Àìsáyà 33:1-24

  • Ìdájọ́ àti ìrètí fún àwọn olódodo (1-24)

    • Jèhófà ni Onídàájọ́, Afúnnilófin àti Ọba (22)

    • Kò sẹ́ni tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá” (24)

33  O gbé, ìwọ apanirun tí wọn ò tíì pa run;+Ìwọ ọ̀dàlẹ̀ tí wọn ò tíì dalẹ̀ rẹ̀! Tí o bá pani run tán, wọ́n á pa ìwọ náà run.+ Tí o bá dalẹ̀ tán, wọ́n á dalẹ̀ ìwọ náà.   Jèhófà, ṣojúure sí wa.+ Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé. Di apá* wa+ ní àràárọ̀,Àní, ìgbàlà wa ní àkókò wàhálà.+   Tí àwọn èèyàn bá gbọ́ ìro ìdàrúdàpọ̀, wọ́n á sá lọ. Tí o bá dìde, àwọn orílẹ̀-èdè á fọ́n ká.+   Bí ọ̀yànnú eéṣú ṣe ń kóra jọ la máa kó àwọn ẹrù ogun rẹ jọ;Àwọn èèyàn máa rọ́ bò ó bí ọ̀wọ́ eéṣú.   A máa gbé Jèhófà ga,Torí ó ń gbé ibi gíga lókè. Ó máa fi ìdájọ́ tí ó tọ́ àti òdodo kún Síónì.   Òun ló ń mú kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ láwọn àkókò rẹ;Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìgbàlà,+ ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà,+Èyí ni ohun iyebíye rẹ̀.   Wò ó! Àwọn akọni wọn ń ké jáde lójú ọ̀nà;Àwọn ìránṣẹ́ àlàáfíà ń sunkún gidigidi.   Àwọn ojú pópó dá páropáro;Ẹnì kankan ò gba àwọn ojú ọ̀nà kọjá. Ó* ti da májẹ̀mú;Ó ti kọ àwọn ìlú náà sílẹ̀;Kò ka ẹni kíkú sí.+   Ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀,* kò sì lọ́ràá mọ́. Ojú ti Lẹ́bánónì;+ ó ti jẹrà. Ṣárónì ti dà bí aṣálẹ̀,Báṣánì àti Kámẹ́lì sì gbọn ewé wọn dà nù.+ 10  “Ní báyìí, màá dìde,” ni Jèhófà wí,“Ní báyìí, màá gbé ara mi ga;+Ní báyìí, màá ṣe ara mi lógo. 11  Ẹ lóyún koríko gbígbẹ, ẹ sì bí àgékù pòròpórò. Ẹ̀mí yín máa jẹ yín run bí iná.+ 12  Àwọn èèyàn sì máa dà bí ẹfun tó jóná. Wọ́n máa dáná sun wọ́n bí ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀.+ 13  Ẹ̀yin tí ẹ wà níbi tó jìnnà, ẹ gbọ́ ohun tí màá ṣe! Ẹ̀yin tí ẹ sì wà nítòsí, ẹ mọ agbára mi! 14  Jìnnìjìnnì ti bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Síónì;+Àwọn apẹ̀yìndà ń gbọ̀n rìrì: ‘Èwo nínú wa ló lè gbé níbi tí iná tó ń jẹni run wà?+ Èwo nínú wa ló lè bá ọwọ́ iná tí kò ṣeé pa gbé?’ 15  Ẹni tí kò jáwọ́ nínú ṣíṣe òdodo,+Tó ń sọ ohun tó tọ́,+Tó kọ àìṣòótọ́ àti èrè jìbìtì,Tí ọwọ́ rẹ̀ kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ dípò kó gbà á,+Tó ń di etí rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀,Tó sì ń di ojú rẹ̀ kó má bàa rí ohun tó burú 16  —Ó máa gbé ní àwọn ibi gíga;Ibi ààbò rẹ̀* máa wà níbi àwọn àpáta tó láàbò,Á máa rí oúnjẹ jẹ,Omi ò sì ní wọ́n ọn láé.”+ 17  Ojú rẹ máa rí ọba kan nínú ẹwà rẹ̀;Wọ́n máa rí ilẹ̀ kan tó jìnnà réré. 18  O máa rántí* ìbẹ̀rù náà nínú ọkàn rẹ: “Ibo ni akọ̀wé wà? Ibo ni ẹni tó wọn ìṣákọ́lẹ̀* wà?+ Ibo ni ẹni tó ka àwọn ilé gogoro wà?” 19  O ò ní rí àwọn aláfojúdi èèyàn mọ́,Àwọn èèyàn tí èdè wọn ṣòroó lóye* gan-an,Tí ahọ́n wọn tó ń kólòlò kò lè yé ọ.+ 20  Wo Síónì, ìlú àwọn àjọyọ̀ wa!+ Ojú rẹ máa rí Jerúsálẹ́mù bí ibùgbé tó pa rọ́rọ́,Àgọ́ tí wọn ò ní kó kúrò.+ Wọn ò ní fa àwọn èèkàn àgọ́ rẹ̀ yọ láé,Wọn ò sì ní já ìkankan nínú àwọn okùn rẹ̀. 21  Àmọ́ níbẹ̀, Jèhófà, Ọba Ọlọ́lá,Máa jẹ́ agbègbè odò fún wa, èyí tó ní àwọn ipadò tó fẹ̀,Tí ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun kankan kò ní lọ síbẹ̀,Tí ọkọ̀ òkun ńlá kankan kò sì ní gba ibẹ̀ kọjá. 22  Torí Jèhófà ni Onídàájọ́ wa,+Jèhófà ni Afúnnilófin wa,+Jèhófà ni Ọba wa;+Òun ni Ẹni tó máa gbà wá.+ 23  Àwọn okùn rẹ máa rọ̀ dirodiro;Wọn ò lè gbé òpó dúró, wọn ò sì lè ta ìgbòkun. Nígbà yẹn, wọ́n máa pín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹrù ogun;Arọ pàápàá máa kó ẹrù ogun púpọ̀.+ 24  Kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀* tó máa sọ pé: “Ara mi ò yá.”+ A ti máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn tó ń gbé ilẹ̀ náà jì wọ́n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “agbára.”
Ọ̀tá ló ń tọ́ka sí.
Tàbí kó jẹ́, “gbẹ dà nù.”
Tàbí “Ibi gíga rẹ̀ tó láàbò.”
Tàbí “ṣàṣàrò nípa.”
Tàbí “owó òde.”
Ní Héb., “jinlẹ̀.”
Tàbí “olùgbé kankan.”