Àkọsílẹ̀ Jòhánù 1:1-51

  • Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara (1-18)

  • Jòhánù Arinibọmi jẹ́rìí (19-28)

  • Jésù ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run (29-34)

  • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù kọ́kọ́ yàn (35-42)

  • Fílípì àti Nàtáníẹ́lì (43-51)

1  Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà+ wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run,+ Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.*+  Ẹni yìí wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀.  Ohun gbogbo wà nípasẹ̀ rẹ̀+ àti pé láìsí i, kò sí nǹkan kan tó wà. Ohun tó wà  nípasẹ̀ rẹ̀ ni ìyè, ìyè náà sì ni ìmọ́lẹ̀ àwọn èèyàn.+  Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn nínú òkùnkùn,+ àmọ́ òkùnkùn náà ò borí rẹ̀.  Ọkùnrin kan wà tí a rán láti jẹ́ aṣojú Ọlọ́run; Jòhánù+ ni orúkọ rẹ̀.  Ọkùnrin yìí wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kó lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà,+ kí onírúurú èèyàn lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.  Òun kọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yẹn,+ àmọ́ a ṣètò pé kó jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ yẹn.  Ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tó ń fún onírúurú èèyàn ní ìmọ́lẹ̀ máa tó wá sí ayé.+ 10  Ó ti wà ní ayé,+ ayé sì wà nípasẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ayé ò mọ̀ ọ́n. 11  Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, àmọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ò gbà á. 12  Ṣùgbọ́n ó fún gbogbo àwọn tó gbà á ní àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.+ 13  A ò bí wọn látinú ẹ̀jẹ̀ tàbí látinú ìfẹ́ ti ara tàbí látinú ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ a bí wọn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 14  Torí náà, Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,+ ó gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, irú ògo tó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo+ ti bàbá kan; ó sì kún fún oore Ọlọ́run* àti òtítọ́. 15  (Jòhánù jẹ́rìí nípa rẹ̀, àní, ó ké jáde pé: “Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi ti lọ níwájú mi, torí ó ti wà ṣáájú mi.’”)+ 16  Torí látinú ẹ̀kún rẹ̀, àní gbogbo wa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. 17  Torí a fúnni ní Òfin nípasẹ̀ Mósè,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti òtítọ́ wà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+ 18  Kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí;+ ọlọ́run bíbí kan ṣoṣo+ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ Baba*+ ni ẹni tó ṣàlàyé Rẹ̀.+ 19  Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ nìyí nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lọ bi í pé: “Ta ni ọ́?”+ 20  Ó sọ òótọ́, kò sì sẹ́, ó ní: “Èmi kọ́ ni Kristi.” 21  Wọ́n bi í pé: “Ta wá ni ọ́? Ṣé ìwọ ni Èlíjà?”+ Ó dáhùn pé: “Èmi kọ́.” “Ṣé ìwọ ni Wòlíì náà?”+ Ó dáhùn pé: “Rárá!” 22  Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ta ni ọ́? Sọ fún wa ká lè mọ ohun tí a máa sọ fún àwọn tó rán wa níṣẹ́. Kí lo sọ nípa ara rẹ?” 23  Ó sọ pé: “Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké nínú aginjù pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà Jèhófà* tọ́,’+ bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ.”+ 24  Àwọn Farisí ló rán àwọn èèyàn yìí. 25  Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn èèyàn tí kì í bá ṣe ìwọ ni Kristi tàbí Èlíjà tàbí Wòlíì náà?” 26  Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Omi ni mo fi ń batisí. Ẹnì kan wà láàárín yín tí ẹ kò mọ̀, 27  ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí mi ò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”+ 28  Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì ní òdìkejì Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn.+ 29  Lọ́jọ́ kejì, ó rí i tí Jésù ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀+ ayé lọ!+ 30  Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ó ti lọ níwájú mi, torí ó wà ṣáájú mi.’+ 31  Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ ìdí tí mo fi wá, tí mò ń fi omi batisí ni pé ká lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.”+ 32  Jòhánù náà jẹ́rìí sí i, ó ní: “Mo rí i tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e.+ 33  Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé,+ òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’+ 34  Mo ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ 35  Nígbà tó tún di ọjọ́ kejì, Jòhánù dúró pẹ̀lú méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 36  bó sì ṣe rí Jésù tó ń rìn lọ, ó sọ pé: “Ẹ wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run!” 37  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì gbọ́ ohun tó sọ yìí, wọ́n tẹ̀ lé Jésù. 38  Jésù wá yíjú pa dà, bó sì ṣe rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé òun, ó bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sọ fún un pé: “Rábì (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́”), ibo lò ń gbé?” 39  Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí ẹ wá wò ó.” Wọ́n wá lọ wo ibi tó ń gbé, wọ́n sì dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ yẹn; nǹkan bíi wákàtí kẹwàá ni.* 40  Áńdérù+ arákùnrin Símónì Pétérù wà lára àwọn méjì tó gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. 41  Ó kọ́kọ́ wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “A ti rí Mèsáyà náà”+ (tó túmọ̀ sí “Kristi”), 42  ó sì mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù. Nígbà tí Jésù wò ó, ó sọ pé: “Ìwọ ni Símónì,+ ọmọ Jòhánù; a ó máa pè ọ́ ní Kéfà” (tó túmọ̀ sí “Pétérù”).+ 43  Lọ́jọ́ kejì, ó fẹ́ lọ sí Gálílì. Jésù wá rí Fílípì,+ ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” 44  Bẹtisáídà, ìlú Áńdérù àti Pétérù, ni Fílípì ti wá. 45  Fílípì rí Nàtáníẹ́lì,+ ó sì sọ fún un pé: “A ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: Jésù, ọmọ Jósẹ́fù,+ láti Násárẹ́tì.” 46  Àmọ́ Nàtáníẹ́lì sọ fún un pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?” Fílípì sọ fún un pé: “Wá wò ó.” 47  Jésù rí i tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ nípa rẹ̀ pé: “Wò ó, ní tòótọ́, ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀tàn kankan ò sí nínú rẹ̀.”+ 48  Nàtáníẹ́lì bi í pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ mí?” Jésù dá a lóhùn pé: “Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí o wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, ni mo ti rí ọ.” 49  Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”+ 50  Jésù sọ fún un pé: “Ṣé torí pé mo sọ fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ lo ṣe gbà gbọ́? O máa rí àwọn nǹkan tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” 51  Ó wá sọ fún un pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ èèyàn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “jẹ́ ẹni ti ọ̀run.”
Tàbí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.”
Tàbí “ní oókan àyà Baba.” Ipò ojúure àrà ọ̀tọ̀ ni èyí ń tọ́ka sí.
Ìyẹn, nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́.