Sí Àwọn Hébérù 7:1-28

  • Melikisédékì, ọba àti àlùfáà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (1-10)

  • Bí Jésù ṣe jẹ́ àlùfáà tó tóbi jù (11-28)

    • Kristi lè gbani là pátápátá (25)

7  Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, pàdé Ábúráhámù nígbà tó ń pa dà bọ̀ látibi tó ti pa àwọn ọba, ó sì súre fún un,+  Ábúráhámù wá fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.* Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ọba Òdodo,” bákan náà, ọba Sálẹ́mù, ìyẹn “Ọba Àlàáfíà.”  Bó ṣe jẹ́ pé kò ní bàbá, kò ní ìyá, kò ní ìran, kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kò sì ní òpin ìwàláàyè, àmọ́ tí a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ àlùfáà títí láé.*+  Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ṣe tóbi tó, ẹni tí Ábúráhámù, olórí ìdílé,* fún ní ìdá mẹ́wàá àwọn ẹrù ogun tó dáa jù.+  Lóòótọ́, bí Òfin ṣe sọ, a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n gba iṣẹ́ àlùfáà wọn pé kí wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn,+ ìyẹn lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí àwọn yìí tiẹ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù.  Àmọ́ ọkùnrin yìí tí kò wá láti ìran wọn gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí a ṣèlérí fún.+  Torí náà, ó ṣe kedere pé ẹni tí ó tóbi súre fún ẹni tí ó kéré.  Àti pé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, àwọn èèyàn tó ń kú ló ń gba ìdá mẹ́wàá, àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ kejì, ẹnì kan tí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé ó wà láàyè ni.+  A sì lè sọ pé Léfì tó ń gba ìdá mẹ́wàá pàápàá ti san ìdá mẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù, 10  torí àtọmọdọ́mọ tí a kò tíì bí ló ṣì jẹ́ sí* baba ńlá rẹ̀ nígbà tí Melikisédékì pàdé rẹ̀.+ 11  Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ àlùfáà+ àwọn ọmọ Léfì lè mú ìjẹ́pípé wá ni (torí ó wà lára Òfin tí a fún àwọn èèyàn), ṣé a tún máa nílò kí àlùfáà míì dìde, ẹni tí a sọ pé ó wà ní ọ̀nà ti Melikisédékì,+ tí kì í ṣe ní ọ̀nà ti Áárónì? 12  Torí nígbà tí a ti yí ètò ṣíṣe àlùfáà pa dà, ó di dandan ká yí Òfin náà pa dà.+ 13  Torí ẹ̀yà míì ni ọkùnrin tí a sọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ ti wá, ẹnì kankan látinú ẹ̀yà náà ò sì ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ rí.+ 14  Torí ó ṣe kedere pé ọ̀dọ̀ Júdà ni Olúwa wa ti ṣẹ̀ wá,+ síbẹ̀, Mósè ò sọ pé àlùfáà kankan máa wá látinú ẹ̀yà yẹn. 15  Èyí wá túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí àlùfáà+ míì tó dà bíi Melikisédékì+ dìde, 16  ẹni tó jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí òfin sọ nípa ibi tí èèyàn ti ṣẹ̀ wá ló mú kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run.+ 17  Torí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+ 18  Torí náà, a pa àṣẹ ti tẹ́lẹ̀ tì torí pé kò lágbára, kò sì gbéṣẹ́ mọ́.+ 19  Torí Òfin ò sọ ohunkóhun di pípé,+ àmọ́ ìrètí tó dáa jù+ tó wọlé wá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tí à ń tipasẹ̀ rẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.+ 20  Bákan náà, nígbà tó jẹ́ pé a ò ṣe èyí láìsí ìbúra 21  (torí ní tòótọ́, àwọn èèyàn wà tí wọ́n ti di àlùfáà láìsí ìbúra, àmọ́ ti ẹni yìí rí bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìbúra tí a ṣe nípa rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ẹni tó sọ pé: “Jèhófà* ti búra, kò sì ní pèrò dà,* ó ní, ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé’”),+ 22  Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó fìdí májẹ̀mú tó dáa jù múlẹ̀.*+ 23  Bákan náà, ó di dandan kí ọ̀pọ̀ di àlùfáà tẹ̀ léra+ torí pé ikú ò jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ, 24  àmọ́ torí pé òun wà láàyè títí láé,+ kò sí pé ẹnì kan ń rọ́pò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà. 25  Èyí jẹ́ kó lè gba àwọn tó ń tipasẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run là pátápátá, torí ó wà láàyè nígbà gbogbo láti bá wọn bẹ̀bẹ̀.+ 26  Torí irú àlùfáà àgbà yìí ló yẹ wá, ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin, aláìṣẹ̀, aláìlẹ́gbin,+ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbé ga ju ọ̀run lọ.+ 27  Kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́,+ bíi ti àwọn àlùfáà àgbà yẹn, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn,+ torí ó ti ṣe èyí nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.+ 28  Torí àwọn èèyàn tó ní àìlera ni Òfin ń yàn ṣe àlùfáà àgbà,+ àmọ́ Ọmọ ni ọ̀rọ̀ ìbúra+ tí a ṣe lẹ́yìn Òfin yàn, ẹni tí a ti sọ di pípé+ títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Grk., “pín ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan fún un.”
Tàbí “títí lọ gbére.”
Tàbí “baba ńlá.”
Ní Grk., “jáde láti abẹ́nú.”
Ní Grk., “torí ó ṣì wà ní abẹ́nú.”
Tàbí “yí ìpinnu rẹ̀ pa dà.”
Tàbí “ẹni tí a fi ṣe ìdúró májẹ̀mú tó dáa jù.”