Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jòhánù 3:16​—“Torí Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Ayé Gan-an”

Jòhánù 3:16​—“Torí Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Ayé Gan-an”

 “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòhánù 3:16, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.”​—Jòhánù 3:​16, Bibeli Mimọ.

Ìtumọ̀ Jòhánù 3:16

 Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká wà láàyè títí láé. Torí náà, ó rán Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ wá sáyé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ṣe nígbà tó wà láyé. Lára ẹ̀ ni pé ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀. (1 Pétérù 1:3) Ó tún fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún gbogbo èèyàn. Torí náà, tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Jésù.

 Gbólóhùn náà, “ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo a fúnni” jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe jinlẹ̀ tó. Jésù dá yàtọ̀ nínú gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Jésù nìkan ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ara rẹ̀ dá. (Kólósè 1:17) Òun ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá tó kù, títí kan àwọn áńgẹ́lì, ni a dá nípasẹ̀ Jésù. Síbẹ̀, Jèhófà b Ọlọ́run fínnúfíndọ̀ rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n yìí wá sáyé “kó lè ṣe ìránṣẹ́, kó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28) Jésù jìyà, ó sì kú, kó lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù.​—Róòmù 5:8, 12.

 Kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jésù kọjá kónítọ̀hún kàn gbà pé Jésù wà, tàbí kó gbà pé ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Mátíù 7:24-27; 1 Pétérù 2:21) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè.”​—Jòhánù 3:36.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jòhánù 3:16

 Ìgbà tí Jésù ń bá aṣáájú ẹ̀sìn Júù kan tó ń jẹ́ Nikodémù sọ̀rọ̀ ló sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. (Jòhánù 3:1, 2) Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, Jésù sọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run c túmọ̀ sí, ó sì sọ ohun tó túmọ̀ sí pé ká ‘tún ẹnì kan bí.’ (Jòhánù 3:3) Ó tún sọ bí wọ́n ṣe máa pa òun, ó ní: “A gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè [tàbí, ká gbé e kọ́ sórí igi], kí gbogbo ẹni tó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:​14, 15) Ó wá tẹnu mọ́ ọn pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwa èèyàn ló jẹ́ kó fún wa láǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé kẹ́nì kan tó lè ní ìyè yìí, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́, kó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn.​—Jòhánù 3:17-21.

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “kan ṣoṣo” ni monogenes. Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, . . . èyí tí ò sírú ẹ̀, ohun tí ò láfiwé.”​—A Greek-English Lexicon of the New Testament and Other Early Christian Literature, ojú ìwé 658.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.

c Ìjọba Ọlọ́run yìí, tá a tún ń pè ní “Ìjọba ọ̀run,” jẹ́ ìṣàkóso kan láti ọ̀run. (Mátíù 10:7; Ìfihàn 11:15) Kristi ni Ọlọ́run fi ṣe Ọba Ìjọba náà. Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?