Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 11:1-34

  • “Ẹ máa fara wé mi” (1)

  • Ipò orí àti bíbo orí (2-16)

  • Ṣíṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa (17-34)

11  Ẹ máa fara wé mi, bí èmi náà ṣe ń fara wé Kristi.+  Mo gbóríyìn fún yín nítorí nínú ohun gbogbo, ẹ̀ ń rántí mi, ẹ sì di àwọn àṣà tí mo fi lé yín lọ́wọ́ mú ṣinṣin.  Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; + bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin;+ bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.+  Gbogbo ọkùnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, tó sì fi nǹkan borí ń dójú ti orí rẹ̀;  àmọ́ gbogbo obìnrin tó ń gbàdúrà tàbí tó ń sọ tẹ́lẹ̀+ láìborí ń dójú ti orí rẹ̀, nítorí bákan náà ló rí pẹ̀lú obìnrin tó fárí.  Nítorí tí obìnrin kò bá borí, kí ó gé irun rẹ̀; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun ìtìjú fún obìnrin láti gé irun tàbí kí ó fárí, ó yẹ kí ó borí.  Nítorí kò yẹ kí ọkùnrin borí, torí ó jẹ́ àwòrán+ àti ògo Ọlọ́run, àmọ́ obìnrin jẹ́ ògo ọkùnrin.  Torí ọkùnrin kò wá láti ara obìnrin, àmọ́ obìnrin wá láti ara ọkùnrin.+  Àti pé, a kò dá ọkùnrin nítorí obìnrin, àmọ́ a dá obìnrin nítorí ọkùnrin.+ 10  Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí obìnrin ní àmì àṣẹ ní orí rẹ̀, nítorí àwọn áńgẹ́lì.+ 11  Yàtọ̀ síyẹn, nínú Olúwa, kò sí obìnrin láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọkùnrin láìsí obìnrin. 12  Nítorí bí obìnrin ṣe wá láti ara ọkùnrin,+ bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin ṣe wá nípasẹ̀ obìnrin; àmọ́ ohun gbogbo wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 13  Ẹ fúnra yín pinnu: Ṣé ó yẹ kí obìnrin gbàdúrà sí Ọlọ́run láìborí? 14  Ṣé ìwà ẹ̀dá fúnra rẹ̀ kò kọ́ yín pé àbùkù ni irun gígùn jẹ́ fún ọkùnrin, 15  àmọ́ tí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un? Nítorí irun rẹ̀ ni a fún un dípò ìbòrí. 16  Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni ò bá fara mọ́ àṣà yìí, a ò ní àṣà míì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ Ọlọ́run kò ní. 17  Àmọ́ bí mo ṣe ń fún yín ní àwọn ìtọ́ni yìí, mi ò gbóríyìn fún yín, nítorí kì í ṣe kí nǹkan lè dáa sí i lẹ ṣe ń pé jọ, kó lè burú sí i ni. 18  Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá kóra jọ nínú ìjọ, ìpínyà máa ń wà láàárín yín; mo sì gbà á gbọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. 19  Ó dájú pé àwọn ẹ̀ya ìsìn tún máa wà láàárín yín,+ kí àwọn tí a tẹ́wọ́ gbà nínú yín lè fara hàn kedere. 20  Nígbà tí ẹ bá kóra jọ sí ibì kan, kì í wulẹ̀ ṣe láti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.+ 21  Torí nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹ ẹ́, kálukú á ti jẹ oúnjẹ alẹ́ tirẹ̀ ṣáájú, tó fi jẹ́ pé ebi á máa pa ẹnì kan, àmọ́ ọtí á máa pa ẹlòmíì. 22  Ṣé ẹ ò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ kí ẹ sì máa mu ni? Àbí ẹ̀ ń fojú pa ìjọ Ọlọ́run rẹ́, tí ẹ wá ń dójú ti àwọn tí kò ní nǹkan kan? Kí ni mo fẹ́ sọ fún yín? Ṣé kí n gbóríyìn fún yín ni? Lórí èyí, mi ò gbóríyìn fún yín. 23  Nítorí ọwọ́ Olúwa ni mo ti gba èyí tí mo fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú búrẹ́dì ní alẹ́ ọjọ́+ tí a ó dalẹ̀ rẹ̀, 24  lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 25  Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 26  Nítorí nígbàkigbà tí ẹ bá ń jẹ búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Olúwa, títí á fi dé. 27  Nítorí náà, ẹni tó bá jẹ búrẹ́dì náà tàbí tó mu ife Olúwa láìyẹ yóò jẹ̀bi nípa ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28  Kí èèyàn kọ́kọ́ dá ara rẹ̀ lójú lẹ́yìn tó bá ti yẹ ara rẹ̀ wò dáadáa,+ ẹ̀yìn ìgbà yẹn nìkan ni kó jẹ nínú búrẹ́dì náà, kó sì mu nínú ife náà. 29  Nítorí ẹni tó bá ń jẹ, tó sì ń mu, láìfi òye mọ ohun tí ara náà jẹ́, ó ń jẹ, ó sì ń mu ìdájọ́ sórí ara rẹ̀. 30  Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ nínú yín fi jẹ́ aláìlera àti aláìsàn, tí àwọn díẹ̀ sì ń sùn nínú ikú.*+ 31  Àmọ́ tí a bá fi òye mọ ẹni tí àwa fúnra wa jẹ́, a ò ní dá wa lẹ́jọ́. 32  Síbẹ̀, nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, Jèhófà* ló ń bá wa wí,+ kí a má bàa dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.+ 33  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá kóra jọ láti jẹ ẹ́, ẹ dúró de ara yín. 34  Tí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun nílé, kí ẹ má bàa kóra jọ fún ìdájọ́.+ Àmọ́ ní ti àwọn ọ̀ràn tó kù, màá bójú tó wọn nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí a dá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ mi.”
Ó ṣe kedere pé ikú nípa tẹ̀mí ló ń tọ́ka sí.