Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Jésù kú torí kí àwọn èèyàn lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 6:23; Éfésù 1:7) Ikú Jésù tún fi hàn pé èèyàn lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run kódà lójú àdánwò tó le jù lọ.​—Hébérù 4:15.

 Wo bí ikú ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè ṣàǹfààní tó bẹ́ẹ̀.

  1.   Jésù kú ká lè rí “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa” gbà.​—Kólósè 1:14.

     Ẹni pípé ni Ádámù nígbà tí Ọlọ́run dá a, kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan lọ́rùn. Àmọ́, ó yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àìgbọràn tí Ádámù ṣe, tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá yìí, ṣàkóbá fún gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Bíbélì sọ pé, “Nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀.”​—Róòmù 5:19.

     Ẹni pípé ni Jésù náà, àmọ́ kò dẹ́ṣẹ̀ rí. Torí náà, ó lè jẹ́ “ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 2:2) Bí àìgbọràn Ádámù ṣe kó ẹ̀ṣẹ̀ ran gbogbo aráyé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú Jésù ṣe yọ àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.

     A lè sọ pé, ṣe ni Ádámù ta ọmọ aráyé sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ Jésù yọ̀ǹda tinútinú láti kú torí wa, ó sì ra aráyé pa dà sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Torí náà, “bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.”​—1 Jòhánù 2:1.

  2.   Jésù kú “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòhánù 3:16.

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run dá Ádámù pé kó wà láàyè títí láé, ẹ̀ṣẹ̀ tó dá ló fà á tó fi kú. Látọ̀dọ̀ Ádámù, “ẹ̀ṣẹ̀ . . . wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”​—Róòmù 5:12.

     Àmọ́ ikú Jésù mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, ó tún fagi lé ìyà ikú tó tọ́ sí wọn. Bíbélì ṣàlàyé ẹ̀ ní ṣókí, ó ní: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú ikú, bákan náà pẹ̀lú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nípasẹ̀ òdodo pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa.”​—Róòmù 5:21.

     Lóòótọ́, ẹ̀mí ọmọ aráyé kì í gùn lónìí. Àmọ́, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tó bá jẹ́ olódodo ní ìyè àìnípẹ̀kun, òun sì máa jí àwọn tó bá ti kú dìde kí àwọn náà lè jàǹfààní látinú ikú Jésù.​—Sáàmù 37:29; 1 Kọ́ríńtì 15:22.

  3.   Jésù jẹ́ “onígbọràn títí dé ikú,” èyí fi hàn pé èèyàn lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka àdánwò èyíkéyìí tó kojú sí.​—Fílípì 2:8.

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Ádámù, tí kò lábùkù kankan lára, síbẹ̀ ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run torí pé ó mọ tara rẹ̀ nìkan, ohun tí kì í ṣe tiẹ̀ ló wù ú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:6) Nígbà tó yá, Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run sọ pé kò sí èèyàn kankan tó máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run láìjẹ́ pé ó ń rí nǹkan gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, pàápàá tó bá wá jẹ́ pé ẹ̀mí ẹni náà wà nínú ewu. (Jóòbù 2:4) Síbẹ̀, Jésù tó jẹ́ ẹni pípé ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kódà nígbà tí wọ́n fi ṣẹ̀sín, tó sì kú ikú oró. (Hébérù 7:26) Ibi tọ́rọ̀ náà já sí ni pé: Èèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka àdánwò èyíkéyìí tí ẹni náà bá kojú sí.

Ìbéèrè nípa ikú Jésù

  •   Kí nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà, kó sì kú torí kó lè ra aráyé pa dà? Kí ló dé tí Ọlọ́run ò kàn fagi lé ìyà ikú tó tọ́ sí ọmọ èèyàn?

     Òfin Ọlọ́run sọ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Ọlọ́run ò fi òfin yìí pa mọ́ fún Ádámù, ó sọ fún Ádámù pé tó bá ti ṣàìgbọràn, ikú ni èrè rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:3) Nígbà tí Ádámù sì ṣẹ̀, Ọlọ́run, “ẹni tí kò lè purọ́,” ṣe ohun tó sọ póun máa ṣe. (Títù 1:2) Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nìkan làwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù jogún lára rẹ̀, wọ́n tún jogún ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fà, ìyẹn ikú.

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ikú ló tọ́ sí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run fi “ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀” hàn sí wọn. (Éfésù 1:7) Ọlọ́run ṣètò láti rán Jésù tó jẹ́ ẹni pípé wá láti fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ kó lè ra aráyé pa dà. Ìdájọ́ òdodo gbáà lohun tí Ọlọ́run ṣe yìí, ó sì ṣàánú ọmọ aráyé lọ́nà tó ga.

  •   Ìgbà wo ni Jésù kú?

     Jésù kú ní “wákàtí kẹsàn-án” sí ìgbà tí oòrùn yọ, tàbí ká sọ pé nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán, lọ́jọ́ táwọn Júù ń ṣe Ìrékọjá. (Máàkù 15:33-37) Friday, April 1, 33 Sànmánì Kristẹni, ni ọjọ́ yẹn bọ́ sí tá a bá wò ó lórí kàlẹ́ńdà òde òní.

  •   Ibo ni Jésù kú sí?

     “Ibi tí àwọn ènìyàn ń pè ní Ibi Agbárí, èyí tí a ń pè ní Gọ́gọ́tà ní èdè Hébérù” ni wọ́n ti pa Jésù. (Jòhánù 19:17, 18) Nígbà ayé Jésù, ‘ẹ̀yìn ibodè’ ìlú Jerúsálẹ́mù ni ibẹ̀ wà. (Hébérù 13:12) Ó ṣeé ṣe kí ibẹ̀ jẹ́ orí òkè kékeré kan, torí Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn kan ń wo Jésù “láti ọ̀ọ́kán” lórí igi tí wọ́n kàn án mọ́. (Máàkù 15:40) Àmọ́ kò ṣeé fi gbogbo ẹnu sọ pé ibi báyìí ni Gọ́gọ́tà wà lóde òní.

  •   Báwo ni Jésù ṣe kú?

     Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé orí àgbélébùú ni wọ́n kan Jésù mọ́, Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí òun tìkárarẹ̀ fi ara rẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi.” (1 Pétérù 2:24, Bíbélì Mímọ́) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì ni àwọn tó kọ Bíbélì lò nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn èèyàn fi pa Jésù. Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni stau·rosʹ àti xyʹlon. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé igi tàbí òpó gbọọrọ kan, tí wọn ò dábùú rẹ̀, ni ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí ń tọ́ka sí.

  •   Báwo ló ṣe yẹ ká máa rántí ikú Jésù?

     Lálẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá táwọn Júù máa ń ṣe lọ́dọọdún, Jésù fi ohun kan tó rọrùn lọ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (1 Kọ́ríńtì 11:24) Wákàtí mélòó kan lẹ́yìn náà ni wọ́n pa Jésù.

     Àwọn tó kọ Bíbélì fi Jésù wé ọmọ àgùntàn tí wọ́n fi máa ń rúbọ nígbà Ìrékọjá. (1 Kọ́ríńtì 5:7) Bó ṣe jẹ́ pé ayẹyẹ Ìrékọjá máa ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọ́n ti dòmìnira kúrò lóko ẹrú, bẹ́ẹ̀ náà ni Ìrántí Ikú Jésù Kristi máa ń rán àwọn Kristẹni létí pé wọ́n ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nísàn 14 ni ayẹyẹ Ìrékọjá bọ́ sí lórí kàlẹ́ńdà táwọn èèyàn ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọdọọdún ni wọ́n sì máa ń ṣe ayẹyẹ náà. Lọ́nà kan náà, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún làwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi.

     Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló máa ń kóra jọ kárí ayé lọ́jọ́ tó bọ́ sí Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà òde òní, kí wọ́n lè rántí ikú Jésù.