Sí Títù 1:1-16

  • Ìkíni (1-4)

  • Kí Títù yan àwọn alàgbà ní Kírétè (5-9)

  • Bá àwọn ọlọ̀tẹ̀ wí (10-16)

1  Pọ́ọ̀lù, ẹrú Ọlọ́run àti àpọ́sítélì Jésù Kristi, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ bá ti àwọn tí Ọlọ́run yàn mu, tó sì bá ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ àti ìfọkànsin Ọlọ́run mu,  èyí tó dá lórí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun+ tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè parọ́,+ ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́;  àmọ́ nígbà tí àkókò tó lójú rẹ̀, ó jẹ́ kí a mọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó fi lé mi lọ́wọ́,+ èyí tí Olùgbàlà wa, Ọlọ́run pa láṣẹ;  sí Títù, ọmọ gidi tí a jọ jẹ́ onígbàgbọ́: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti ti Kristi Jésù Olùgbàlà wa máa wà pẹ̀lú rẹ.  Mo fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí kò tọ́,* kí o sì lè yan àwọn alàgbà láti ìlú dé ìlú, bí mo ṣe sọ fún ọ pé kí o ṣe:  bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà tí kò ní ẹ̀sùn lọ́rùn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí wọn kò sì ní ẹ̀sùn lọ́rùn pé wọ́n jẹ́ oníwà pálapàla* tàbí ọlọ̀tẹ̀.+  Torí pé alábòójútó jẹ́ ìríjú Ọlọ́run, kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀sùn lọ́rùn, kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń ṣe tinú ara rẹ̀,+ kó má ṣe jẹ́ ẹni tó ń tètè bínú,+ kó má ṣe jẹ́ ọ̀mùtípara, kó má ṣe jẹ́ oníwà ipá,* kó má sì jẹ́ ẹni tó máa ń wá èrè tí kò tọ́,  àmọ́ kó jẹ́ ẹni tó ń ṣe aájò àlejò,+ tó nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tó ní àròjinlẹ̀,*+ tó jẹ́ olódodo, olóòótọ́,+ tó máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu,+  ẹni tó ń di ọ̀rọ̀ òtítọ́* mú ṣinṣin nínú ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́,*+ kó lè fi ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní*+ gbani níyànjú* kó sì bá àwọn tó ń ṣàtakò wí.+ 10  Nítorí ọ̀pọ̀ ọlọ̀tẹ̀ èèyàn ló wà, àwọn tó ń sọ̀rọ̀ tí kò wúlò, tí wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́tàn, pàápàá àwọn tó ń rin kinkin mọ́ ìdádọ̀dọ́.*+ 11  Rí i dájú pé o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, torí àwọn èèyàn yìí ń ba ìgbàgbọ́ àwọn agbo ilé jẹ́ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ torí wọ́n ń wá èrè tí kò tọ́. 12  Ọ̀kan lára wọn tó jẹ́ wòlíì wọn sọ pé: “Òpùrọ́ paraku ni àwọn ará Kírétè, ẹranko ni wọ́n, ọ̀lẹ alájẹkì.” 13  Òótọ́ ni ẹ̀rí yìí. Torí náà, máa bá wọn wí lọ́nà tó múná, kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára, 14  kí wọ́n má ṣe fiyè sí ìtàn àròsọ àwọn Júù àti àṣẹ àwọn èèyàn tí wọ́n ti kúrò nínú òtítọ́. 15  Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́.+ Àmọ́ fún àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìnígbàgbọ́, kò sí ohun tí ó mọ́, torí èrò inú wọn àti ẹ̀rí ọkàn wọn jẹ́ ẹlẹ́gbin.+ 16  Wọ́n sọ ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, àmọ́ iṣẹ́ wọn fi hàn pé wọ́n kọ̀ ọ́,+ torí wọ́n jẹ́ ẹni ìkórìíra àti aláìgbọràn, wọn kò sì yẹ fún iṣẹ́ rere kankan.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó jẹ́ àbùkù.”
Tàbí “ewèlè.”
Tàbí “aluni.”
Tàbí “làákàyè; ọgbọ́n.”
Tàbí “ọ̀rọ̀ tó ṣeé gbára lé.”
Tàbí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”
Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”
Tàbí “fúnni níṣìírí.”
Tàbí “ìkọlà.”