Àìsáyà 45:1-25

  • Ọlọ́run yan Kírúsì pé kó ṣẹ́gun Bábílónì (1-8)

  • Amọ̀ ò lè bá Amọ̀kòkò fà á (9-13)

  • Àwọn orílẹ̀-èdè míì mọ Ísírẹ́lì (14-17)

  • Ọlọ́run ṣeé gbára lé lórí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀dá àti ṣíṣí nǹkan payá (18-25)

    • Ó dá ayé ká lè máa gbé inú rẹ̀ (18)

45  Ohun tí Jèhófà sọ fún ẹni tó yàn nìyí, fún Kírúsì,+Ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú,+Láti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba níwájú rẹ̀,+Láti gba ohun ìjà* àwọn ọba,Láti ṣí àwọn ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì níwájú rẹ̀,Kí wọ́n má sì ti àwọn ẹnubodè:   “Màá lọ níwájú rẹ,+Màá sì mú kí àwọn òkè di ilẹ̀ tó tẹ́jú. Màá fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà sí wẹ́wẹ́,Màá sì gé àwọn ọ̀pá irin lulẹ̀.+   Màá fún ọ ní àwọn ìṣúra tó wà nínú òkùnkùnÀti àwọn ìṣúra tó pa mọ́ láwọn ibi tí kò hàn síta,+Kí o lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń fi orúkọ rẹ pè ọ́.+   Torí ìránṣẹ́ mi Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì àyànfẹ́ mi,Màá fi orúkọ rẹ pè ọ́. Màá fún ọ ní orúkọ tó lọ́lá, bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí.   Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì. Kò sí Ọlọ́run kankan yàtọ̀ sí mi.+ Màá fún ọ lókun,* bó ò tiẹ̀ mọ̀ mí,   Kí àwọn èèyàn lè mọ̀,Láti ibi tí oòrùn ti ń yọ, dé ibi tó ti ń wọ̀*Pé kò sí ẹnì kankan yàtọ̀ sí mi.+ Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì.+   Mo dá ìmọ́lẹ̀,+ mo sì ṣe òkùnkùn,+Mo dá àlàáfíà,+ mo sì ṣe àjálù;+Èmi Jèhófà ni mò ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.   Ẹ̀yin ọ̀run, ẹ rọ òjò sílẹ̀ látòkè;+Kí ojú ọ̀run rọ òdodo sílẹ̀. Kí ilẹ̀ lanu, kó sì so èso ìgbàlà,Kó mú kí òdodo rú yọ lẹ́ẹ̀kan náà.+ Èmi Jèhófà ti dá a.”   Ó mà ṣe fún ẹni tó ń bá Aṣẹ̀dá rẹ̀* fa nǹkan* o,Torí ó dà bí àfọ́kù ìkòkò lásánLáàárín àwọn àfọ́kù ìkòkò míì tó wà nílẹ̀! Ṣé ó yẹ kí amọ̀ sọ fún Amọ̀kòkò* pé: “Kí lò ń mọ?”+ Àbí ó yẹ kí iṣẹ́ rẹ sọ pé: “Kò ní ọwọ́”?* 10  Ó mà ṣe o, fún ẹni tó ń sọ fún bàbá pé: “Kí lo bí?”Àti fún obìnrin pé: “Kí lo fẹ́ bí?”* 11  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+ Ẹni tó dá a: “Ṣé o máa bi mí nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ ni,Kí o sì pàṣẹ fún mi nípa àwọn ọmọ mi+ àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi? 12  Mo dá ayé,+ mo sì dá èèyàn sórí rẹ̀.+ Ọwọ́ ara mi ni mo fi na ọ̀run,+Mo sì ń pàṣẹ fún gbogbo ọmọ ogun wọn.”+ 13  “Mo ti gbé ẹnì kan dìde nínú òdodo,+Màá sì mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Òun ló máa kọ́ ìlú mi,+Tó sì máa dá àwọn ìgbèkùn mi sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ + tàbí láìgba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 14  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Èrè* Íjíbítì àti ọjà* Etiópíà àtàwọn Sábéà, àwọn tó ga,Máa wá bá ọ, wọ́n á sì di tìrẹ. Wọ́n á máa rìn lẹ́yìn rẹ, pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè wọ́n,Wọ́n á wá bá ọ, wọ́n á sì tẹrí ba fún ọ.+ Wọ́n á gbàdúrà, wọ́n á sọ fún ọ pé, ‘Ó dájú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ,+Kò sì sí ẹlòmíì; kò sí Ọlọ́run míì.’” 15  Lóòótọ́, Ọlọ́run tó ń fi ara rẹ̀ pa mọ́ ni ọ́,Ìwọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Olùgbàlà.+ 16  Ojú máa ti gbogbo wọn, wọ́n sì máa tẹ́;Ìtìjú ni gbogbo àwọn tó ń ṣe ère máa bá kúrò.+ 17  Àmọ́ Jèhófà máa gba Ísírẹ́lì là, ìgbàlà náà sì máa jẹ́ títí láé.+ Ojú ò ní tì yín, ìtìjú ò sì ní bá yín títí ayé.+ 18  Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí,Ẹlẹ́dàá ọ̀run,+ Ọlọ́run tòótọ́,Ẹni tó dá ayé, Aṣẹ̀dá rẹ̀ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+Ẹni tí kò kàn dá a lásán,* àmọ́ tó dá a ká lè máa gbé inú rẹ̀:+ “Èmi ni Jèhófà, kò sí ẹlòmíì. 19  Mi ò sọ̀rọ̀ ní ibi tó pa mọ́,+ ní ilẹ̀ tó ṣókùnkùn;Mi ò sọ fún ọmọ* Jékọ́bù pé,‘Ẹ kàn máa wá mi lásán.’* Èmi ni Jèhófà, tó ń sọ ohun tó jẹ́ òdodo, tó sì ń kéde ohun tó tọ́.+ 20  Ẹ kóra jọ, kí ẹ sì wá. Ẹ jọ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin tí ẹ yè bọ́ látinú àwọn orílẹ̀-èdè.+ Wọn ò mọ nǹkan kan, àwọn tó ń gbé ère gbígbẹ́ kiri,Tí wọ́n sì ń gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbà wọ́n.+ 21  Ẹ sọ tẹnu yín, ẹ ro ẹjọ́ yín. Kí wọ́n fikùn lukùn ní ìṣọ̀kan. Ta ló ti sọ èyí tipẹ́tipẹ́,Tó sì kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́? Ṣebí èmi, Jèhófà ni? Kò sí Ọlọ́run míì, àfi èmi;Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà,+ kò sí ẹlòmíì yàtọ̀ sí mi.+ 22  Ẹ yíjú sí mi, kí ẹ sì rí ìgbàlà,+ gbogbo ìkángun ayé. Torí èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíì.+ 23  Mo ti fi ara mi búra;Ọ̀rọ̀ ti jáde lẹ́nu mi nínú òdodo,Kò sì ní pa dà:+ Gbogbo eékún máa tẹ̀ ba fún mi,Gbogbo ahọ́n máa búra láti dúró ṣinṣin,+ 24  Wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé inú Jèhófà ni òdodo tòótọ́ àti okun wà. Gbogbo àwọn tó ń bínú sí i máa fi ìtìjú wá síwájú rẹ̀. 25  Gbogbo ọmọ* Ísírẹ́lì máa fi hàn pé àwọn ṣe ohun tó tọ́ nínú Jèhófà,+Òun ni wọ́n á sì máa fi yangàn.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “tú àmùrè ìbàdí.”
Ní Héb., “dì ọ́ lámùrè gírígírí.”
Tàbí “Láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”
Tàbí “Ẹni tó dá a.”
Tàbí “bá Aṣẹ̀dá rẹ̀ jiyàn.”
Tàbí “Ẹni tó mọ ọ́n.”
Tàbí kó jẹ́, “Àbí ó yẹ kí amọ̀ sọ pé: ‘Iṣẹ́ rẹ ò ní ọwọ́’?”
Tàbí “Kí lò ń rọbí rẹ̀?”
Tàbí kó jẹ́, “Àwọn alágbàṣe.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn oníṣòwò.”
Tàbí kó jẹ́, “dá a pé kó ṣófo.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “wá mi lórí òfo.”
Ní Héb., “èso.”