Àìsáyà 35:1-10

  • Ayé pa dà di Párádísè (1-7)

    • Afọ́jú máa ríran; adití máa gbọ́ràn (5)

  • Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́ fún àwọn tí a tún rà (8-10)

35  Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀,+Aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.+   Ó dájú pé ó máa yọ ìtànná;+Ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa kígbe ayọ̀. A máa fún un ní ògo Lẹ́bánónì,+Ẹwà Kámẹ́lì+ àti ti Ṣárónì.+ Wọ́n máa rí ògo Jèhófà, ẹwà Ọlọ́run wa.   Ẹ fún àwọn ọwọ́ tí kò lágbára lókun,Ẹ sì mú kí àwọn orúnkún tó ń gbọ̀n dúró gbọn-in.+   Ẹ sọ fún àwọn tó ń ṣàníyàn nínú ọkàn wọn pé: “Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín máa wá gbẹ̀san,Ọlọ́run máa wá láti fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni.+ Ó máa wá gbà yín sílẹ̀.”+   Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú máa là,+Etí àwọn adití sì máa ṣí.+   Ní àkókò yẹn, ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín,+Ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì máa kígbe ayọ̀.+ Torí omi máa tú jáde ní aginjù,Odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.   Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,Ilẹ̀ gbígbẹ sì máa di ìsun omi.+ Koríko tútù, esùsú àti òrépètéMáa wà ní ibùgbé tí àwọn ajáko* ti ń sinmi.+   Ọ̀nà kan sì máa wà níbẹ̀,+Àní, ọ̀nà tí à ń pè ní Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́. Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.+ Àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ló wà fún;Òmùgọ̀ kankan ò sì ní rìn gbéregbère lọ síbẹ̀.   Kò ní sí kìnnìún kankan níbẹ̀,Ẹranko ẹhànnà kankan kò sì ní wá sórí rẹ̀. A ò ní rí wọn níbẹ̀;+Àwọn tí a tún rà nìkan ló máa gba ibẹ̀.+ 10  Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà wá,+ wọ́n sì máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì.+ Ayọ̀ tí kò lópin máa dé orí wọn ládé.+ Wọ́n á máa yọ̀ gidigidi, inú wọn á sì máa dùn,Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, koríko etí omi.
Tàbí “akátá.”