Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?

Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Tẹ́ni kan bá ṣe ohunkóhun tàbí tó ní èrò èyíkéyìí tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ẹ̀ṣẹ̀ lẹni yẹn dá. Èèyàn tún lè dẹ́ṣẹ̀ tó bá ń rú òfin Ọlọ́run, ìyẹn tó bá ń ṣe ohun tó burú tàbí ohun tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. (1 Jòhánù 3:4; 5:17) Ẹ̀ṣẹ̀ míì tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún sọ nípa rẹ̀ ni pé kéèyàn mọ ohun tó yẹ kó ṣe, àmọ́ kó má ṣe é, ìyẹn ni pé kéèyàn rí ohun tó tọ́, kó sì gbójú fò ó.​— Jákọ́bù 4:17.

 Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún ẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí kéèyàn “ṣi nǹkan” tàbí kó ju nǹkan, kí nǹkan ọ̀hún wá lọ tàsé. Bí àpẹẹrẹ, atamátàsé làwọn ọmọ ogun kan ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, wọ́n mọ bí wọ́n ṣe ń ju òkúta sí nǹkan “tí kò sì ní tàsé.” Tí a bá túmọ̀ gbólóhùn yẹn ní ṣáńgílítí sí èdè Yorùbá, ohun tó máa túmọ̀ sí ni “tí kò sì ní ṣẹ̀.” (Àwọn Onídàájọ́ 20:16) Torí náà, tí ẹnì kan bá ṣẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ẹni náà ti tàsé ìlànà Ọlọ́run.

 Ọlọ́run ló dá wa, torí náà ó lẹ́tọ̀ọ́ láti fún àwa èèyàn ní ìlànà tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe. (Ìṣípayá 4:11) Òun la máa jíhìn ohun tá a bá ṣe fún.​— Róòmù 14:12.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn máà dẹ́ṣẹ̀ rárá?

 Kò ṣeé ṣe. Bíbélì sọ pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23; 1 Àwọn Ọba 8:46; Oníwàásù 7:20; 1 Jòhánù 1:8) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

 Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, wọn ò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan lọ́rùn. Ìdí ni pé Ọlọ́run dá wọn ní pípé, ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Àmọ́, wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì di aláìpé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:5, 6, 17-​19) Nígbà tí wọ́n sì bímọ, àwọn ọmọ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé látọ̀dọ̀ wọn. (Róòmù 5:12) Ìyẹn ló jẹ́ kí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì sọ pé, “Pẹ̀lú ìṣìnà ni a bí mi nínú ìrora ìbímọ.”​—Sáàmù 51:5.

Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ máa burú ju ara wọn lọ?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin Sódómù ìgbàanì “burú, wọ́n sì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku,” ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì “rinlẹ̀ gidigidi.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:13; 18:20) Wo ohun mẹ́ta táá jẹ́ kó o mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ kan ṣe burú tó tàbí bó ṣe wúwo tó.

  1.   Bó ṣe burú tó. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé ká yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, irú bí ìṣekúṣe, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà, mímu ọtí para, ìlọ́nilọ́wọ́gbà, ìpànìyàn àti ìbẹ́mìílò. (1 Kọ́ríńtì 6:9-​11; Ìṣípayá 21:8) Bíbélì fi hàn pé irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí yàtọ̀ sí èyí téèyàn ò mọ̀ọ́mọ̀ dá tàbí èyí tó dá torí pé kò ronú jinlẹ̀, bí àpẹẹrẹ, kéèyàn sọ ohun tó bí ẹlòmíì nínú tàbí kó ṣe ohun tó dun ẹni náà gan-an. (Òwe 12:18; Éfésù 4:31, 32) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká má fojú kéré ẹ̀ṣẹ̀ kankan, torí pé ẹ̀ṣẹ̀ tí ò tó nǹkan lójú ẹni lè di ńlá, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, èèyàn lè ṣe ohun tó burú jáì, kó sì rú òfin Ọlọ́run.​— Mátíù 5:27, 28.

  2.   Ohun tó mú kéèyàn dẹ́ṣẹ̀. Èèyàn lè dẹ́ṣẹ̀ torí pé kò mọ bí ohun tí òun ṣe ṣe rí lójú Ọlọ́run. (Ìṣe 17:30; 1 Tímótì 1:13) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò gbójú fo irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó fìyàtọ̀ sírú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn àti èyí téèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá, tó sì rú òfin Ọlọ́run. (Númérì 15:30, 31) Torí náà, “ọkàn-àyà búburú” ló ń mú kéèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀.​—Jeremáyà 16:12.

  3.   Béèyàn ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ tó. Bíbélì tún fìyàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ téèyàn dá lẹ́ẹ̀kan péré àti ẹ̀ṣẹ̀ tó ti pẹ́ tẹ́ni kan ti ń dá bọ̀, tó sì ti wá dàṣà. (1 Jòhánù 3:4-8) Ọlọ́run ò ní ṣojúure sí àwọn tó ti mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe ohun tó tọ́ àmọ́ tí wọ́n ṣì “mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà,” yóò sì dá wọn lẹ́jọ́.​—Hébérù 10:26, 27.

 Ìdààmú lè bá àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, torí bí àṣìṣe wọn ṣe wúwo tó. Bí àpẹẹrẹ, Ọba Dáfídì sọ pé: “Àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá; bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi.” (Sáàmù 38:4) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká nírètí, ó ní: “Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”​—Aísáyà 55:7.