Jẹ́nẹ́sísì 3:1-24

  • Bí èèyàn ṣe kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ (1-13)

    • Irọ́ àkọ́kọ́ (4, 5)

  • Jèhófà dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ lẹ́jọ́ (14-24)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọmọ obìnrin náà (15)

    • Ọlọ́run lé Ádámù àti Éfà jáde ní Édẹ́nì (23, 24)

3  Nínú gbogbo ẹranko tí Jèhófà Ọlọ́run dá, ejò+ ló máa ń ṣọ́ra jù.* Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?”+  Ni obìnrin náà bá sọ fún ejò yẹn pé: “A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà.+  Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà+ pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.’”  Ejò yẹn wá sọ fún obìnrin náà pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú.+  Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.”+  Obìnrin náà wá rí i pé èso igi náà dára fún jíjẹ, ó dùn-ún wò, àní, igi náà wuni. Ló bá mú lára èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.+ Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ lára èso náà nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.+  Ni ojú àwọn méjèèjì bá là, wọ́n sì wá rí i pé ìhòòhò ni àwọn wà. Torí náà, wọ́n so ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì ṣe bàǹtẹ́ fún ara wọn.+  Lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run nígbà tó ń rìn nínú ọgbà ní àkókò tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́,* ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ sì lọ fara pa mọ́ sáàárín àwọn igi inú ọgbà, kí Jèhófà Ọlọ́run má bàa rí wọn.  Jèhófà Ọlọ́run sì ń pe ọkùnrin náà, ó ń sọ pé: “Ibo lo wà?” 10  Níkẹyìn, ọkùnrin náà fèsì pé: “Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú ọgbà, àmọ́ ẹ̀rù bà mí torí pé mo wà ní ìhòòhò, mo wá lọ fara pa mọ́.” 11  Ó sọ fún un pé: “Ta ló sọ fún ọ pé o wà ní ìhòòhò?+ Ṣé o jẹ èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé kí o má jẹ ni?”+ 12  Ọkùnrin náà sọ pé: “Obìnrin tí o fún mi pé kó wà pẹ̀lú mi ni, òun ló fún mi ní èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” 13  Ni Jèhófà Ọlọ́run bá sọ fún obìnrin náà pé: “Kí lo ṣe yìí?” Obìnrin náà fèsì pé: “Ejò ló tàn mí, tí mo fi jẹ ẹ́.”+ 14  Jèhófà Ọlọ́run wá sọ fún ejò+ náà pé: “Torí ohun tí o ṣe yìí, ègún ni fún ọ nínú gbogbo ẹran ọ̀sìn àti gbogbo ẹranko. Ikùn rẹ ni wàá máa fi wọ́, erùpẹ̀ ni wàá sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 15  Màá mú kí ìwọ+ àti obìnrin+ náà di ọ̀tá+ ara yín,* ọmọ* rẹ+ àti ọmọ* rẹ̀+ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ,*+ ìwọ yóò sì ṣe é léṣe* ní gìgísẹ̀.”+ 16  Ó sọ fún obìnrin náà pé: “Èmi yóò mú kí ìrora rẹ pọ̀ gan-an tí o bá lóyún; inú ìrora ni wàá ti máa bímọ, ọkàn rẹ á máa fà sí ọkọ rẹ, á sì máa jọba lé ọ lórí.” 17  Ó sọ fún Ádámù* pé: “Torí o fetí sí ìyàwó rẹ, tí o sì jẹ èso igi tí mo pàṣẹ+ fún ọ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ,’ ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ.+ Inú ìrora ni wàá ti máa jẹ èso rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.+ 18  Ẹ̀gún àti òṣùṣú ni yóò máa hù jáde fún ọ, ewéko ni wàá sì máa jẹ. 19  Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+ 20  Lẹ́yìn èyí, Ádámù sọ ìyàwó rẹ̀ ní Éfà,* torí òun ló máa di ìyá gbogbo èèyàn.*+ 21  Jèhófà Ọlọ́run sì fi awọ ṣe aṣọ gígùn fún Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n á máa wọ̀.+ 22  Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Ọkùnrin náà ti dà bí ọ̀kan lára wa, ó ti mọ rere àti búburú.+ Ní báyìí, kó má bàa na ọwọ́ rẹ̀, kó sì tún mú èso igi ìyè,+ kó jẹ ẹ́, kó sì wà láàyè títí láé,*—” 23  Ni Jèhófà Ọlọ́run bá lé e kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì  + kó lè máa ro ilẹ̀ tí a ti mú un jáde.+ 24  Torí náà, ó lé ọkùnrin náà jáde, ó sì fi àwọn kérúbù+ àti idà oníná tó ń yí láìdáwọ́ dúró sí ìlà oòrùn ọgbà Édẹ́nì, kí wọ́n lè máa ṣọ́ ọ̀nà tó lọ síbi igi ìyè náà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ló gbọ́n jù.”
Ní Héb., “àkókò tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ lóòjọ́.”
Tàbí “dọ́gbẹ́ sí i; fọ́ ọ.”
Tàbí “dọ́gbẹ́ sí ọ lórí; ṣe ọ́ lẹ́ṣe ní orí.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “kórìíra ara yín.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Fi Erùpẹ̀ Mọ; Èèyàn; Aráyé.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Wà Láàyè.”
Ní Héb., “gbogbo èèyàn tó wà láàyè.”
Tàbí “títí ayérayé.”