Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Báwo Ni Ẹbọ tí Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Rú Ṣe Jẹ́ “Ìràpadà fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”?

Báwo Ni Ẹbọ tí Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Rú Ṣe Jẹ́ “Ìràpadà fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ẹbọ tí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rú ni Ọlọ́run fi gba aráyé sílẹ̀ tàbí dá wọn nídè lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Bíbélì pe ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ìràpadà. (Éfésù 1:7; 1 Pétérù 1:18, 19) Torí náà, Jésù sọ pé òun wá “láti fi ẹ̀mí [òun] ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”​—Mátíù 20:28, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

Kí nìdí tí a fi nílò “ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn”?

 Ọlọ́run dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ní ẹni pípé tàbí láìní ẹ̀ṣẹ̀. Ó láǹfààní láti wà láàyè títí láé, àmọ́ àǹfààní yẹn bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ nígbà tó yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-​19) Nígbà tó bímọ, ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ran àwọn ọmọ náà. (Róòmù 5:12) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé Ádámù “ta” ara rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 7:14) Torí pé aláìpé sì ni gbogbo wọn, kò sí ìkankan nínú wọn tó lè ra ohun tí Ádámù gbé sọnù pa dà.​—Sáàmù 49:7, 8.

 Àánú àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ṣe Ọlọ́run torí wọn ò nírètí kankan. (Jòhánù 3:16) Àmọ́ torí pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run, kò kàn ní gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn tàbí kó kàn dárí jì wọ́n láìsí ìpìlẹ̀ kankan. (Sáàmù 89:14; Róòmù 3:23-​26) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aráyé, torí náà, ó pèsè ọ̀nà tó bófin mu tó máa jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kó sì tún pa á rẹ́. (Róòmù 5:6-8) Ìràpadà ni ọ̀nà tó bófin mu náà.

Iṣẹ́ wo ni ìràpadà náà ń ṣe?

 Nínú Bíbélì, ohun mẹ́ta yìí ni ọ̀rọ̀ náà, “ìràpadà” ní nínú:

  1.   Ó dà bí owó téèyàn san.​—Númérì 3:46, 47.

  2.   Ó máa ń túni sílẹ̀, tàbí rani pa dà.​—Ẹ́kísódù 21:30.

  3.   Ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí wọ́n fẹ́ rà pa dà, tàbí ká sọ pé ó bò ó. a

 Wo bí ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ṣe ṣe ohun mẹ́ta yìí.

  1.   Ó san iye kan. Bíbélì sọ pé ‘a ti ra àwọn Kristẹni ní iye kan.’ (1 Kọ́ríńtì 6:20; 7:23) Ẹ̀jẹ̀ Jésù ni iye yẹn, òun ló fi “ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.”​—Ìṣípayá 5:8, 9.

  2.   Ó pèsè ìtúsílẹ̀. Ẹbọ tí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rú pèsè “ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà” lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.​—1 Kọ́ríńtì 1:30; Kólósè 1:14; Hébérù 9:15.

  3.   Ó ṣe rẹ́gí. Torí pé Jésù jẹ́ ẹni pípé, ẹbọ tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rú ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí Ádámù gbé sọ nù. (1 Kọ́ríńtì 15:21, 22, 45, 46) Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan [ìyẹn Ádámù] ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan, [ìyẹn Jésù Kristi] ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” (Róòmù 5:19) Èyí ṣàlàyé bí ikú ẹnì kan ṣe lè ra ọ̀pọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ pa dà. Kódà, ẹbọ tí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rú jẹ́ “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn” tó bá ṣe àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n lè jàǹfààní látinú rẹ̀.—1 Tímótì 2:5, 6.

a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ìràpadà” máa ń tọ́ka sí iye kan tàbí ohun iyebíye kan tẹ́nì kan san. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù náà ka·pharʹ túmọ̀ sí “bò.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Ó sábà máa ń tọ́ka sí bíbo ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 65:3) Ọ̀rọ̀ míì tó jẹ mọ́ ọn ni koʹpher, ohun tíyẹn máa ń tọ́ka sí ni iye tí wọ́n san láti bo ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tàbí tú u sílẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:30) Bákan náà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà lyʹtron sábà máa ń túmọ̀ sí “ìràpadà,” wọ́n sì lè túmọ̀ rẹ̀ sí “owó ìtúsílẹ̀.” (Mátíù 20:28; Bíbélì The New Testament in Modern Speech, by R.  F.  Weymouth) Àwọn òǹkọ̀wé tó jẹ́ Gíríìkì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n bá ń tọ́ka sí owó tẹ́nì kan san kí wọ́n lè tú ẹrú sílẹ̀ tàbí ra ẹni tí wọ́n mú lẹ́rú nígbà ogun pa dà.