Jeremáyà 29:1-32

  • Lẹ́tà tí Jeremáyà kọ sí àwọn tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì (1-23)

    • Ísírẹ́lì yóò pa dà lẹ́yìn 70 ọdún (10)

  • Iṣẹ́ tí wọ́n rán sí Ṣemáyà (24-32)

29  Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jerúsálẹ́mù sí àwọn àgbààgbà tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó wà nígbèkùn àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn èèyàn náà, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì,  lẹ́yìn tí Ọba Jekonáyà,+ ìyá ọba,*+ àwọn òṣìṣẹ́ ààfin, àwọn ìjòyè Júdà àti Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin* ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+  Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Ṣáfánì+ àti Gemaráyà ọmọ Hilikáyà, ẹni tí Ọba Sedekáyà+ ti Júdà rán sí Bábílónì sí Ọba Nebukadinésárì ti Bábílónì. Ó sọ pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn, ìyẹn àwọn tó mú kí wọ́n lọ sí ìgbèkùn kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.  ‘Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn. Ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn.  Ẹ fẹ́ ìyàwó kí ẹ sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin; ẹ fẹ́ ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ, kí àwọn náà lè bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Ẹ di púpọ̀ níbẹ̀, kí ẹ má sì dín kù.  Ẹ máa wá àlàáfíà ní ìlú tí mo kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì máa gbàdúrà sí Jèhófà nítorí rẹ̀, nítorí bí ó bá wà ní àlàáfíà, ẹ̀yin náà á wà ní àlàáfíà.+  Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì yín àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín tó wà láàárín yín tàn yín jẹ,+ ẹ má sì fetí sí àlá tí wọ́n ń lá.  Nítorí ‘èké ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín ní orúkọ mi. Mi ò rán wọn,’+ ni Jèhófà wí.”’” 10  “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Tó bá ti pé àádọ́rin (70) ọdún tí ẹ ti wà ní Bábílónì, màá yí ojú mi sí yín,+ màá sì mú ìlérí mi ṣẹ láti mú yín pa dà wá sí ibí yìí.’+ 11  “‘Nítorí mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa,’ ni Jèhófà wí, ‘èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù,+ láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.+ 12  Ẹ ó pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, màá sì fetí sí yín.’+ 13  “‘Ẹ ó wá mi, ẹ ó sì rí mi,+ nítorí gbogbo ọkàn yín ni ẹ ó fi wá mi.+ 14  Màá sì jẹ́ kí ẹ rí mi,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá kó yín pa dà láti oko ẹrú, màá sì kó yín jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti gbogbo ibi tí mo fọ́n yín ká sí,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá sì mú yín pa dà wá sí ibi tí mo ti jẹ́ kí wọ́n kó yín lọ sí ìgbèkùn.’+ 15  “Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé, ‘Jèhófà ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.’ 16  “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí fún ọba tó jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti gbogbo àwọn èèyàn tó ń gbé inú ìlú yìí, ìyẹn àwọn arákùnrin yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn, 17  ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn*+ sí wọn, màá sì ṣe wọ́n bí ọ̀pọ̀tọ́ jíjẹrà* tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ.”’+ 18  “‘Màá fi idà,+ ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn lé wọn, màá sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù lójú gbogbo ìjọba ayé,+ màá sì sọ wọ́n di ẹni ègún àti ohun ìyàlẹ́nu, ohun àrísúfèé+ àti ẹni ẹ̀gàn láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí màá fọ́n wọn ká sí,+ 19  nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí mo fi ránṣẹ́ sí wọn nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì,’ ni Jèhófà wí, ‘tí mò ń rán wọn léraléra.’*+ “‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀,’+ ni Jèhófà wí. 20  “Torí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin tó wà nígbèkùn, tí mo rán lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Bábílónì. 21  Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa Áhábù ọmọ Koláyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Maaseáyà, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi,+ ‘Wò ó, màá fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì pa wọ́n lójú yín. 22  Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn á di ohun tí gbogbo àwọn ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn ní Bábílónì á máa sọ, tí wọ́n bá fẹ́ gégùn-ún fún àwọn èèyàn, wọ́n á ní: “Kí Jèhófà ṣe ọ́ bíi Sedekáyà àti Áhábù, àwọn tí ọba Bábílónì yan nínú iná!” 23  nítorí pé wọ́n ti hùwà àìnítìjú ní Ísírẹ́lì,+ wọ́n ń bá aya ọmọnìkejì wọn ṣe àgbèrè, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ èké ní orúkọ mi, èyí tí mi ò pa láṣẹ fún wọn.+ “‘“Èmi ni Ẹni tí ó mọ̀, èmi sì ni ẹlẹ́rìí,”+ ni Jèhófà wí.’” 24  “Kí o sọ fún Ṣemáyà+ ará Néhélámù pé, 25  ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Nítorí pé o fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ ní orúkọ rẹ sí gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti sí Sefanáyà+ ọmọ Maaseáyà tó jẹ́ àlùfáà àti sí gbogbo àwọn àlùfáà, pé, 26  ‘Jèhófà ti sọ ọ́ di àlùfáà dípò Jèhóádà àlùfáà láti di alábòójútó ilé Jèhófà, láti máa kápá ẹnikẹ́ni tó ya wèrè tó sì ń ṣe bíi wòlíì, kí o sì fi í sínú àbà àti sínú egìran;*+ 27  kí wá nìdí tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì+ wí, ẹni tó ń ṣe wòlíì fún yín?+ 28  Torí ó ránṣẹ́ sí wa ní Bábílónì pé: “Ó máa pẹ́ gan-an! Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn. Ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn,+—”’”’” 29  Nígbà tí àlùfáà Sefanáyà+ ka lẹ́tà yìí létí wòlíì Jeremáyà, 30  Jèhófà bá Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 31  “Ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣemáyà ará Néhélámù nìyí: “Nítorí pé Ṣemáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún yín, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò rán an, tó sì fẹ́ mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé irọ́,+ 32  nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá fìyà jẹ Ṣemáyà ará Néhélámù àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Kò ní sí ọkùnrin kankan tó jẹ́ tirẹ̀ tó máa yè bọ́ lára àwọn èèyàn yìí, kò sì ní rí ohun rere tí màá ṣe fún àwọn èèyàn mi,’ ni Jèhófà wí, ‘nítorí ó ti mú kí wọ́n dìtẹ̀ sí Jèhófà.’”’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń kọ́ odi ààbò.”
Tàbí “ìyáàfin.”
Tàbí kó jẹ́, “fífọ́.”
Tàbí “àìsàn.”
Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù, mo sì ń rán wọn.”
Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
Tàbí “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ọrùn.” Egìran túmọ̀ sí igi méjì tí wọ́n fi ń de apá àti ọrùn ẹni tí wọ́n bá fẹ́ pẹ̀gàn.