Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì

Orí

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

  • 1

    • Ó kọ̀wé sí Tìófílọ́sì (1-5)

    • Iṣẹ́ ìwàásù máa dé gbogbo ìkángun ayé (6-8)

    • Jésù gòkè lọ sọ́run (9-11)

    • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ ní ìṣọ̀kan (12-14)

    • Wọ́n yan Màtáyásì rọ́pò Júdásì (15-26)

  • 2

    • Ẹ̀mí mímọ́ tú jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì (1-13)

    • Ọ̀rọ̀ Pétérù (14-36)

    • Ọ̀pọ̀ èèyàn gba ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ (37-41)

      • Èèyàn 3,000 ṣèrìbọmi (41)

    • Ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni (42-47)

  • 3

    • Pétérù wo arọ tó ń tọrọ nǹkan sàn (1-10)

    • Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Sólómọ́nì (11-26)

      • ‘Ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ (21)

      • Wòlíì kan bíi Mósè (22)

  • 4

    • Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù (1-4)

      • Iye àwọn onígbàgbọ́ di 5,000 ọkùnrin (4)

    • Ìgbẹ́jọ́ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (5-22)

      • ‘A ò lè ṣàì sọ̀rọ̀’ (20)

    • Àdúrà ìgboyà (23-31)

    • Àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ pín ohun tí wọ́n ní (32-37)

  • 5

    • Ananáyà àti Sàfírà (1-11)

    • Àwọn àpọ́sítélì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì (12-16)

    • Wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ (17-21a)

    • Wọ́n tún mú wọn wá síwájú Sàhẹ́ndìrìn (21b-32)

      • ‘Ṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò èèyàn’ (29)

    • Ìmọ̀ràn Gàmálíẹ́lì (33-40)

    • Wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé (41, 42)

  • 6

    • Wọ́n yan ọkùnrin méje láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ (1-7)

    • Wọ́n fẹ̀sùn kan Sítéfánù pé ó sọ̀rọ̀ òdì (8-15)

  • 7

    • Ọ̀rọ̀ tí Sítéfánù sọ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (1-53)

      • Ìgbà ayé àwọn baba ńlá (2-16)

      • Mósè ṣe aṣáájú; Ísírẹ́lì bọ̀rìṣà (17-43)

      • Ọlọ́run kì í gbé inú tẹ́ńpìlì tí èèyàn kọ́ (44-50)

    • Wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta (54-60)

  • 8

    • Sọ́ọ̀lù ṣe inúnibíni (1-3)

    • Ìwàásù Fílípì sèso rere ní Samáríà (4-13)

    • Wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ sí Samáríà (14-17)

    • Símónì fẹ́ ra ẹ̀mí mímọ́ (18-25)

    • Ìwẹ̀fà ará Etiópíà (26-40)

  • 9

    • Sọ́ọ̀lù wà ní ọ̀nà Damásíkù (1-9)

    • Olúwa rán Ananáyà pé kó lọ ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ (10-19a)

    • Sọ́ọ̀lù wàásù nípa Jésù ní Damásíkù (19b-25)

    • Sọ́ọ̀lù wá sí Jerúsálẹ́mù (26-31)

    • Pétérù wo Énéà sàn (32-35)

    • Dọ́káàsì tó jẹ́ ọ̀làwọ́ jíǹde (36-43)

  • 10

    • Ìran tí Kọ̀nílíù rí (1-8)

    • Pétérù rí àwọn ẹranko tí a ti sọ di mímọ́ nínú ìran (9-16)

    • Pétérù wá sílé Kọ̀nílíù (17-33)

    • Pétérù kéde ìhìn rere fún àwọn Kèfèrí (34-43)

      • “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú” (34, 35)

    • Àwọn Kèfèrí gba ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi (44-48)

  • 11

    • Pétérù ròyìn fún àwọn àpọ́sítélì (1-18)

    • Bánábà àti Sọ́ọ̀lù wà ní Áńtíókù ti Síríà (19-26)

      • Ìgbà àkọ́kọ́ tí a pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni (26)

    • Ágábù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìyàn máa mú (27-30)

  • 12

    • Wọ́n pa Jémíìsì; wọ́n fi Pétérù sẹ́wọ̀n (1-5)

    • Ọlọ́run dá Pétérù sílẹ̀ lọ́nà ìyanu (6-19)

    • Áńgẹ́lì kọ lu Hẹ́rọ́dù (20-25)

  • 13

    • Wọ́n rán Bánábà àti Sọ́ọ̀lù láti lọ ṣe míṣọ́nnárì (1-3)

    • Iṣẹ́ ìwàásù ní Sápírọ́sì (4-12)

    • Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Áńtíókù ti Písídíà (13-41)

    • Àsọtẹ́lẹ̀ tó fún wọn láṣẹ láti yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè (42-52)

  • 14

    • Ní Íkóníónì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, inúnibíni sì ń ṣẹlẹ̀ (1-7)

    • Ní Lísírà, wọ́n rò pé ọlọ́run ni wọ́n (8-18)

    • Wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, àmọ́ kò kú (19, 20)

    • Wọ́n ń fún àwọn ìjọ lókun (21-23)

    • Wọ́n pa dà sí Áńtíókù ti Síríà (24-28)

  • 15

    • Awuyewuye ní Áńtíókù lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ (1, 2)

    • Wọ́n gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí Jerúsálẹ́mù (3-5)

    • Àwọn alàgbà àti àwọn àpọ́sítélì ṣèpàdé (6-21)

    • Lẹ́tà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí (22-29)

      • Ta kété sí ẹ̀jẹ̀ (28, 29)

    • Lẹ́tà náà gbé àwọn ìjọ ró (30-35)

    • Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ (36-41)

  • 16

    • Pọ́ọ̀lù mú Tímótì (1-5)

    • Ìran ọkùnrin ará Makedóníà (6-10)

    • Lìdíà di onígbàgbọ́ ní ìlú Fílípì (11-15)

    • Wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n (16-24)

    • Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi (25-34)

    • Pọ́ọ̀lù ní kí àwọn aláṣẹ wá tọrọ àforíjì (35-40)

  • 17

    • Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Tẹsalóníkà (1-9)

    • Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní Bèróà (10-15)

    • Pọ́ọ̀lù ní Áténì (16-22a)

    • Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Áréópágù (22b-34)

  • 18

    • Iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Kọ́ríńtì (1-17)

    • Ó pa dà sí Áńtíókù ti Síríà (18-22)

    • Pọ́ọ̀lù lọ sí Gálátíà àti Fíríjíà (23)

    • Àpólò tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ rí ìrànlọ́wọ́ gbà (24-28)

  • 19

    • Pọ́ọ̀lù ní Éfésù; àwọn kan tún batisí ṣe (1-7)

    • Àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe láti kọ́ni (8-10)

    • Ó ń ṣàṣeyọrí láìka àwọn tó ní ẹ̀mí èṣù sí (11-20)

    • Éfésù dà rú (21-41)

  • 20

    • Pọ́ọ̀lù ní Makedóníà àti ilẹ̀ Gíríìsì (1-6)

    • Yútíkọ́sì jíǹde ní Tíróásì (7-12)

    • Láti Tíróásì sí Mílétù (13-16)

    • Pọ́ọ̀lù bá àwọn alàgbà Éfésù ṣèpàdé (17-38)

      • Ó ń kọ́ni láti ilé dé ilé (20)

      • “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni” (35)

  • 21

    • Lójú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù (1-14)

    • Wọ́n dé Jerúsálẹ́mù (15-19)

    • Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn alàgbà (20-26)

    • Inú tẹ́ńpìlì dà rú; wọ́n mú Pọ́ọ̀lù (27-36)

    • Wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láyè kó bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ (37-40)

  • 22

    • Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn (1-21)

    • Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tó ní (22-29)

    • Sàhẹ́ndìrìn pé jọ (30)

  • 23

    • Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ níwájú Sàhẹ́ndìrìn (1-10)

    • Olúwa fún Pọ́ọ̀lù lókun (11)

    • Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Pọ́ọ̀lù (12-22)

    • Wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaríà (23-35)

  • 24

    • Wọ́n fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù (1-9)

    • Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú Fẹ́líìsì (10-21)

    • Wọ́n dá ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù dúró fún ọdún méjì (22-27)

  • 25

    • Pọ́ọ̀lù jẹ́jọ́ níwájú Fẹ́sítọ́ọ̀sì (1-12)

      • “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” (11)

    • Fẹ́sítọ́ọ̀sì fọ̀rọ̀ lọ Ọba Ágírípà (13-22)

    • Pọ́ọ̀lù dúró níwájú Ágírípà (23-27)

  • 26

    • Pọ́ọ̀lù gbèjà ara rẹ̀ níwájú Ágírípà (1-11)

    • Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bó ṣe yí pa dà (12-23)

    • Èsì Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti ti Ágírípà (24-32)

  • 27

    • Pọ́ọ̀lù wọkọ̀ òkun lọ sí Róòmù (1-12)

    • Ìjì kọ lu ọkọ̀ òkun (13-38)

    • Ọkọ̀ òkun fọ́ (39-44)

  • 28

    • Wọ́n gúnlẹ̀ sí Málítà (1-6)

    • Bàbá Púbílọ́sì rí ìwòsàn (7-10)

    • Wọ́n forí lé Róòmù (11-16)

    • Pọ́ọ̀lù bá àwọn Júù sọ̀rọ̀ ní Róòmù (17-29)

    • Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà wàásù fún ọdún méjì (30, 31)