Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 3:1-23

  • Àwọn ará Kọ́ríńtì ṣì jẹ́ ẹni tara (1-4)

  • Ọlọ́run ń mú kó dàgbà (5-9)

    • Alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run (9)

  • Fi ohun tí kò lè jóná kọ́lé (10-15)

  • Ẹ̀yin ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run (16, 17)

  • Ọgbọ́n ayé jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run (18-23)

3  Nítorí náà, ẹ̀yin ará, mi ò lè bá yín sọ̀rọ̀ bí ẹní ń bá àwọn ẹni tẹ̀mí sọ̀rọ̀,+ àmọ́ bí ẹní ń bá àwọn ẹni ti ara sọ̀rọ̀, bí ẹní ń bá àwọn ìkókó+ nínú Kristi sọ̀rọ̀.  Wàrà ni mo fi bọ́ yín, kì í ṣe oúnjẹ líle, torí nígbà yẹn, ẹ ò tíì lágbára tó. Kódà ní báyìí, ẹ ò tíì lágbára tó,+  nítorí ẹ ṣì jẹ́ ẹni ti ara.+ Nígbà tí owú àti wàhálà wà láàárín yín, ṣé ẹ kì í ṣe ẹni ti ara ni,+ ṣé ẹ kì í sì í ṣe bí àwọn èèyàn ayé ni?  Torí nígbà tí ẹnì kan bá sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,” tí òmíràn sì sọ pé, “Èmi jẹ́ ti Àpólò,”+ ṣé kì í ṣe ìwà àwọn èèyàn ayé lẹ̀ ń hù yẹn?  Kí wá ni Àpólò jẹ́? Kí sì ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn òjíṣẹ́+ tí ẹ tipasẹ̀ wọn di onígbàgbọ́, bí Olúwa ṣe fún kálukú láǹfààní.  Èmi gbìn,+ Àpólò bomi rin,+ àmọ́ Ọlọ́run ló mú kó máa dàgbà,  tó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tó ń gbìn ló ṣe pàtàkì tàbí ẹni tó ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tó ń mú kó dàgbà.+  Ní báyìí, ọ̀kan náà ni ẹni tó ń gbìn àti ẹni tó ń bomi rin jẹ́,* àmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀.+  Nítorí alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni wá. Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí à ń ro lọ́wọ́, ilé Ọlọ́run.+ 10  Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fún mi, mo fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá kọ́lékọ́lé tó mọṣẹ́,* àmọ́ ẹlòmíì ń kọ́lé sórí rẹ̀. Kí kálukú máa ṣọ́ bó ṣe ń kọ́lé sórí rẹ̀. 11  Nítorí kò sí ẹni tó lè fi ìpìlẹ̀ èyíkéyìí míì lélẹ̀ ju ohun tí a ti fi lélẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi.+ 12  Ní báyìí, tí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye, igi, koríko gbígbẹ tàbí pòròpórò sórí ìpìlẹ̀ náà, 13  ohun tí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ á hàn,* torí ọjọ́ náà yóò tú u síta, nítorí iná yóò fi í hàn,+ iná náà yóò sì fi ohun tí kálukú fi kọ́lé hàn. 14  Bí ohun tí ẹnì kan kọ́ sórí rẹ̀ bá dúró, ẹni náà yóò gba èrè; 15  bí iṣẹ́ ẹnì kan bá jóná, ẹni náà yóò pàdánù, àmọ́ a ó gba òun fúnra rẹ̀ là; síbẹ̀, tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dà bí ìgbà téèyàn la iná kọjá. 16  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run+ àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín?+ 17  Tí ẹnikẹ́ni bá pa tẹ́ńpìlì Ọlọ́run run, Ọlọ́run á pa ẹni náà run; nítorí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin sì ni tẹ́ńpìlì yẹn.+ 18  Kí ẹnì kankan má tan ara rẹ̀ jẹ: Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá rò pé òun gbọ́n nínú ètò àwọn nǹkan yìí,* kí ó di òmùgọ̀, kí ó lè gbọ́n. 19  Nítorí ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, torí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn.”+ 20  Àti pé: “Jèhófà* mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.”+ 21  Torí náà, kí ẹnì kankan má ṣe máa fi èèyàn yangàn; nítorí ohun gbogbo jẹ́ tiyín, 22  ì báà jẹ́ Pọ́ọ̀lù tàbí Àpólò tàbí Kéfà*+ tàbí ayé tàbí ìyè tàbí ikú tàbí àwọn ohun tó wà níbí nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀, ohun gbogbo jẹ́ tiyín; 23  ẹ̀yin náà jẹ́ ti Kristi;+ Kristi ní tirẹ̀ jẹ́ ti Ọlọ́run.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “èrò kan náà ni ẹni tó ń gbìn àti ẹni tó ń bomi rin ní.”
Tàbí “ọlọ́gbọ́n olùdarí àwọn iṣẹ́.”
Ní Grk., “fara hàn kedere.”
Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.