Jóòbù 2:1-13
2 Lẹ́yìn náà, nígbà tó di ọjọ́ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ ń wọlé láti dúró níwájú Jèhófà,+ Sátánì náà wọlé sáàárín wọn kó lè dúró níwájú Jèhófà.+
2 Jèhófà bi Sátánì pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Látinú ayé, mo lọ káàkiri, mo sì rìn káàkiri nínú rẹ̀.”+
3 Jèhófà sì bi Sátánì pé: “Ṣé o ti kíyè sí* Jóòbù ìránṣẹ́ mi? Kò sí ẹni tó dà bí rẹ̀ ní ayé. Olódodo àti olóòótọ́* èèyàn+ ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú. Kò fi ìwà títọ́ rẹ̀ sílẹ̀ rárá,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé o fẹ́ sún mi+ láti pa á run* láìnídìí.”
4 Àmọ́, Sátánì dá Jèhófà lóhùn pé: “Awọ dípò awọ. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀.
5 Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu egungun àti ara rẹ̀, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”+
6 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Ó wà ní ọwọ́ rẹ!* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí* rẹ̀!”
7 Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà, ó sì fi eéwo tó ń roni lára*+ kọ lu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.
8 Jóòbù wá mú àfọ́kù ìkòkò, ó sì fi ń họ ara rẹ̀, ó wá jókòó sínú eérú.+
9 Níkẹyìn, ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ṣé pé o ò tíì fi ìwà títọ́ rẹ sílẹ̀? Sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kí o sì kú!”
10 Àmọ́ Jóòbù sọ fún un pé: “Ò ń sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí kò nírònú. Tí a bá gba ohun rere lọ́wọ́ Ọlọ́run tòótọ́, ṣé kò yẹ ká tún gba ohun búburú?”+ Nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jóòbù kò fi ẹnu rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.+
11 Àwọn ọ̀rẹ́* Jóòbù mẹ́ta gbọ́ nípa gbogbo àjálù tó dé bá a, kálukú sì wá láti ibi tó ń gbé, Élífásì+ ará Témánì, Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì+ àti Sófárì+ ọmọ Náámà. Wọ́n ṣàdéhùn láti pàdé, kí wọ́n lè lọ bá Jóòbù kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú.
12 Nígbà tí wọ́n rí i lọ́ọ̀ọ́kán, wọn ò dá a mọ̀. Ni wọ́n bá bú sẹ́kún, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọ́n sì da iyẹ̀pẹ̀ sínú afẹ́fẹ́ àti sórí ara wọn.+
13 Wọ́n sì jókòó sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ fún ọ̀sán méje àti òru méje. Ẹnì kankan ò bá a sọ̀rọ̀, torí wọ́n rí i pé ìrora rẹ̀ pọ̀ gan-an.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.
^ Ní Héb., “fi ọkàn rẹ sí.”
^ Tàbí “Aláìlẹ́bi àti adúróṣinṣin.”
^ Ní Héb., “gbé e mì.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
^ Tàbí “ní ìkáwọ́ rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ní ojú.”
^ Tàbí “àwọn ọgbẹ́ tó le gan-an.”
^ Tàbí “ojúlùmọ̀.”