Àkọsílẹ̀ Mátíù 2:1-23

  • Àwọn awòràwọ̀ wá (1-12)

  • Wọ́n sá lọ sí Íjíbítì (13-15)

  • Hẹ́rọ́dù pa àwọn ọmọdékùnrin (16-18)

  • Wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì (19-23)

2  Lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Ọba Hẹ́rọ́dù,*+ wò ó! àwọn awòràwọ̀* wá sí Jerúsálẹ́mù láti Ìlà Oòrùn,  wọ́n sọ pé: “Ibo ni ọba àwọn Júù tí wọ́n bí wà?+ Torí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní Ìlà Oòrùn, a sì ti wá ká lè forí balẹ̀* fún un.”  Nígbà tí Ọba Hẹ́rọ́dù gbọ́ èyí, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀, òun àti gbogbo Jerúsálẹ́mù.  Ó kó gbogbo àwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin àwọn èèyàn náà jọ, ó sì wádìí ibi tí wọ́n á ti bí Kristi* lọ́wọ́ wọn.  Wọ́n sọ fún un pé: “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà ni, torí bí a ṣe kọ ọ́ nípasẹ̀ wòlíì nìyí:  ‘Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti ilẹ̀ Júdà, lọ́nàkọnà, ìwọ kọ́ ni ìlú tó rẹlẹ̀ jù lára àwọn gómìnà Júdà, torí inú rẹ ni alákòóso ti máa jáde wá, ẹni tó máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’”+  Hẹ́rọ́dù wá ránṣẹ́ pe àwọn awòràwọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́, ó sì fara balẹ̀ wádìí àkókò tí ìràwọ̀ náà fara hàn lọ́wọ́ wọn.  Nígbà tó ń rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sọ pé: “Ẹ lọ fara balẹ̀ wá ọmọ kékeré náà, tí ẹ bá sì ti rí i, ẹ pa dà wá jábọ̀ fún mi, kí èmi náà lè lọ forí balẹ̀ fún un.”  Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ohun tí ọba sọ, wọ́n lọ, sì wò ó! ìràwọ̀ tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n wà ní Ìlà Oòrùn+ ń lọ níwájú wọn, títí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré náà wà. 10  Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, inú wọn dùn gidigidi. 11  Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wá wólẹ̀, wọ́n sì forí balẹ̀* fún un. Wọ́n tún ṣí àwọn ìṣúra wọn, wọ́n sì fún un lẹ́bùn, ìyẹn wúrà, oje igi tùràrí àti òjíá. 12  Àmọ́ torí pé wọ́n ti gba ìkìlọ̀ láti ọ̀run lójú àlá+ pé kí wọ́n má pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, wọ́n gba ọ̀nà míì lọ sí ilẹ̀ wọn. 13  Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara han Jósẹ́fù lójú àlá,+ ó sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o dúró síbẹ̀ títí màá fi bá ọ sọ̀rọ̀, torí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà kiri kó lè pa á.” 14  Jósẹ́fù bá dìde, ó mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Íjíbítì. 15  Ó dúró síbẹ̀ títí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí mú ohun tí Jèhófà* sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ, pé: “Láti Íjíbítì ni mo ti pe ọmọkùnrin mi.”+ 16  Nígbà tí Hẹ́rọ́dù rí i pé àwọn awòràwọ̀ náà ti já ọgbọ́n òun, inú bí i gidigidi, ó ránṣẹ́, ó sì ní kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo agbègbè rẹ̀, láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkókò tó fara balẹ̀ wádìí lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ náà.+ 17  Ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà wá ṣẹ, pé: 18  “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà, ẹkún àti ìpohùnréré ẹkún púpọ̀. Réṣẹ́lì+ ló ń sunkún torí àwọn ọmọ rẹ̀, kò sì fẹ́ kí wọ́n tu òun nínú, torí pé wọn kò sí mọ́.”+ 19  Lẹ́yìn tí Hẹ́rọ́dù kú, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà* fara han Jósẹ́fù lójú àlá+ ní Íjíbítì, 20  ó sì sọ pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, torí àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí* ọmọ kékeré náà ti kú.” 21  Torí náà, ó dìde, ó mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, ó sì lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 22  Àmọ́ nígbà tó gbọ́ pé Ákíláọ́sì ló ń ṣàkóso ní Jùdíà ní ipò Hẹ́rọ́dù bàbá rẹ̀, ẹ̀rù bà á láti lọ síbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, torí a kìlọ̀ fún un láti ọ̀run lójú àlá,+ ó kúrò níbẹ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ Gálílì.+ 23  Ó wá lọ ń gbé ní ìlú kan tí à ń pè ní Násárẹ́tì,+ kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì lè ṣẹ, pé: “A máa pè é ní ará Násárẹ́tì.”*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “onídán.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Tàbí “Mèsáyà; Ẹni Àmì Òróró.”
Tàbí “tẹrí ba.”
Tàbí “ọkàn.”
Ó ṣeé ṣe kó wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, “èéhù.”