lójú, ẹ sì ń ṣe dáadáa bí ẹ ṣe ń fiyè sí i bíi fìtílà+ tó ń tàn níbi tó ṣókùnkùn (títí ilẹ̀ fi máa mọ́, tí ìràwọ̀ ojúmọ́+ sì máa yọ) nínú ọkàn yín. 20  Nítorí ẹ kọ́kọ́ mọ̀ pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó wá látinú èrò* ara ẹni èyíkéyìí. 21  Torí a ò fìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípasẹ̀ ìfẹ́ èèyàn,+ àmọ́ àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìgbàgbọ́ tí àǹfààní rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú tiwa.”
Tàbí “ti fún wa ní gbogbo ohun tó mú ká lè ní ìyè àti ìfọkànsìn Ọlọ́run lọ́fẹ̀ẹ́.”
Tàbí “fi fún wa ní àwọn ìlérí tó ṣeyebíye, tó sì jẹ́ àgbàyanu lọ́fẹ̀ẹ́.”
Tàbí “ìfẹ́ ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “ó ti fọ́jú, kò ríran jìnnà.”
Tàbí “ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àǹfààní láti wọlé.”
Ìyẹn, ara tó ní lórí ilẹ̀ ayé.
Tàbí “sọ̀rọ̀ nípa.”
Ní Grk., “jẹ́ kó gbọ́ irú ohùn yìí.”
Tàbí “ìtúmọ̀.”
Ní Grk., “sún wọn; mú kí wọ́n gba ìmísí.”