Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 5:1-13

  • Ẹjọ́ ìṣekúṣe tó wáyé (1-5)

  • Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú (6-8)

  • Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò (9-13)

5  Ní tòótọ́, wọ́n ròyìn ìṣekúṣe*+ tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín, irú ìṣekúṣe* bẹ́ẹ̀ kò tiẹ̀ sí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé ọkùnrin kan ń fẹ́* ìyàwó bàbá rẹ̀.+  Ṣé ẹ wá ń fìyẹn yangàn ni? Ṣé kì í ṣe pé ó yẹ kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀+ kí a lè mú ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí kúrò láàárín yín?+  Bí mi ò tiẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa tara, mo wà lọ́dọ̀ yín nípa tẹ̀mí, mo sì ti ṣèdájọ́ ọkùnrin tó ṣe nǹkan yìí, bíi pé èmi fúnra mi wà lọ́dọ̀ yín.  Nígbà tí ẹ bá pé jọ ní orúkọ Olúwa wa Jésù, tí ẹ sì mọ̀ pé mo wà pẹ̀lú yín nípa tẹ̀mí nínú agbára Olúwa wa Jésù,  kí ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́+ kí agbára ẹ̀ṣẹ̀ náà lè pa run, kí ipò tẹ̀mí ìjọ lè wà láìyingin ní ọjọ́ Olúwa.+  Bí ẹ ṣe ń fọ́nnu yìí kò dáa. Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú ni?+  Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè di ìṣùpọ̀ tuntun, tí kò bá ti sí amóhunwú nínú yín. Torí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá wa+ rúbọ.+  Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe àjọyọ̀,+ kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, àmọ́ ká ṣe é pẹ̀lú búrẹ́dì aláìwú ti òótọ́ inú àti ti òtítọ́.  Nínú lẹ́tà tí mo kọ sí yín, mo ní kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́* pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe,* 10  àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn oníṣekúṣe* ayé yìí+ tàbí àwọn olójúkòkòrò tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà ni mò ń sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, á di pé kí ẹ kúrò nínú ayé.+ 11  Ṣùgbọ́n ní báyìí mò ń kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ nínú kíkẹ́gbẹ́*+ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, àmọ́ tó jẹ́ oníṣekúṣe* tàbí olójúkòkòrò+ tàbí abọ̀rìṣà tàbí pẹ̀gànpẹ̀gàn* tàbí ọ̀mùtípara+ tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà,+ kí ẹ má tiẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun. 12  Torí kí ló kàn mí pẹ̀lú ṣíṣèdájọ́ àwọn tó wà lóde? Ṣebí àwọn tó wà nínú ìjọ lẹ̀ ń dá lẹ́jọ́, 13  nígbà tí Ọlọ́run ń dá àwọn tó wà lóde lẹ́jọ́?+ “Ẹ mú ẹni burúkú náà kúrò láàárín yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ń gbé pẹ̀lú.”
Tàbí “dídarapọ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Tàbí “dídarapọ̀.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”