Sí Àwọn Hébérù 4:1-16

  • Ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n wọnú ìsinmi Ọlọ́run (1-10)

  • Ká sapá ká lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run (11-13)

    • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè (12)

  • Jésù, àlùfáà àgbà tó tóbi (14-16)

4  Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé ìlérí tó ṣe pé a máa wọnú ìsinmi òun ṣì wà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra,* kó má bàa di pé ẹnì kan nínú yín ò kúnjú ìwọ̀n rẹ̀.+  Torí wọ́n ti kéde ìhìn rere fún àwa náà,+ bíi tiwọn; àmọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ ò ṣe wọ́n láǹfààní, torí ìgbàgbọ́ wọn ò bá ti àwọn tó fetí sílẹ̀ mu.  Torí àwa tí a ní ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà, bó ṣe sọ pé: “Torí náà, mo búra nínú ìbínú mi pé, ‘Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi,’”+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ti parí látìgbà ìpìlẹ̀ ayé.+  Torí ibì kan wà tó ti sọ nípa ọjọ́ keje pé: “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,”+  ó tún sọ níbí yìí pé: “Wọn ò ní wọnú ìsinmi mi.”+  Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé àwọn kan ò tíì wọnú rẹ̀, tí àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere ò sì wọnú rẹ̀ torí àìgbọràn,+  bó ṣe sọ pé, “Òní” nínú sáàmù ti Dáfídì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àkókò, ó tún sàmì sí ọjọ́ kan pàtó; bẹ́ẹ̀ náà la sọ ṣáájú pé, “Lónìí, tí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le.”+  Torí ká ní Jóṣúà+ ti mú wọn dé ibi ìsinmi ni, Ọlọ́run ò tún ní sọ̀rọ̀ ọjọ́ míì lẹ́yìn náà.  Torí náà, ìsinmi sábáàtì kan ṣì wà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run.+ 10  Torí ẹni tó wọnú ìsinmi Ọlọ́run ti sinmi pẹ̀lú lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ rẹ̀, bí Ọlọ́run ṣe sinmi lẹ́yìn iṣẹ́ tirẹ̀.+ 11  Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnì kankan má bàa kó sínú irú ìwà àìgbọràn kan náà.+ 12  Torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára,+ ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ,+ ó sì ń gúnni, àní débi pé ó ń pín ọkàn* àti ẹ̀mí* níyà, ó ń pín àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò. 13  Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀,+ àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.+ 14  Torí náà, nígbà tó jẹ́ pé àlùfáà àgbà tó tóbi la ní, ẹni tó ti la ọ̀run kọjá, Jésù Ọmọ Ọlọ́run,+ ẹ jẹ́ ká máa kéde rẹ̀ ní gbangba.+ 15  Torí àlùfáà àgbà tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa,+ àmọ́ ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi tiwa, àmọ́ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.+ 16  Torí náà, ẹ jẹ́ ká sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ká sọ̀rọ̀ ní fàlàlà,+ ká lè rí àánú gbà, ká sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó máa ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó tọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “ẹ jẹ́ ká máa bẹ̀rù.”