Sí Àwọn Hébérù 2:1-18

  • Ká túbọ̀ máa fiyè sí àwọn ohun tí a gbọ́ (1-4)

  • A fi ohun gbogbo sábẹ́ Jésù (5-9)

  • Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ (10-18)

    • Olórí Aṣojú ìgbàlà wọn (10)

    • Àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú (17)

2  Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká túbọ̀ máa fiyè sí àwọn ohun tí a gbọ́,+ ká má bàa sú lọ láé.+  Torí tí ọ̀rọ̀ tí a gbẹnu àwọn áńgẹ́lì sọ+ bá dájú, tí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà àìgbọràn bá sì gba ìyà tó tọ́,+  báwo la ṣe máa bọ́ tí a ò bá ka irú ìgbàlà tó tóbi bẹ́ẹ̀ sí?  + Torí Olúwa wa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀,+ àwọn tó gbọ́ ọ lẹ́nu rẹ̀ sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa,  nígbà tí Ọlọ́run náà jẹ́rìí sí i pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu* àti oríṣiríṣi iṣẹ́ agbára,+ tó sì pín ẹ̀mí mímọ́ bó ṣe fẹ́.+  Nítorí kò fi ayé tó ń bọ̀ tí à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ sí ìkáwọ́ àwọn áńgẹ́lì.+  Àmọ́ ibì kan wà tí ẹlẹ́rìí kan ti sọ pé: “Kí ni èèyàn jẹ́ tí o fi ń fi í sọ́kàn tàbí ọmọ aráyé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+  O mú kí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì; o fi ògo àti ọlá dé e ládé, o sì yàn án ṣe olórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.  O fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Bí Ọlọ́run ṣe fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kò sí ohun tí kò fi sábẹ́ rẹ̀.+ Àmọ́, ní báyìí, a ò tíì rí ohun gbogbo lábẹ́ rẹ̀.+  Àmọ́ a rí Jésù, ẹni tí a mú kó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì lọ,+ a ti fi ògo àti ọlá dé e ládé báyìí torí ó jìyà títí ó fi kú,+ kó lè tọ́ ikú wò fún gbogbo èèyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.+ 10  Torí ó yẹ kí ẹni tí ohun gbogbo torí rẹ̀ wà, tí ohun gbogbo sì tipasẹ̀ rẹ̀ wà, bí o ti ń mú ọ̀pọ̀ ọmọ wá sínú ògo,+ sọ Olórí Aṣojú ìgbàlà+ wọn di pípé nípasẹ̀ ìjìyà.+ 11  Torí ọ̀dọ̀ ẹnì kan ni ẹni tó ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí à ń sọ di mímọ́+ ti wá,+ torí èyí ni ojú ò ṣe tì í láti pè wọ́n ní arákùnrin,+ 12  bó ṣe sọ pé: “Màá sọ orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; màá sì fi orin yìn ọ́ láàárín ìjọ.”+ 13  Ó tún sọ pé: “Màá gbẹ́kẹ̀ lé e.”+ Àti pé: “Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ kéékèèké tí Jèhófà* fún mi.”+ 14  Nítorí náà, torí pé “àwọn ọmọ kéékèèké” ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, òun náà wá ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara,+ kó lè tipasẹ̀ ikú rẹ̀ pa ẹni tó lè fa ikú run,+ ìyẹn Èṣù,+ 15  kó sì lè dá àwọn tí ìbẹ̀rù ikú ti mú lẹ́rú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn sílẹ̀.*+ 16  Torí kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì ló ń ràn lọ́wọ́, àmọ́ ọmọ* Ábúráhámù ló ń ràn lọ́wọ́.+ 17  Bákan náà, ó ní láti dà bí “àwọn arákùnrin” rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà,+ kó lè di àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run, kó lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn.+ 18  Torí pé òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a dán an wò,+ ó lè ran àwọn tí à ń dán wò lọ́wọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn àmì.”
Tàbí “sọ àwọn tí ìbẹ̀rù ikú ti mú lẹ́rú di òmìnira.”
Ní Grk., “èso.”
Tàbí “ṣe ètùtù; rú ẹbọ láti pẹ̀tù.”