Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 7:1-60

  • Ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (1-53)

    • Ìgbà ayé àwọn baba ńlá (2-16)

    • Mósè ṣe aṣáájú; Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà (17-43)

    • Ọlọ́run kì í gbé inú tẹ́ńpìlì tí èèyàn kọ́ (44-50)

  • Wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta (54-60)

7  Àmọ́ àlùfáà àgbà béèrè lọ́wọ́ Sítéfánù pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà rí?”  Sítéfánù dáhùn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin bàbá, ẹ fetí sílẹ̀. Ọlọ́run ògo fara han Ábúráhámù baba ńlá wa nígbà tó wà ní Mesopotámíà, kí ó tó máa gbé ní Háránì,+  ó sì sọ fún un pé: ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.’+  Lẹ́yìn náà, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ń gbé ní Háránì. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run darí rẹ̀ láti ibẹ̀ pé kí ó lọ máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé báyìí.+  Síbẹ̀, kò fún un ní ogún kankan nínú rẹ̀, rárá, kò tiẹ̀ fún un ní ibi tó lè gbẹ́sẹ̀ lé; àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa fún un láti fi ṣe ohun ìní, lẹ́yìn rẹ̀ òun á fún ọmọ* rẹ̀,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ní ọmọ kankan.  Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run sọ fún un pé àwọn ọmọ* rẹ̀ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n* fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.+  ‘Màá dá orílẹ̀-èdè tí wọ́n máa ṣẹrú fún lẹ́jọ́,’+ ni Ọlọ́run wí, ‘lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, wọ́n á jáde, wọ́n á sì ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún mi ní ibí yìí.’+  “Ó tún fún Ábúráhámù ní májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́,*+ ó sì bí Ísákì,+ ó dádọ̀dọ́ rẹ̀* ní ọjọ́ kẹjọ,+ Ísákì sì bí* Jékọ́bù, Jékọ́bù sì bí àwọn olórí ìdílé* méjìlá (12).  Àwọn olórí ìdílé náà jowú Jósẹ́fù,+ wọ́n sì tà á sí Íjíbítì.+ Àmọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀,+ 10  ó gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀, ó ṣe ojúure sí i, ó sì fún un ní ọgbọ́n níwájú Fáráò ọba Íjíbítì. Ó yàn án láti ṣàkóso Íjíbítì àti gbogbo ilé rẹ̀.+ 11  Àmọ́ ìyàn kan mú ní gbogbo Íjíbítì àti Kénáánì, ìpọ́njú ńlá ni, àwọn baba ńlá wa ò sì rí nǹkan kan jẹ.+ 12  Àmọ́ Jékọ́bù gbọ́ pé oúnjẹ* wà ní Íjíbítì, ó sì rán àwọn baba ńlá wa jáde ní ìgbà àkọ́kọ́.+ 13  Nígbà kejì, Jósẹ́fù jẹ́ kí àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ òun, Fáráò náà sì mọ ìdílé Jósẹ́fù.+ 14  Torí náà, Jósẹ́fù ránṣẹ́ pe Jékọ́bù bàbá rẹ̀ àti gbogbo mọ̀lẹ́bí rẹ̀ láti ibẹ̀,+ gbogbo wọn* lápapọ̀ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rin (75).+ 15  Jékọ́bù lọ sí Íjíbítì,+ ó sì kú síbẹ̀,+ ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn baba ńlá wa.+ 16  Wọ́n gbé wọn lọ sí Ṣékémù, wọ́n sì tẹ́ wọn sínú ibojì tí Ábúráhámù fi owó fàdákà rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì ní Ṣékémù.+ 17  “Bó ṣe ku díẹ̀ kí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ, àwọn èèyàn náà gbilẹ̀, wọ́n sì di púpọ̀ ní Íjíbítì, 18  títí ọba míì fi jẹ ní Íjíbítì, ẹni tí kò mọ Jósẹ́fù.+ 19  Ẹni yìí lo ọgbọ́n àrékérekè fún ẹ̀yà wa, ó sì fipá mú àwọn bàbá láti pa àwọn ọmọ wọn jòjòló tì, kí wọ́n má bàa wà láàyè.+ 20  Lákòókò yẹn, wọ́n bí Mósè, Ọlọ́run sì fún un lẹ́wà gan-an.* Wọ́n fi oṣù mẹ́ta tọ́jú rẹ̀* ní ilé bàbá rẹ̀.+ 21  Àmọ́ nígbà tí wọ́n pa á tì,*+ ọmọbìnrin Fáráò gbé e, ó sì tọ́ ọ dàgbà bí ọmọ òun fúnra rẹ̀.+ 22  Nítorí náà, wọ́n kọ́ Mósè ní gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì. Kódà, ó di alágbára ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.+ 23  “Nígbà tó pé ẹni ogójì (40) ọdún, ó wá sí i lọ́kàn* láti lọ wo* àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 24  Nígbà tó tajú kán rí ọ̀kan lára wọn tí ará Íjíbítì kan ń hùwà àìdáa sí, ó gbèjà rẹ̀, ó sì bá ẹni tí wọ́n ń ṣàìdáa sí náà gbẹ̀san, ó pa ará Íjíbítì náà. 25  Ó rò pé àwọn arákùnrin òun máa lóye pé Ọlọ́run máa ti ọwọ́ òun gbà wọ́n là, àmọ́ kò yé wọn. 26  Lọ́jọ́ kejì, ó yọ sí wọn nígbà tí wọ́n ń jà, ó sì fẹ́ bá wọn parí ìjà ní àlàáfíà, ó sọ pé: ‘Ẹ̀yin èèyàn, arákùnrin ni yín. Kí ló dé tí ẹ̀ ń hùwà àìdáa sí ara yín?’ 27  Àmọ́ ẹni tó ń fìyà jẹ ọmọnìkejì rẹ̀ tì í dà nù, ó ní: ‘Ta ló fi ọ́ ṣe alákòóso àti onídàájọ́ lé wa lórí? 28  Àbí o tún fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Íjíbítì yẹn lánàá?’ 29  Bí Mósè ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó fẹsẹ̀ fẹ, ó sì lọ di àjèjì ní ilẹ̀ Mídíánì, ibẹ̀ ló ti bí ọmọkùnrin méjì.+ 30  “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, áńgẹ́lì kan fara hàn án ní aginjù Òkè Sínáì nínú ọwọ́ iná tó ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún.+ 31  Nígbà tí Mósè rí i, ohun tó rí yà á lẹ́nu. Àmọ́ bí ó ṣe ń sún mọ́ ọn láti wádìí ohun tí ó jẹ́, ó gbọ́ ohùn Jèhófà* pé: 32  ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù.’+ Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, kò sì gbójúgbóyà láti sọ pé òun fẹ́ wádìí sí i. 33  Jèhófà* sọ fún un pé: ‘Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. 34  Mo ti rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn mi tó wà ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ mo ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n sílẹ̀. Ní báyìí, wá, màá rán ọ lọ sí Íjíbítì.’ 35  Mósè yìí kan náà, tí wọ́n sọ pé àwọn ò mọ̀ rí, tí wọ́n sọ fún pé: ‘Ta ló fi ọ́ ṣe alákòóso àti onídàájọ́?’+ òun kan náà ni Ọlọ́run rán+ láti jẹ́ alákòóso àti olùdáǹdè nípasẹ̀ áńgẹ́lì tó fara hàn án látinú igi ẹlẹ́gùn-ún. 36  Ọkùnrin yìí mú wọn jáde,+ ó ṣe àwọn ohun ìyanu* àti iṣẹ́ àmì ní Íjíbítì+ àti ní Òkun Pupa+ àti ní aginjù fún ogójì (40) ọdún.+ 37  “Mósè yìí ló sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ọlọ́run máa gbé wòlíì kan bí èmi dìde fún yín láàárín àwọn arákùnrin yín.’+ 38  Ẹni yìí wà lára ìjọ tó wà ní aginjù, ó wà pẹ̀lú áńgẹ́lì+ tó bá a sọ̀rọ̀+ lórí Òkè Sínáì pẹ̀lú àwọn baba ńlá wa, ó sì gba àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ tó jẹ́ ààyè láti fún wa.+ 39  Àmọ́ àwọn baba ńlá wa kọ̀, wọn ò ṣègbọràn sí i, ṣe ni wọ́n tì í sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,+ wọ́n sì pa dà sí Íjíbítì nínú ọkàn wọn,+ 40  wọ́n sọ fún Áárónì pé: ‘Ṣe àwọn ọlọ́run fún wa tó máa ṣáájú wa. Torí a ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí Mósè yìí, ẹni tó kó wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’+ 41  Nítorí náà, wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù kan lákòókò yẹn, wọ́n mú ẹbọ wá fún ère náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn.+ 42  Torí náà, Ọlọ́run pa dà lẹ́yìn wọn, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n lọ máa sin àwọn ọmọ ogun ọ̀run,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé àwọn Wòlíì pé: ‘Èmi kọ́ ni ẹ̀ ń mú ọrẹ àti ẹbọ wá fún ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí ẹ fi wà ní aginjù, àbí èmi ni, ilé Ísírẹ́lì? 43  Àmọ́ àgọ́ Mólókù+ àti ìràwọ̀ ọlọ́run Réfánì tí ẹ̀ ń gbé ga ni, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa jọ́sìn wọn. Nítorí náà, màá lé yín dà nù kọjá Bábílónì.’+ 44  “Àwọn baba ńlá wa ní àgọ́ ẹ̀rí nínú aginjù, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ nígbà tó sọ fún Mósè pé kó ṣe é bí èyí tí ó rí.+ 45  Àwọn baba ńlá wa jogún rẹ̀, wọ́n sì gbé e wá nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé Jóṣúà bọ̀ ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ àwọn tí Ọlọ́run lé jáde kúrò níwájú àwọn baba ńlá wa.+ Ó sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà ayé Dáfídì. 46  Ó rí ojú rere Ọlọ́run, ó sì ní kó fún òun láǹfààní láti kọ́ ibùgbé fún Ọlọ́run Jékọ́bù.+ 47  Àmọ́ Sólómọ́nì ló kọ́ ilé fún un.+ 48  Síbẹ̀, Ẹni Gíga Jù Lọ kì í gbé àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́,+ bí wòlíì kan ṣe sọ pé: 49  ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,+ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.+ Irú ilé wo lẹ fẹ́ kọ́ fún mi? ni Jèhófà* wí. Àbí ibo ni ibi ìsinmi mi? 50  Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan yìí, àbí òun kọ́?’+ 51  “Ẹ̀yin olóríkunkun àti aláìkọlà* ọkàn àti etí, gbogbo ìgbà lẹ̀ ń ta ko ẹ̀mí mímọ́; bí àwọn baba ńlá yín ti ṣe náà lẹ̀ ń ṣe.+ 52  Èwo nínú àwọn wòlíì ni àwọn baba ńlá yín kò ṣe inúnibíni sí?+ Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n pa àwọn tó kéde pé olódodo náà ń bọ̀,+ ẹni tí ẹ dalẹ̀ rẹ̀ tí ẹ sì pa,+ 53  ẹ̀yin tí ẹ gba Òfin bí ó ṣe wá látọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì+ àmọ́ tí ẹ kò pa á mọ́.” 54  Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọ́n gbaná jẹ,* wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wa eyín wọn pọ̀ sí i. 55  Àmọ́ òun, tó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ń wo ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti ti Jésù tó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run,+ 56  ó sọ pé: “Ẹ wò ó! Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ èèyàn+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”+ 57  Ni wọ́n bá figbe ta bí ohùn wọn ṣe lè ròkè tó, wọ́n fi ọwọ́ bo etí wọn, gbogbo wọn sì ṣùrù bò ó. 58  Lẹ́yìn tí wọ́n jù ú sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ́ lókùúta.+ Àwọn ẹlẹ́rìí+ kó aṣọ àwọ̀lékè wọn síbi ẹsẹ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Sọ́ọ̀lù.+ 59  Bí wọ́n ṣe ń sọ òkúta lu Sítéfánù, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60  Lẹ́yìn náà, ó kúnlẹ̀, ó sì fi ohùn líle ké jáde pé: “Jèhófà,* má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.”+ Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó sùn nínú ikú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “èso.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “pọ́n wọn lójú.”
Tàbí “àwọn baba ńlá.”
Tàbí kó jẹ́, “ṣe bákan náà sí.”
Tàbí “kọlà fún un.”
Tàbí “ìkọlà.”
Tàbí “ọkà.”
Tàbí “ọkàn náà.”
Tàbí “tọ́ ọ.”
Tàbí “ó rẹwà lójú Ọlọ́run.”
Tàbí “gbé e síta.”
Tàbí “pinnu.”
Tàbí “ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀.”
Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí “aláìdádọ̀dọ́.”
Tàbí “ó dùn wọ́n wọra.”