Òwe 20:1-30

  • Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì (1)

  • Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù (4)

  • Èrò ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn (5)

  • Ìkìlọ̀ lórí kéèyàn kánjú jẹ́ ẹ̀jẹ́ (25)

  • Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn (29)

20  Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì,+ aláriwo ni ọtí;+Ẹni tó bá sì tipasẹ̀ wọn ṣìnà kò gbọ́n.+   Ẹ̀rù* tó wà lára ọba dà bí ìgbà tí kìnnìún* bá ń kùn;+Ẹnikẹ́ni tó bá mú un bínú ń fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu.+   Ògo ló jẹ́ fún èèyàn láti yẹra fún ìjà,+Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ jẹ́ aríjàgbá.+   Ọ̀lẹ kì í túlẹ̀ nígbà òtútù,Tó bá dìgbà ìkórè, á máa tọrọ torí pé kò ní nǹkan kan.*+   Èrò* ọkàn èèyàn dà bí omi jíjìn,Àmọ́ olóye ló ń fà á jáde.   Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé àwọn ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀,Àmọ́ ibo la ti lè rí olóòótọ́ èèyàn?   Olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀.+ Aláyọ̀ ni àwọn ọmọ* tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀.+   Nígbà tí ọba bá jókòó sórí ìtẹ́ láti dájọ́,+Ó máa ń fi ojú rẹ̀ yẹ ọ̀ràn wò kí ó lè mú gbogbo ìwà ibi kúrò.+   Ta ló lè sọ pé: “Mo ti wẹ ọkàn mi mọ́;+Mo ti mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi”?+ 10  Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n èké*Àwọn méjèèjì jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà.+ 11  Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé* pàápàá dá a mọ̀,Bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.+ 12  Etí tí a fi ń gbọ́ràn àti ojú tí a fi ń ríranJèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+ 13  Má ṣe nífẹ̀ẹ́ oorun, torí wàá di aláìní.+ La ojú rẹ, wàá sì máa jẹ àjẹtẹ́rùn.+ 14  “Èyí ò dáa, tọ̀hún ò dáa!” ni ẹni tó ń rajà ń sọ;Lẹ́yìn náà, ó bá tirẹ̀ lọ, ó sì ń yangàn.+ 15  Wúrà wà, ọ̀pọ̀ iyùn* sì wà,Àmọ́ ètè ìmọ̀ jẹ́ ohun tó ṣeyebíye.+ 16  Gba ẹ̀wù ẹni tó bá ṣe onídùúró fún àjèjì;+Tó bá sì jẹ́ pé obìnrin àjèjì* ló ṣe é fún, gba ohun tó fi ṣe ìdúró lọ́wọ́ rẹ̀.+ 17  Oúnjẹ tí a fi èrú kó jọ máa ń dùn lẹ́nu èèyàn,Àmọ́ tó bá yá, òkúta ni yóò kún ẹnu rẹ̀.+ 18  Ìmọ̀ràn* máa ń jẹ́ kí ohun téèyàn fẹ́ ṣe yọrí sí rere,*+Ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n sì ni kí o fi ja ogun rẹ.+ 19  Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri;+Má ṣe bá ẹni tó fẹ́ràn láti máa ṣòfófó* kẹ́gbẹ́. 20  Ẹni tó bá bú bàbá àti ìyá rẹ̀,Fìtílà rẹ̀ yóò kú nígbà tí òkùnkùn bá ṣú.+ 21  Ogún téèyàn bá fi ojúkòkòrò gbà níbẹ̀rẹ̀Kì í ní ìbùkún lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.+ 22  Má ṣe sọ pé: “Màá fi búburú san búburú!”+ Ní ìrètí nínú Jèhófà,+ yóò sì gbà ọ́ là.+ 23  Jèhófà kórìíra ìwọ̀n èké,*Òṣùwọ̀n èké kò sì dára. 24  Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ èèyàn;+Báwo ni èèyàn ṣe lè lóye ọ̀nà ara rẹ̀?* 25  Ìdẹkùn ni téèyàn bá sọ láìronú pé, “Mímọ́!”+ Lẹ́yìn náà, kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú lórí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́.+ 26  Ọlọ́gbọ́n ọba máa ń yọ àwọn ẹni ibi sọ́tọ̀+Á sì wa àgbá kẹ̀kẹ́ ìpakà kọjá lórí wọn.+ 27  Èémí èèyàn jẹ́ fìtílà Jèhófà,Ó ń ṣàyẹ̀wò inú rẹ̀ lọ́hùn-ún. 28  Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ ń dáàbò bo ọba;+Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sì ń jẹ́ kó pẹ́ lórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 29  Ògo àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn,+Iyì àwọn arúgbó sì ni ewú orí wọn.+ 30  Ọgbẹ́ àti egbò máa ń fọ* ibi dà nù,+Lílù sì ń fọ inú èèyàn lọ́hùn-ún mọ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ìpayà.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí kó jẹ́, “Á máa wá nǹkan nígbà ìkórè, àmọ́ kò ní rí nǹkan kan.”
Ní Héb., “Ìmọ̀ràn.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin.”
Tàbí “Òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì àti ohun èèlò ìdíwọ̀n oríṣi méjì.”
Tàbí “ọmọdékùnrin.”
Tàbí “àjèjì kan.”
Tàbí “Àmọ̀ràn.”
Tàbí “fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
Tàbí “ẹni tó máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ fajú èèyàn mọ́ra.”
Tàbí “òkúta ìwọ̀n oríṣi méjì.”
Tàbí “ọ̀nà tó yẹ kó gbà?”
Tàbí “nu.”